Jẹ́nẹ́sísì 11 BMY

Ilé-ìṣọ́ Bábílónì

1 Lẹ́yìn náà, gbogbo àgbáyé sì ń sọ èdè kan ṣoṣo.

2 Bí àwọn ènìyàn ṣe ń tẹ̀ṣíwájú lọ sí ìhà ìlà oòrùn, wọ́n rí pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan ní ilẹ̀ Sínárì (Bábílónì), wọ́n sì tẹ̀dó ṣíbẹ̀.

3 Wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a mọ bíríkì kí a sì sun wọ́n jiná.” Bíríkì ni wọn ń lò ní ipò òkúta, àti ọ̀dà ilẹ̀ tí wọn ń lò láti mú wọn papọ̀ dípò ẹfun (òkúta láìmù tí wọn fi ń ṣe símẹ́ńtì àti omi).

4 Nígbà náà ni wọ́n wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú kan fún ara wa, kí a sì kọ́ ilé-ìṣọ́ kan tí yóò kan ọ̀run, kí á baà lè ní orúkọ (òkìkí) kí a má sì tú káàkiri sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”

5 Ṣùgbọ́n, Olúwa sọ̀kalẹ̀ láti wo ìlú àti ilé-ìṣọ́ tí àwọn ènìyàn náà ń kọ́.

6 Olúwa wí pé, “Bí àwọn ènìyàn bá ń jẹ́ ọ̀kan àti èdè kan tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ yìí, kò sí ohun tí wọ́n gbérò tí wọn kò ní le ṣeyọrí.

7 Ẹ̀ wá, ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ lọ, kí a da èdè wọn rú kí èdè wọn má baà yé ara wọn mọ́.”

8 Ọlọ́run sì tú wọn ká sórí ilẹ̀ gbogbo, wọ́n sì ṣíwọ́ ìlú náà tí wọn ń tẹ̀dó.

9 Ìdí èyí ni a fi pè é ní Bábílónì nítorí ní ibẹ̀ ni Ọlọ́run ti da èdè gbogbo ayé rú, tí ó sì tú àwọn ènìyàn ká sí gbogbo orí ilẹ̀ ayé.

Ìran Ṣémù tó fi dé ti Ábúrámù

10 Wọ̀nyí ni ìran ṢémùỌdún méjì lẹ́yìn ìkún omi, tí Ṣémù pé ọgọ́rùn-ún ọdún (100) ni ó bí Áfákísádì.

11 Lẹ́yìn tí ó bí Áfákísádì, ó tún wà láàyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

12 Nígbà tí Áfákísádì pé ọdún marùndínlógójì (35) ni ó bí Ṣélà.

13 Ó sì wà láàyè fún ọdún mẹ́talénírínwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ṣélà, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn.

14 Nígbà tí Ṣélà pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Ébérì.

15 Ó sì wà láàyè fún ọdún mẹ́talénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ébérì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

16 Ébérì sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (34), ó sì bí Pélégì.

17 Ébérì sì wà láàyè fún irínwó-ó-lé-ọgbọ̀n ọdún (430) lẹ́yìn tí ó bí Pélégì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

18 Nígbà tí Pélégì pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Réù.

19 Ó sì tún wà láàyè fún igba-ó-lé-mẹ́sàn án ọdún (209) lẹ́yìn tí ó bí Réù, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

20 Nígbà tí Réù pé ọdún méjìlélọ́gbọ̀n (32) ni ó bí Ṣérúgì.

21 Ó tún wà láàyè lẹ́yìn tí ó bí Ṣérúgì fún igba-ó-lé-méje ọdún (207), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn.

22 Nígbà tí Ṣérúgì pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Náhórì.

23 Ó sì wà láàyè fún igba ọdún (200) lẹ́yìn tí ó bí Náhórì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

24 Nígbà tí Náhórì pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29), ó bí Tẹ́rà.

25 Ó sì wà láàyè fún ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́fà (119) lẹ́yìn ìbí Tẹ́rà, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

26 Lẹ́yìn tí Tẹ́rà pé ọmọ àádọ́rin ọdún (70) ó bí Ábúrámù, Náhórì àti Háránì.

27 Wọ̀nyí ni ìran Tẹ́rà: Tẹ́rà ni baba Ábúrámù, Náhórì àti Áránì, Áránì sì bí Lọ́tì.

28 Áránì sì kú ṣáájú Tẹ́rà baba rẹ̀ ní ilẹ̀ ìbí rẹ̀ ní Úrì ti ilẹ̀ Kálídéà.

29 Ábúrámù àti Náhórì sì gbéyàwó. Orúkọ aya Ábúrámù ni Sáráì, nígbà tí aya Náhórì ń jẹ́ Mílíkà, tí ṣe ọmọ Áránì. Áránì ni ó bí Mílíkà àti Ísíkà.

30 Sáráì sì yàgàn, kò sì bímọ.

31 Tẹ́rà sì mú ọmọ rẹ̀ Ábúrámù àti Lọ́tì ọmọ Áránì, ọmọ-ọmọ rẹ̀, ó sì mú Sáráì tí i ṣe aya ọmọ rẹ̀. Ábúrámù pẹ̀lú, gbogbo wọn sì jáde kúrò ní Úrì ti Kálídéà láti lọ sí ilẹ̀ Kénánì. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn dé Áránì wọ́n tẹ̀dó síbẹ̀.

32 Nígbà tí Tẹ́rà pé ọmọ igba ó lé márùn-ún ọdún (205) ni ó kú nì Áránì