Jẹ́nẹ́sísì 10 BMY

Ìran àwọn ọmọ Nóà

1 Èyí ni ìran àwọn ọmọ Nóà: Ṣémù, Ámù àti Jáfétì, tí àwọn náà sì bí ọmọ lẹ́yìn ìkún omi.

Ìran Jáfétì

2 Àwọn ọmọ Jáfétì ni:Gómérì, Mágógì, Mádáì, Jáfánì, Túbálì, Méṣékì àti Tírásì.

3 Àwọn ọmọ Gómérì ni:Áṣíkénásì, Rífátì àti Tógárímà.

4 Àwọn ọmọ Jáfánì ni:Élíṣà, Tásísì, Kítímù, àti Ródánímù.

5 (Láti ọ̀dọ̀ àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ń gbé agbégbé tí omi wà ti tàn ká agbégbé wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, ìdílé wọn ní orílẹ̀ èdè wọn, olúkúlùkù pẹ̀lú èdè tirẹ̀).

Ìran Ámù

6 Àwọn ọmọ Ámù ni:Kúsì, Mísíráímù, Fútì àti Kénánì.

7 Àwọn ọmọ Kúsì ni:Ṣébà, Háfílà, Ṣábátà, Rámà, àti Ṣábítékà.Àwọn ọmọ Rámà ni:Ṣébà àti Dédánì.

8 Kúsì sì bí Nímúrọ́dù, èyí tí ó di alágbára àti jagunjagun ní ayé.

9 Ó sì jẹ́ ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa; nítorí náà ni a ṣe ń wí pé, “Bí Nímúrọ́dù-ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa.”

10 Ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni Bábílónì, Érékì, Ákádì, Kálínéhì, gbogbo wọn wà ní ilẹ̀ Ṣínárì.

11 Láti ilẹ̀ náà ni ó ti lọ sí dé Áṣíríà, níbi tí ó ti tẹ ìlú Nínéfè, Réhóbótì àti Kálà,

12 àti Résínì, tí ó wà ní àárin Nínéfè àti Kálà, tí ó jẹ́ ìlú olókìkí.

13 Mísíráímù ni baba ńlá àwọn aráLúdì, Ánámì, Léhábì, Náfítúhímù.

14 Pátírúsímù, Kásílúhímù (èyí tí í ṣe baba ńlá àwọn Fílístínì) àti Káfítórímù.

15 Kénánì ni baba àwọn aráSídónì (èyi ni àkọ́bí rẹ̀), àti àwọn ara Hítì.

16 Àwọn ará Jébúsì, Ámórì, Gágásì.

17 Hífì, Áríkì, Sínì,

18 Áfádì, Ṣémárì àti Hámátì.Nígbà tí ó ṣe, àwọn ẹ̀yà Kénánì tàn kálẹ̀.

19 Ààlà ilẹ̀ àwọn ará Kénánì sì dé Ṣídónì, lọ sí Gérárì títí dé Gásà, lọ sí Sódómù, Gòmórà, Ádímà àti Ṣébóìmù, títí dé Láṣà.

20 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ámù, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, àti èdè wọn, ní ìpínlẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn.

Ìran Ṣémù

21 A bí àwọn ọmọ fún Ṣémù tí Jáfétì jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin: Ṣémù sì ni baba gbogbo àwọn ọmọ Ébérì.

22 Àwọn ọmọ Ṣémù ni:Élámù, Ásọ̀, Áfákísádì, Lúdì àti Árámù.

23 Àwọn ọmọ Árámù ni:Úsì, Úlì, Gétérì àti Méṣékì.

24 Áfákísádì ni baba Ṣélà,Ṣélà yìí sì ni ó bí Ébérì.

25 Ébérì sì bí ọmọ méjì:ọ̀kan sì ń jẹ́ Pélégì, nítorí ní ìgbà ayé rẹ̀ ni ilẹ̀ ayé pín sí oríṣìíríṣìí ẹ̀yà àti èdè. Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Jókítanì.

26 Jókítanì sì bíÁlímádádì, Ṣéléfì, Hásámáfétì àti Jérà.

27 Hádórámù, Húsálì, Díbílà.

28 Óbálì, Ábímáélì, Ṣébà.

29 Ófírì, Áfílà àti Jóbábù. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Jókítanì.

30 Agbègbè ibi tí wọn ń gbé bẹ̀rẹ̀ láti Méṣà títí dé Ṣéfárì, ní àwọn ilẹ̀ tó kún fún òkè ní ìlà oòrùn.

31 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Ṣémù gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, ní èdè wọn, ní ilẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀ èdè wọn.

32 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Nóà gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, ní orílẹ̀ èdè wọn. Ní ipaṣẹ̀ wọn ni àwọn ènìyàn ti tàn ká ilẹ̀ ayé lẹ́yìn ìkún omi.