1 Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí, ni agbọ́tí ọba àti alásè rẹ̀ ṣẹ ọba Éjíbítì, olúwa wọn.
2 Fáráò sì bínú sí méjì nínú àwọn ìjòyè rẹ̀, olórí agbọ́tí àti olórí alásè,
3 Ó sì fi wọ́n sí ìhámọ́ ní ilé olórí ẹ̀sọ́, ní inú ẹ̀wọ̀n ibi tí Jósẹ́fù pẹ̀lú wà.
4 Olórí ẹ̀sọ́ sì yan Jósẹ́fù láti máa ṣe ìránṣẹ́ wọn.Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wà ní ìhámọ́ fún ìgbà díẹ̀.
5 Ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọkùnrin méjèèjì náà-olórí agbọ́tí àti olórí alásè lá àlá, ní òru kan náà, àlá kọ̀ọ̀kan sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀.
6 Nígbà tí Jósẹ́fù dé ọ̀dọ̀ wọn ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó ṣe àkíyèsí pé, inú wọn kò dùn.
7 Ó sì bi àwọn ìjòyè Fáráò tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìhámọ́, nínú ilé olúwa rẹ̀ léèrè pé, “Èéṣe tí ojú yín fi fàro bẹ́ẹ̀ ní òní, tí inú yín kò sì dùn?”
8 Wọ́n wí pé, “Àwa méjèèjì ni a lá àlá, kò sì sí ẹni tí yóò túmọ̀ rẹ̀.”Jósẹ́fù sì wí fún wọn pé, “Ọlọ́run nìkan ni ó ni ìtúmọ̀. Ẹ sọ àwọn àlá yín fún mi.”
9 Olórí agbọ́tí sì ṣọ́ àlá rẹ̀ fún Jósẹ́fù, wí pé, “Ní ojú àlá mi, mo rí àjàrà kan (tí wọn ń fi èso rẹ̀ ṣe wáìnì) níwájú mi,
10 Mo sì rí ẹ̀ka mẹ́ta lórí àjàrà náà, ó yọ ẹ̀ka tuntun, ó sì tanná, láìpẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní í ní èso tí ó ti pọ́n.
11 Ife Fáráò sì wà lọ́wọ́ mi, mo sì mú àwọn èṣo àjàrà náà, mo sì fún un sínú ife Fáráò, mo sì gbé ife náà fún Fáráò.”
12 Jósẹ́fù wí fún-un pé, “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ. Ẹ̀ka mẹ́ta náà dúró fún ọjọ́ mẹ́ta.
13 Láàrin ọjọ́ mẹ́ta Fáráò yóò mú ọ jáde nínú ẹ̀wọ̀n padà sí ipò rẹ, ìwọ yóò sì tún máa gbọ́tí fún-un, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ àtẹ̀yìnwá.
14 Ṣùgbọ́n nígbà tí ohun gbogbo bá dára fún ọ, rántí mi kí o sì fi àánú hàn sí mi. Dárúkọ mi fún Fáráò, kí o sì mú mi jáde kúrò ní ìhín.
15 Nítorí á jí mi gbé tà kúrò ní ilẹ̀ àwọn Ébérù ni, àti pé níhìnín èmi kò ṣe ohunkóhun tí ó fi yẹ kí èmi wà ní ìhámọ́ bí mo ti wà yìí.”
16 Nígbà tí olórí alásè rí i wí pé ìtúmọ̀ tí Jósẹ́fù fún àlá náà dára, ó wí fún Jósẹ́fù pé, “Èmi pẹ̀lú lá àlá: Mo ru agbọ̀n oúnjẹ mẹ́ta lórí,
17 Nínú agbọ̀n tí ó wà lókè, onírúurú oúnjẹ ló wà níbẹ̀ fún Fáráò, ṣùgbọ́n àwọn ẹyẹ sì ń ṣà wọ́n jẹ láti inú apẹ̀rẹ̀ náà tí ó wà lórí mi”
18 Jósẹ́fù dáhùn, “Èyí ni ìtúmọ̀ àlá rẹ. Agbọ̀n mẹ́ta náà túmọ̀ sí ọjọ́ mẹ́ta.
19 Láàrin ọjọ́ mẹ́ta, Fáráò yóò tú ọ sílẹ̀, yóò sì bẹ́ orí rẹ, yóò sì gbé ara rẹ kọ́ sí orí igi. Àwọn ẹyẹ yóò sì jẹ ara rẹ.”
20 Ọjọ́ kẹ́ta sì jẹ́ ọjọ́ ìbí Fáráò, ó sì ṣe àsè fún gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀. Ó sì mú olórí agbọ́tí àti olórí aláṣè jáde kúrò nínú ẹ̀wọ̀n.
21 Ó dá olórí agbọ́tí padà sí ipò tí ó wà tẹ́lẹ̀, kí ó ba à le máa ṣe iṣẹ́ rẹ̀ bí i ti àtẹ̀yìnwa,
22 Ṣùgbọ́n, ó so olórí alásè kọ́ sórí igi, gẹ́gẹ́ bí Jósẹ́fù ti sọ fún wọn nínú ìtúmọ̀ rẹ̀ sí àlá wọn.
23 Ṣùgbọ́n, olórí agbọ́tí kò rántí Jósẹ́fù mọ́, kò tilẹ̀ ronú nípa rẹ̀.