1 Ní ọjọ́ kan, Dínà ọmọbìnrin tí Líà bí fún Jákọ́bù jáde lọ bẹ àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ náà wò.
2 Nígbà tí Ṣékémù ọmọ ọba Hámórì ará Hífì rí i, ó mú un, ó sì fi ipá bá a lo pọ̀
3 Ọkàn rẹ sì fà sí Dínà ọmọ Jákọ́bù gan-an, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ ó sì bá ọmọbìnrin náà sọ̀rọ̀-ìfẹ́.
4 Ṣékémù sì wí fún Hámórì bàbá rẹ̀ pé, “Fẹ́ ọmọbìnrin yìí fún mi bí aya.”
5 Nígbà tí Jákọ́bù gbọ́ ohun tí ó sẹlẹ̀ pé a fi ipá bá Dínà ọmọbìnrin òun lò pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀ wà nínú pápá níbi tí wọ́n ti ń daran nítorí náà ó mú sùúrù títí tí wọ́n fi dé.
6 Ámórì baba Ṣékémù sì jáde wá láti bá Jákọ́bù sọ̀rọ̀.
7 Àwọn ọmọ Jákọ́bù sì ti oko dé, wọ́n sì gbọ́ ohun tí ó ṣelẹ̀ inú wọn sì bàjẹ́, ó sì ń bí wọn nínú gidigidi, nítorí pé, ohun àbùkù ńlá ni ó jẹ́ pé Ṣékémù bá ọmọ Jákọ́bù lò pọ̀-irú ohun tí kò yẹ kí ó ṣẹlẹ̀ rárá.
8 Hámórì sì bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkàn ọmọ mi Ṣékémù fà sí ọmọ rẹ. Jọ̀wọ́ fi fún un gẹ́gẹ́ bí aya.
9 Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ìgbéyàwó láàrin ara wa, kí àwọn ọmọ yín kó máa fẹ́ àwọn ọmọ wa.
10 Ẹ lè máa gbé láàrin wa, ibikíbi tí ó bá tẹ́ yín lọ́rùn láàrin wa ni ẹ lè gbé, ẹ máa ṣe òwò yín kí ẹ sì kó ọrọ̀ jọ fún ara yín.”
11 Ṣékémù sì wí fún baba àti arákùnrin Dínà pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n rí ojú rere yín, èmi yóò sì fún yín ní ohunkóhun tí ẹ̀yin bá fẹ́ gbà.
12 Iyekíye tí owó orí rẹ̀ bá jẹ́ àti ẹ̀bùn gbogbo tí ẹ bá fẹ́, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó, èmi yóò san-án, kí ẹ sáà jẹ́ kí ń fi ọmọ náà ṣe aya.”
13 Àwọn arákùnrin Dínà sì fi ẹ̀tàn dá Ṣékémù àti Ámórì bàbá rẹ̀ lóhùn nítorí tí ó ti ba ògo Dínà arábìnrin wọn jẹ́.
14 Wọ́n wí fún wọn pé, “Àwa kò le ṣe nǹkan yìí láti fi arábìnrin wa fún aláìkọlà, nítorí àbùkù ni èyí yóò jẹ́ fún wa.
15 Àwa yóò fara mọ́ ọn bí ẹ̀yin yóò bá gbà láti dàbí i tiwa, wí pé ẹ̀yin pẹ̀lú yóò kọ gbogbo ọkùnrin yín ní ilà.
16 Nígbà náà ni àwa yóò le máa fún yín ní ọmọ wa, tí àwa náà yóò máa fẹ́ ẹ yín. A ó máa gbé láàrin yín, a ó sì di ara kan pẹ̀lú yín.
17 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ láti kọlà, àwa yóò mú arábìnrin wa, á ó sì máa lọ.”
18 Àbá náà sì dùn mọ́ Ámórì àti Ṣékémù ọmọ rẹ̀.
19 Ọ̀dọ́mọkùnrin náà, ẹni tí ó jẹ́ ẹni iyì jùlọ ní ilé bàbá rẹ̀, kò jáfara láti ṣe ohun tí wọ́n wí. Nítorí tí ó fẹ́ràn ọmọbìnrin Jákọ́bù.
20 Ámórì àti Ṣékémù ọmọ rẹ̀ sì wá sí ẹnu ibodè ìlú náà wọn sì bá àwọn ará ìlú náà sọ̀rọ̀.
21 Wí pé, “Ìwa àwọn ọkùnrin wọ̀nyí dára, ẹ jẹ́ kí wọn máa gbé ní àárin wa, kí wọn sì máa ṣòwò, ilẹ̀ kúkú wà rẹpẹtẹ tó gbààyè dáradára. A lè fẹ́ àwọn ọmọ wọ̀n, ki wọn sì fẹ́ tiwa pẹ̀lú.
22 Ṣùgbọ́n kin ní kan ni a lè ṣe kí wọn tó gbà láti gbé pẹ̀lú wa, ìyẹn sì ni pé àwọn ọkùnrin wa yóò kọlà bí i tiwọn
23 Ṣe bí àwọn ẹran wọn àti ẹrú wọn àti àwọn ohun ọ̀sìn wọn ni yóò di tiwa bí a bá lè gbà bẹ́ẹ̀, wọn yóò sì máa gbé ni àárin wa.”
24 Gbogbo àwọn ọkùnrin tí ń jáde lẹ́nu bodè ìlú náà sì gbọ́ ti Ámórì àti Ṣékémù ọmọ rẹ̀. Gbogbo ọkùnrin ìlú náà sì kọlà.
25 Lẹ́yìn ọjọ́ kẹ́ta, nígbà tí gbogbo wọn sì wà nínú ìrora. Àwọn ọmọ Jákọ́bù méjì, Símónì àti Léfì tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún Dínà, sì mú idà wọn pẹ̀lú ìgboyà, wọ́n sì pa gbogbo ọkùnrin ìlú náà.
26 Wọ́n pa Ámórì àti Ṣékémù ọmọ rẹ̀, wọ́n mú Dínà kúrò ní ilé wọn, wọ́n sì jáde.
27 Àwọn ọmọ Jákọ́bù sì wọlé àwọn tí a pa, wọ́n sì kó ẹrù ìlú tí a ti ba ògo arábìnrin wọn jẹ́.
28 Wọ́n kó màlúù wọn àti agbo ẹran wọn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìlú àti ní oko.
29 Gbogbo ọrọ̀ wọn, gbogbo obìnrin ìlú àti àwọn ọmọ wẹẹrẹ pátapáta ni wọ́n kó. Wọ́n sì kó gbogbo ohun tí ó wà nínú ilé wọn bí ìkógun.
30 Nígbà náà ni Jákọ́bù wí fún Símónì àti Léfì wí pé, “Ẹ̀yin ti kó ìyọnu bá mi nípa sísọ mí di olóòórùn láàrin ará Kénánì àti Pérésì, tí ó ń gbé ilẹ̀ yìí. Àwa kò pọ̀, bí wọn bá wá parapọ̀ sígun sí wa, gbogbo wa pátapáta ni wọn yóò parun.”
31 Ṣùgbọ́n wọ́n dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí ó ṣe arábìnrin wa bí aṣẹ́wó?”