Jẹ́nẹ́sísì 35 BMY

Jákọ́bù Padà sí Bẹ́tẹ́lì

1 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Jákọ́bù pé, “Gòkè lọ sí Bẹ́tẹ́lì kí o sì tẹ̀dó ṣíbẹ̀, kí o mọ pẹpẹ níbẹ̀ fún Ọlọ́run tó farahàn ọ́ nígbà tí o ń sá lọ kúrò níwájú Íṣọ̀ arákùnrin rẹ.”

2 Nítorí náà, Jákọ́bù wí fún gbogbo ará ilé rẹ̀ pé, “Ẹ mú gbogbo àjòjì òrìsà tí ó wà lọ́dọ̀ yín kúrò, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì pààrọ̀ aṣọ yín.

3 Nígbà náà ni kí ẹ wá, kí ẹ jẹ́ kí a lọ sí Bẹ́tẹ́lì, níbi tí n ó ti mọ pẹpẹ fún Ọlọ́run, tí ó dá mi lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú mi tí ó sì ti ń pẹ̀lú mi níbi gbogbo tí mo ń lọ.”

4 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fún Jákọ́bù ní gbogbo àjòjì òrìsà tí ó wà lọ́wọ́ wọn, àti yẹtí etí wọn, Jákọ́bù sì bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ sabẹ́ igi Óákù ní Ṣékémù.

5 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò wọn. Ìbẹ̀rù láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run sì ń bá lé gbogbo ìlú tí wọ́n ń là kọjá ní ọ̀nà wọn tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹni tí ó le è dojú ìjà kọ wọ́n.

6 Jákọ́bù àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì dé sí Lúsì (Bẹ́tẹ́lì) tí ó wà ní ilẹ̀ Kénánì.

7 Níbẹ̀ ni ó sì mọ pẹpẹ kan tí ó pè ní El-Bẹ́tẹ́lì (Ọlọ́run Bẹ́tẹ́lì), nítorí níbẹ̀ ni Ọlọ́run ti gbé fi ara hàn-án nígbà tí ó ń sá lọ fún arákùnrin rẹ̀.

8 Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí ni Dèbórà, olùtọ́jú Rèbékà kú, a sì sin-ín sábẹ́ igi Óàkù ní ìsàlẹ̀ Bẹ́tẹ́lì: Nítorí náà a sọ ọ́ ní Aloni-Bákútì (Óákù Ẹkún).

9 Lẹ́yìn tí Jákọ́bù padà dé láti Padani-Árámù, Ọlọ́run tún fara hàn-án, ó sì súre fún un.

10 Ọlọ́run sì wí fun un pé, “Jákọ́bù ni orúkọ rẹ̀, a kì yóò pè ọ́ ní Jákọ́bù (alọ́nilọ́wọ́gbà) mọ́ bí kò ṣe Ísírẹ́lì (ẹni tí ó bá Ọlọ́run jìjàkadì, tí ó sì ṣẹ́gun).” Nítorí náà, ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Ísírẹ́lì.

11 Ọlọ́run sì wí fún-un pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára; máa bí sí i, kí o sì máa pọ̀ sí i. Orílẹ̀-èdè àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, àwọn ọba yóò sì jáde wá láti ara rẹ̀.

12 Gbogbo ilẹ̀ tí mo fi fún Ábúráhámù àti Ísáákì ni èmi yóò fún ọ pẹ̀lú, àti fún àwọn ìran rẹ tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn.”

13 Nígbà náà ni Ọlọ́run gòkè lọ kúrò ní ibi tí ó ti ń bá a sọ̀rọ̀.

14 Jákọ́bù sì fi òkúta ṣe òpó kan sí ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀ ó sì ta ọrẹ ohun mímu (wáìnì) ní orí rẹ̀, ó sì da òróró ólífì sí orí rẹ̀ pẹ̀lú.

15 Jákọ́bù sì pe orúkọ ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì.

Ikú Rákélì àti Ísáákì

16 Nígbà náà ni wọ́n ń tẹ̀ṣíwájú nínú ìrìn-àjò wọn láti Bẹ́tẹ́lì. Nígbà tí ó sì ku díẹ̀ kí wọn dé Éfúrátì, Rákélì bẹ̀rẹ̀ sí ní rọbí, ó sì ní ìdààmú púpọ̀.

17 Bí ó sì ti ń rọbí pẹ̀lú ìrora yìí, agbẹ̀bí wí fún-un pé “Má bẹ̀rù nítorí ọmọkùnrin mìíràn ni ó ń bọ̀ yìí.”

18 Bí o sì ti fẹ́ gbé ẹ̀mí mi (torí pé ó ń kú lọ), ó pe ọmọ rẹ̀ náà ní Bẹni-Ónì (ọmọ ìpọ́njú mi). Ṣùgbọ́n Jákọ́bù sọ ọmọ náà ní Bẹ́ńjámínì (ọmọ oókan àyà mi).

19 Báyìí ni Rákélì kú, a sì sin-ín sí ọ̀nà Éfúrátì (Bẹ́tílẹ́hẹ́mù).

20 Jákọ́bù sì mọ òpó (ọ̀wọ̀n) kan sí ibojì rẹ̀, òpó náà sì tọ́ka sí ojú ibojì Rákélì títí di òní.

21 Ísírẹ́lì sì ń bá ìrìn-àjò rẹ̀ lọ, ó sì pa àgọ́ rẹ̀ sí Migida-Édérì (ilé-ìsọ́ Édérì).

22 Nígbà tí Ísírẹ́lì sì ń gbé ní ibẹ̀, Rúbẹ́nì wọlé tọ Bílíhà, àlè (ìyàwó tí a kò fi owó fẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀) baba rẹ̀ lọ, ó sì bá a lò pọ̀, Ísírẹ́lì sì gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.Jákọ́bù sì bí ọmọkunrin méjìlá:

23 Àwọn ọmọ Líà:Rúbẹ́nì tí í ṣe àkọ́bí Jákọ́bù,Símónì, Léfì, Júdà, Ísákárì àti Ṣébúlúnì.

24 Àwọn ọmọ Rákélì:Jóṣẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì.

25 Àwọn ọmọ Bílíhà ìránṣẹ́bìnrin Rákélì:Dánì àti Náfítalì.

26 Àwọn ọmọ Ṣílípà ìránṣẹ́-bìnrin Líà:Gádì àti Áṣérì.Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Jákọ́bù bí ní Padani-Árámù.

27 Jákọ́bù sì padà dé ilé lọ́dọ̀ Ísáákì baba rẹ̀ ni Mámúrè ní tòsí i Kiriati-Árábà (Hébúrónì). Níbi tí Ábúráhámù àti Ísáákì gbé.

28 Ẹni ọgọ́sán-an (180) ọdún ni Ísáákì.

29 Ísáákì sì kú láìpẹ́ lẹ́yìn ìpadàbọ̀ Jákọ́bù, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ọjọ́-ogbó rẹ̀. Ísọ̀ àti Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ sì sin-ín.