Jẹ́nẹ́sísì 49 BMY

Ọ̀rọ̀ Ìkẹyìn Jákọ́bù Sí Àwọn Ọmọ Rẹ̀

1 Nígbà náà ni Jákọ́bù ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí n le è sọ ohun tí yóò sẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú fún-un yín.

2 “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí ẹ sì tẹ́tí, ẹ̀yin ọmọ Jákọ́bù;Ẹ fetí sí Ísírẹ́lì baba yín.

3 “Rúbẹ́nì, ìwọ ni àkọ́bí mi,agbára mi, ìpìlẹṣẹ̀ ipá mi,títayọ ní ọlá àti títayọ ní agbára.

4 Ẹni ríru bí omi òkun, ìwọ kì yóò tayọ mọ́,nítorí pé ìwọ gun ibùsùn baba rẹ,lórí àkéte mi, ìwọ sì bà á jẹ́(ìwọ bá ọ̀kan nínú àwọn aya baba rẹ lò pọ̀).

5 “Símónì àti Léfì jẹ́ arákùnrin—idà wọn jẹ́ ohun èlò ogun alágbára.

6 Kí ọkàn mi má ṣe ni àṣepọ̀ pẹ̀lú wọn,kí n má sì ṣe dúró níbí ìpéjọpọ̀ wọn,nítorí wọ́n ti pa àwọn ènìyàn ní ìbínú wọn,wọ́n sì da àwọn màlúù lóró bí ó ti wù wọ́n.

7 Ìfibú ni ìbínú wọn nítorí tí ógbóná púpọ̀, àti fún ìrunú wọn nítorí tí ó kún fún ìkà.Èmi yóò tú wọn ká ní Jákọ́bù,èmi ó sì fọ́n wọn ká ní Ísírẹ́lì.

8 “Júdà, àwọn arákùnrin rẹ yóò yìn ọ,ọwọ́ rẹ yóò wà ní ọrùn àwọn ọ̀ta rẹ,àwọn ọmọkùnrin baba rẹ yóò foríbalẹ̀ fún ọ.

9 Ọmọ kìnnìún ni ọ́, ìwọ Júdà,o darí láti ìgbẹ́ ọdẹ, ọmọ mi.Bí i kìnnìún, o ba mọ́lẹ̀, o sì sùn sílẹ̀ bí i abo kìnnìún,Ta ni ó tó bẹ́ẹ̀, kí o lé e dìde?

10 Ọ̀pá oyè kì yóò kúrò ní Júdàbẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá-ìsàkóso kì yóò kúròláàrin ẹṣẹ̀ rẹ̀, títí tí ẹni tí ó ni í yóò fi dé,tí gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè yóò máa wárí fún un.

11 Yóò má ṣo ọmọ ẹsin rẹ̀ mọ́ igi àjàrà àtiọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ mọ́ ẹ̀ka tí ó dára jù.Yóò fọ aṣọ rẹ̀ nínú wáìnì àti ẹ̀wùrẹ̀ nù nínú omi-pupa ti eṣo àjàrà (gíréèpù).

12 Ojú rẹ̀ yóò rẹ̀ dòdò ju wáìnì lọ,ẹyín rẹ yóò sì funfunu pẹ̀lú omi-ọyàn

13 “Ṣébúlúnì yóò máa gbé ní etí òkun,yóò sì jẹ́ èbúté fún ọkọ̀ ojú omi,agbégbé rẹ yóò tàn ká títí dé Ṣídónì.

14 “Ísákárì jẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ alágbáratí ó sùn sílẹ̀ láàrin àpò ẹrù méjì.

15 Nígbà tí ó bá rí bí ibi ìsinmi òun ti dára tó,àti bí ilẹ̀ rẹ̀ ti ní ìdẹ̀ra tó,yóò tẹ èjìká rẹ̀ ba láti ru àjàgà,yóò sì fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ipá.

16 “Dánì yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.

