1 Ṣáráì, aya Ábúrámù kò bímọ fún un, ṣùgbọ́n ó ní ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrini ará Éjíbítì kan tí ń jẹ́ Ágárì.
2 Nítorí náà, Ṣáráì wí fún Ábúrámù pé, “Kíyèsí i Olúwa ti sé mi ní inú, èmi kò sì bímọ, wọlé tọ ọmọ ọ̀dọ̀ mi lọ, bóyá èmi yóò le ti ipaṣẹ̀ rẹ̀ ní ọmọ.”Ábúrámù sì gba ohun tí Ṣáráì sọ.
3 Lẹ́yín ọdún mẹ́wàá tí Ábúrámù ti ń gbé ni Kénánì ni Ṣáráì mú ọmọbìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Hágárì, tí í ṣe ará Éjíbítì fún Ábúrámù ọkọ rẹ̀ láti fi ṣe aya.
4 Ábúrámù sì bá Ágárì lòpọ̀, ó sì lóyún.Nígbà tí ó sì ti mọ̀ pé òun lóyún, ó bẹ̀rẹ̀ sì ní kẹ́gàn ọ̀gá rẹ̀ (Ṣáráì).
5 Nígbà náà ni Ṣáráì wí fún Ábúrámù pé, “Ìwọ ni ó jẹ́ kí ẹ̀gbin yìí máa jẹmí, mo fa ọmọ ọ̀dọ̀ mi lé ọ lọ́wọ́, nígbà tí ó sì rí i pé òun lóyún, mo di ẹni ẹ̀gàn ní ojú rẹ̀. Kí Olúwa kí ó ṣe ìdájọ́ láàrin èmi àti ìwọ.”
6 Ábúrámù dáhùn pé, “Ìwọ ló ni ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣe ohunkóhun tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ sí i.” Nígbà náà ni Ṣáráì fi ìyà jẹ ẹ́, ó sì sá lọ.
7 Ańgẹ́lì Olúwa sì rí Ágáì ní ẹ̀gbẹ́ ìsun omi ní ijù, ìsun omi tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀na tí ó lọ sí Ṣúrì.
8 Ó sì wí pé, “Hágárì, ìránṣẹ́ Ṣáráì, níbo ni o ti ń bọ̀, níbo sì ni ìwọ ń lọ?”Ó sì dáhùn pé, “Mo ń sá lọ kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá mi Ṣáráì ni.”
9 Ańgẹ́lì Olúwa sì wí fún un pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ kí o sì tẹríba fún un.”
10 Ańgẹ́lì náà sì fi kún fún un pé, “Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá, ìran rẹ kì yóò sì lóǹkà.”
11 Ańgẹ́lì náà sì wí fún un pé,“Ìwọ ti lóyún ìwọ yóò sì bíọmọkùnrin kan,ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Íṣímáélì,nítorí tí Olúwa ti rí ìpọ́njú rẹ.
12 Òun yóò jẹ́ ẹhànnà ènìyànyóò máa tako gbogbo ènìyàn,gbogbo ènìyàn yóò sì máa takò ó,kì yóò sì bá awọn arákùnrin rẹ̀gbé ní ìrẹ́pọ̀.”
13 Ó sì fi pe Olúwa tí o bá sọ̀rọ̀ ní, “Ìwọ ni Ọlọ́run tí ó rí mi,” nítorí tí ó wí pé, “Mo ti ri ẹni tí ó rí mi báyìí.”
14 Nítorí náà ni a ṣe ń pe kànga náà ní Beeri-Lahai-Róì: kànga ẹni alààyè tí ó rí mi. Ó wà lágbedeméjì Kédásì àti Bérédì.
15 Ágárì sì bí ọmọkùnrin kan fún Ábúrámù, Ábúrámù sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ísímáélì.
16 Ábúrámù jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndín-láàádọ́rùn-ún (86) nígbà tí Hágárì bí Ísímáélì fún-un.