Jẹ́nẹ́sísì 2 BMY

1 Báyìí ni Ọlọ́run parí dídá àwọn ọ̀run àti ayé pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.

2 Ní ọjọ́ keje Ọlọ́run parí iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ń ṣe, ó sì sinmi ní ọjọ́ kéje.

3 Ọlọ́run sì súre fún ọjọ́ kéje, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ní ọjọ́ náà ni ó sinmi kúrò nínú iṣẹ́ dídá ayé tí ó ti ń ṣe.

Ádámù àti Éfà

4 Èyí ni ìtàn bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn ọ̀run àti ayé nígbà tí ó dá wọn.Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run dá ayé àti àwọn ọ̀run,

5 kò sí igi igbó kan ní orí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ewéko igbó kan tí ó tí ì hù jáde ní ilẹ̀, nítorí Olúwa Ọlọ́run kò tí ì rọ̀jò sórí ilẹ̀, kò sì sí ènìyàn láti ro ilẹ̀.

6 Ṣùgbọ́n ìsun omi ń jáde láti ilẹ̀, ó sì ń bu omi rin gbogbo ilẹ̀.

7 Olúwa Ọlọ́run sì mọ ènìyàn láti ara erùpẹ̀ ilẹ̀, ó si mí èémí sí ihò imú rẹ̀, èémí ìyè, ènìyàn sì di ẹ̀dá alààyè.

8 Olúwa Ọlọ́run sì gbin ọgbà kan sí Édẹ́nì ní ìhà ìlà oòrùn, níbẹ̀ ni ó fi ọkùnrin náà tí ó ti dá sí.

9 Ọlọ́run sì mú kí onírúurú igi hù jáde láti inú ilẹ̀: àwọn igi tí ó dùn-ún wò lójú, tí ó sì dára fún oúnjẹ. Ní àárin ọgbà náà ni igi ìyè àti igi tí ń mú ènìyàn mọ rere àti búburú wà.

10 Odò kan sì ń ti Édẹ́nì sàn wá láti bu omi rin ọgbà náà, láti ibẹ̀ ni odò náà gbé ya sí ipa mẹ́rin.

11 Orúkọ èkínní ni Písónì: òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Háfílà ká, níbi tí wúrà gbé wà.

12 (Wúrà ilẹ̀ náà dára, òjíá àti òkúta oníyebíye wà níbẹ̀ pẹ̀lú).

13 Orúkọ odò kejì ni Gíhónì: òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Kúsì ká.

14 Orúkọ odò kẹta ni Tígírísì: òun ni ó sàn ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ Áṣúrì. Odò kẹ́rin ni Yúfúrátè.

15 Olúwa Ọlọ́run mú ọkùnrin náà sínú ọgbà Édẹ́nì láti máa ṣe iṣẹ́ níbẹ̀, kí ó sì máa ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

16 Olúwa Ọlọ́run sì pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé, “ìwọ́ lè jẹ lára èyíkéyìí èṣo àwọn igi inú ọgbà;

17 ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú èṣo igi ìmọ̀ rere àti èṣo igi ìmọ̀ búburú, nítorí ní ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ ẹ́ ni ìwọ yóò kú.”

18 Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Kò dára kí ọkùnrin wà ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀ fún un.”

19 Lẹ́yìn tí Olúwa Ọlọ́run ti dá àwọn ẹranko inú igbó àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀, Ó sì kó wọn tọ ọkùnrin náà wá láti wo orúkọ tí yóò sọ wọ́n; orúkọ tí ó sì sọ gbogbo ẹ̀dá alààyè náà ni wọ́n ń jẹ́.

20 Gbogbo ohun ọ̀sìn, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹranko igbó ni ọkùnrin náà sọ ní orúkọ.Ṣùgbọ́n fún Ádámù ni a kò rí olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀.

21 Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run mú kí ọkùnrin náà sùn fọnfọn; nígbà tí ó sì ń sùn, Ọlọ́run yọ egungun ìhà rẹ̀ kan, ó sì fi ẹran ara bò ó padà.

22 Olúwa Ọlọ́run sì dá obìnrin láti inú egungun tí ó yọ ní ìhà ọkùnrin náà, ó sì mu obìnrin náà tọ̀ ọ́ wá.

23 Ọkùnrin náà sì wí pé,“Èyí ni egungun láti inú egungun miàti ẹran-ara nínú ẹran-ara mi;‘obìnrin’ ni a ó máa pè énítorí a mú un jáde láti ara ọkùnrin.”

24 Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.

25 Ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ sì wà ní ìhòòhò, ojú kò sì tì wọ́n.