1 Nítorí náà Ísáákì pe Jákọ́bù, ó sì súre fún un, ó sì pàṣẹ fún un pé; “Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ aya láàrin àwọn ọmọbìnrin Kénánì.
2 Dípò bẹ́ẹ̀ lọ sí Padani-Árámù, sí ilé Bétúélì, baba ìyá rẹ, kí ìwọ kí ó sì fẹ́ aya fún ara rẹ nínú àwọn ọmọbìnrin Lábánì arákùnrin ìyá rẹ.
3 Kí Ọlọ́run Olódùmarè kí ó bùkún fún ọ, kí ó sì mú ọ bí sí i, kí ó sì mú ọ pọ̀ sí i ní iye títí tí ìwọ yóò di àgbájọ àwọn ènìyàn.
4 Kí Ọlọ́run kí ó fún ìwọ àti irú ọmọ rẹ ní ìre tí ó sú fún Ábúráhámù, kí ìwọ kí ó le gba ilẹ̀ níbi tí a ti ń ṣe àtìpó yìí, ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún Ábúráhámù.”
5 Bẹ́ẹ̀ ni Ísáákì sì rán Jákọ́bù lọ. Ó sì lọ sí Padani-Árámù, lọ́dọ̀ Lábánì ọmọ Bétúélì, ará Árámíà, tí í ṣe arákùnrin Rèbékà ìyá Jákọ́bù àti Ísọ̀.
6 Nígbà tí Ísọ̀ gbọ pé, Ísáákì ti ṣúre fún Jákọ́bù, ó sì ti ran Jákọ́bù lọ sí Padani-Árámù láti fẹ́ aya níbẹ̀ àti pé nígbà tí ó ṣúre fún un, ó kìlọ̀ fun un pé, kò gbọdọ̀ fẹ́ nínú àwọn ọmọbìnrin Kénánì
7 àti pé, Jákọ́bù ti gbọ́ràn sí ìyá àti baba rẹ̀ lẹ́nu, ó sì ti lọ sí Padani-Árámù.
8 Nígbà náà ni Ísọ̀ mọ bí Ísáákì baba rẹ ti kórìíra àwọn ọmọbìnrin Kénánì tó.
9 Nítorí náà ó tọ Íṣímáélì lọ, ó sì fẹ́ Máhálátì, arábìnrin Nébájótù, ọmọbìnrin Ísímáélì tí í ṣe ọmọ Ábúráhámù. Ó fẹ́ ẹ, kún àwọn ìyàwó tí ó ti ní tẹ́lẹ̀
10 Jákọ́bù kúrò ní Bíáṣébà, ó sì kọrí sí ìlú Áránì.
11 Nígbà tí ó dé ibìkan, ó dúró ní òru náà nítorí tí ilẹ̀ ti ń sú, ó sì gbé òkúta kan ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn.
12 Ó sì lá àlá pé, a gbé àkàsọ̀ kan dúró ti ó fi ìdí lélẹ̀, orí rẹ̀ sì kan ọ̀run, àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run sì ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀.
13 Olúwa sì dúró lókè rẹ̀, ó sì wí pé, “Èmi ni Olúwa, Ọlọ́run Baba rẹ Ábúráhámù àti Ọlọ́run Ísáákì, ìwọ àti ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ tí ìwọ dùbúlẹ̀ sórí rẹ̀ yìí fún.
14 Ìran rẹ yóò pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ìwọ yóò sì tànkálẹ̀ dé ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn, àti dé gúsù àti àríwá. A ó sì bùkún gbogbo orílẹ̀ èdè ayé nípaṣẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ.
15 Èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì pa ọ mọ́ ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmi yóò sì mú ọ padà wá sí ilẹ̀ yìí ní àlàáfíà. Èmi kì yóò fi ọ sílẹ̀ ní ìgbà kan, títí tí èmi yóò fi mú gbogbo ìlérí mi ṣẹ.”
16 Nígbà tí Jákọ́bù jí lójú oorun rẹ̀, ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Dájúdájú Olúwa ń bẹ ní ìhín yìí, èmi kò sì mọ̀.”
17 Ẹ̀rù sì bà á, ó sì wí pé, “Ìhín yìí ní ẹ̀rù gidigidi; Ibí kì í ṣe ibòmíràn bí kò ṣe ilé Ọlọ́run, àní ẹnu ibodè ọ̀run nìyìí”
18 Jákọ́bù sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì gbé òkúta tí ó fi ṣe ìrọ̀rí lélẹ̀ bí òpó, ó sì da òróró si lórí.
19 Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì (Ilé Ọlọ́run) bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú náà ń jẹ́ Lúsì tẹ́lẹ̀ rí.
20 Jákọ́bù sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ níbẹ̀ pé, “Bí Ọlọ́run yóò bá wà pẹ̀lú mi, tí yóò sì pa mí mọ́ ní ìrìnàjò mi tí mo ń lọ, tí yóò sì fún mi ní oúnjẹ láti jẹ àti aṣọ láti wọ̀,
21 tí mo sì padà sílé baba mi ní àlàáfíà, nígbà náà Olúwa ni yóò jẹ́ Ọlọ́run mi,
22 Òkúta yìí tí mo gbé kalẹ̀ bí ọ̀wọ̀n yóò jẹ́ ilé Ọlọ́run, gbogbo ohun tí O bá sì fún mi, èmi yóò fún Ọ ní ìdámẹ́wàá rẹ̀.”