17 Dánì yóò jẹ́ ejo ni pópónààti paramọ́lẹ̀ ní ẹ̀bá ọ̀nà,tí ó bu ẹsin jẹ ní ẹṣẹ̀,kí ẹni tí n gùn-un bá à le è subú sẹ́yìn.

18 “Mo ń dúró de ìtúsilẹ̀ rẹ, Olúwa

19 “Ẹgbẹ́-ogun àwọn ẹlẹ́sin yóò kọ lu Gádì,ṣùgbọ́n yóò kọ lu wọ́n ní gìgíṣẹ̀ wọn.

20 “Oúnjẹ Áṣérì yóò dára;yóò ṣe àṣè tí ó yẹ fún ọba.

21 “Náfútalì yóò jẹ́ abo àgbọ̀nríntí a tú sílẹ̀ tí ó ń bí ọmọ daradara.

22 “Jóṣẹ́fù jẹ́ àjàrà eléṣo,àjàrà eléṣo ní etí odò,tí ẹ̀ka rẹ̀ gun orí odi.

23 Pẹ̀lú ìkorò,àwọn tafàtafà dojú ìjà kọ ọ́,wọ́n tafà sí í pẹ̀lú ìkanra,

24 Ṣùgbọ́n ọrun rẹ̀ dúró ni agbára,ọwọ́ agbára rẹ̀ ni a sì mu lára le,nítorí ọwọ́ alágbára Jákọ́bù,nítorí olútọ́jú àti aláàbò àpáta Ísírẹ́lì.

25 Nítorí Ọlọ́run baba rẹ tí ó ràn ọ́ lọ́wọ́,nítorí Olódùmarè tí ó bù kún ọ,pẹ̀lú láti ọ̀run wá,ìbùkún ọ̀gbìn tí ó wà ní ìṣàlẹ̀,ìbùkún ti ọmú àti ti inú,

26 ìbùkún baba rẹ pọ̀ púpọ̀ju ìbùkún àwọn òkè ńlá ìgbàanì,ju ẹ̀bùn ńlá àwọn òkè láéláé.Jẹ́ kí gbogbo èyí sọ̀kalẹ̀ sí orí Jóṣẹ́fù,lé ìpéǹpéjú ọmọ aládé láàrin arákùnrin rẹ̀.

27 “Bẹ́ńjámínì jẹ́ ìkookò tí ó burú.Ní òwúrọ̀ ni ó jẹ ẹran-ọdẹ rẹ,ní àsáálẹ́, ó pín ìkógun.”

28 Gbogbo ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá, èyí sì ni ohun tí baba wọn sọ fún wọn nígbà tí ó súre fún wọn, tí ó sì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ìbùkún tí ó tọ́ sí i.

Ikú Jákọ́bù

29 Nígbà náà ni ó fún wọn ní àwọn ìlànà yìí, “Ọjọ́ ikú mi kù fẹ́ẹ́fẹ́. Kí ẹ sin mí sí ibojì pẹ̀lú àwọn baba mi ní inú àpáta ní ilẹ̀ Hítì ará Éfúrónì.

30 Ihò àpáta tí ó wà ní ilẹ̀ Mákípélà, nítòsí Mámúrè ní Kénánì, èyí tí Ábúráhámù rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀-ìsìnkú lọ́wọ́ Éfúrónì ará Hétì pẹ̀lú ilẹ̀ rẹ̀.

31 Níbẹ̀ ni a sin Ábúráhámù àti aya rẹ̀ Ṣárà sí, níbẹ̀ ni a sin Ísáákì àti Rèbékà aya rẹ̀ sí, níbẹ̀ sì ni mo sìnkú Líà sí.

32 Ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni a rà lọ́wọ́ ará Hítì.”

33 Nígbà tí Jákọ́bù ti pàṣẹ yìí fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó gbé ẹṣẹ rẹ̀ sókè sórí ibùsùn, ó sì kú, a sì ko jọ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.