Jẹ́nẹ́sísì 32 BMY

Jákọ́bù Gbáradì Láti Pàdé Éṣáù

1 Jákọ́bù sì ń bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ, àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀.

2 Nígbà tí Jákọ́bù rí wọn, ó wí pé, “Àgọ́ Ọlọ́run nìyi!” Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ni Máhánáímù.

3 Jákọ́bù sì rán àwọn oníṣẹ́ ṣáájú ara rẹ̀ sí Ísọ̀ arákùnrin rẹ̀ ni ilẹ̀ Ṣéírì ní orílẹ̀-èdè Édómù.

4 Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀yin yóò wí fún Ísọ̀ olúwa mi, Jákọ́bù ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé, ‘Mo ti ṣe àtìpó lọ́dọ̀ Lábánì títí ó fi di àṣìkò yìí

5 Mo ní màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn àti ewúrẹ́. Mo tún ni àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin. Mo ń ránṣẹ́ yìí sí olúwa mi kí èmi le è rí ojúrere rẹ.’ ”

6 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà padà tọ Jákọ́bù wà, wọ́n wí pé “Ísọ̀ arákùnrin rẹ ti múra láti wá pàdé rẹ pẹ̀lú irinwó (400) ọkùnrin.”

7 Pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìbànújẹ́ ni Jákọ́bù fi pín àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìpín méjì, ó sì pín àwọn ẹran ọ̀sìn, agbo ẹran àti ràkúnmí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.

8 Nítorí ó rò ó nínú rẹ̀ pé, “Bí Ísọ̀ bá kọjú ogun sí ìpín kan, ìpín kejì yóò sá àsálà.”

9 Nígbà náà ni Jákọ́bù gbàdúrà pe, “Ọlọ́run Ábúráhámù baba mi, àti Ọlọ́run Ísáákì baba mi, Olúwa tí ó wí fún mi pé, ‘Padà sí orílẹ̀-èdè rẹ àti sọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, Èmi yóò sì ṣe ọ́ ní rere,’

10 Èmi kò tilẹ̀ yẹ fún àánú àti òtítọ́ tí o ń fi hàn fún ìránṣẹ́ rẹ. Nítorí pé, kìkì ọ̀pá mi ni mo mu kúrò ni ilé kọjá Jọ́dánì yìí, ṣùgbọ́n nísin yìí, èmi ti di ẹgbẹ́ méjì.

11 Jọ̀wọ́ Olúwa gbà mí lọ́wọ́ Ísọ̀ arákùnrin mi, nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé yóò wá dojú ìjà kọ mí àti àwọn ìyàwó pẹ̀lú àwọn ọmọ mi.

12 Ṣùgbọ́n ìwọ ti ṣèlérí pé, ‘Èmi yóò mú ọ gbilẹ̀, èmi yóò sì mú kí àwọn ìran rẹ dà bì í yanrìn òkun tí ẹnikẹ́ni kò le è kà.’ ”

13 Ó sì lo òru ọjọ́ náà níbẹ̀. Ó mú ẹ̀bùn fún arákùnrin rẹ̀ nínú ohun ìní rẹ̀.

14 Igba ewúrẹ́ (200), ogún (20) òbúkọ, igba (200) àgùntàn, ogún (20) àgbò,

15 Ọgbọ̀n (30) abo ràkunmí pẹ̀lú ọmọ wọn, ogójì (40) abo màlúù àti akọ màlúù mẹ́wàá (10), ogún (20) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá (10).

16 Ó sì fi wọ́n lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣáájú mi, kí ẹ sì jẹ́ kí àlàfo wà láàrin ọ̀wọ́ agbo ẹran kọ̀ọ̀kan sí èkeji.”

17 Ó pàṣẹ fún èyí tí ó ṣáájú pé, “Nígbà tí arákùnrin mi Ísọ̀ bá pàdé rẹ tí ó sì béèrè ẹni tí ìwọ í ṣe àti ibi tí ìwọ ń lọ àti ẹni tí ó ni agbo ẹran tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ,

18 Nígbà náà ni ìwọ yóò wí pé, ‘Ti ìránṣẹ́ rẹ Jákọ́bù ni wọ́n. Ẹ̀bùn ni ó sì fi wọ́n ṣe fún Ísọ̀ olúwa mi, òun pàápàá ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’ ”

19 Jákọ́bù sì pàṣẹ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ fún ọ̀wọ́ kejì àti ẹ̀kẹta àti àwọn tókù tí ó tẹ̀lé agbo ẹran pé, “Ohun kan ṣoṣo yìí náà ni kí ẹ sọ fún Ísọ̀ nígbà tí ẹ bá pàdé rẹ̀.

20 Kí ẹ rí i dájú wí pé, ẹ sọ fún-un pé, ‘Jákọ́bù ìránṣẹ́ rẹ̀ ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’ ” Èrò Jákọ́bù ni láti fi àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí tu Ísọ̀ lójú pé bóyá inú Ísọ̀ yóò dùn sí òun nígbà tí àwọn bá pàdé.

21 Nítorí náà ẹ̀bùn Jákọ́bù ṣáájú rẹ̀ lọ, Jákọ́bù pàápàá sì lo òru ọjọ́ náà nínú àgọ́

Jákọ́bù Láti Bá Ọlọ́run Ja Ìjàkadì:

22 Ó sì dìde ní òru ọjọ́ náà, ó mú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ méjèèjì, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mọ́kọ̀ọ̀kànlá, wọ́n sì kọjá ní ìwọdò Jábókù.

23 Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti rán wọn kọjá odò tán sí òkè-odò, ó sì rán àwọn ohun-ìní rẹ̀ kọjá pẹ̀lú.

24 Ó sì ku Jákọ́bù nìkan, ọkùnrin kan sì báa ja ìjàkadì títí ó fi di àfẹ̀mọ́jú.

25 Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé òun kò le borí Jákọ́bù, ó fọwọ́ kan-án ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀, egungun náà sì yẹ̀ kúrò lórí ìké, bí ó ti ń ja ìjàkadì.

26 Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń máa lọ, nítorí ojúmọ́ ti mọ́.”Ṣùgbọ́n Jákọ́bù dá a lóhùn pé, “Èmi kò ní jẹ́ kí o lọ, àyàfi bí o bá súre fún mi.”

27 Ọkùnrin náà béèrè orúkọ rẹ̀.Ó sì wí fún un pé, “Jákọ́bù ni òun ń jẹ́.”

28 Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí pé, “Orúkọ rẹ kì yóò jẹ́ Jákọ́bù mọ́ bí kò ṣe Ísírẹ́lì, nítorí pé ìwọ ti bá Ọlọ́run àti ènìyàn jà, o sì borí.”

29 Jákọ́bù sì bẹ ọkùnrin náà pé, “Sọ orúkọ rẹ fún mi.”Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà ṣáà dáhùn pé, “Èéṣe tí o n béèrè orúkọ mi?” Lẹ́yìn náà ó ṣúre fún Jákọ́bù níbẹ̀.

30 Jákọ́bù sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Pẹ́núẹ́lì pé, “Mo rí Ọlọ́run ní ojúkojú, ṣíbẹ̀ a dá ẹ̀mí mi sí.”

31 Bí ó sì ti ń kọjá Pẹ́núẹ́lì, oòrùn ràn bá a, ó sì ń tiro nítorí itan rẹ̀.

32 Ìdí nìyí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kì í fií jẹ iṣan tí ó wà ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀ títí di òní-olónìí, nítorí níbi iṣan náà ni a ti fọwọ́ kan ibi tí egungun itan Jákọ́bù ti bẹ̀rẹ̀.