Jẹ́nẹ́sísì 36 BMY

Àwọn Ìránṣẹ́ Ísọ̀:

1 Wọ̀nyí ni ìran Ísọ̀, ẹni tí a ń pè ní Édómù.

2 Nínú àwọn ọmọbìnrin Kénánì ni Ísọ̀ ti fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀: Ádà ọmọbìnrin Élónì ará Hítì àti Óhólíbámà, ọmọbìnrin Ánà, ọmọ ọmọ Ṣíbéónì ará Hífítì.

3 Ó sì tún fẹ́ Báṣémátì ọmọ Ísímáélì arábìnrin Nébájótù.

4 Ádà bí Élífásì fún Ísọ̀, Báṣémátì sì bí Réúẹ́lì,

5 Óhólíbámà pẹ̀lú sì bí Jéúsì, Jálámù, àti Kórà. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Ísọ̀ bí ní Kénánì.

6 Ísọ̀ sì mú àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ àti àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn àti gbogbo ohun ìní mìíràn tí ó ní, ni Kénánì, ó sì kó lọ sí ilẹ̀ mìíràn, jìnà sí ibi tí Jákọ́bù arakùnrin rẹ̀ wà.

7 Ohun ìní wọn pọ̀ ju èyí tí àwọn méjèèjì lè máa gbé ní ojúkan lọ. Ilẹ̀ tí wọ́n wà kò le gba àwon méjèèjì nítorí àwọn ohun ọ̀sìn wọn.

8 Báyìí ni Ísọ̀ tí a tún mọ̀ sí Édómù tẹ̀dó sí àwọn orílẹ̀ èdè oloke tí Ṣéírì.

9 Èyí ni ìran Ísọ̀ baba àwọn ará Édómù ní àwọn orílẹ̀ èdè olókè Ṣéírì.

10 Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Ísọ̀:Élífásì ọmọ Ádà aya Ísọ̀ àti Rúélì, ọmọ Báṣémátì tí í ṣe aya Ísọ̀ pẹ̀lú.

11 Àwọn ọmọ Élífásì ni ìwọ̀nyí:Témánì, Ómárì, Ṣéfò, Gátamù, àti Kénásì.

12 Élífásì ọmọ Ísọ̀ sì tún ní àlè tí a ń pè ní Tímúnà pẹ̀lú, òun ló bí Ámálékì fún un. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ-ọmọ Ádà aya Ísọ̀.

13 Àwọn ọmọ Rúélì:Náhátì, Ṣérà, Ṣámà àti Mísà. Àwọn ni ọmọ-ọmọ Báṣémátì aya Ísọ̀.

14 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Óhólíbámà ọmọbìnrin Ánà ọmọ-ọmọ Ṣíbéónì: tí ó bí fún Ísọ̀:Jéúsì, Jálámì àti Kórà.

15 Wọn wọ̀nyí ni olórí nínú àwọn ọmọ Ísọ̀:Àwọn ọmọ Élífásì, àkọ́bí Ísọ̀:Témánì, Ómárì, Ṣéfò, Kénásíà,

16 Kórà, Gátamù àti Ámálékì. Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Élífásì ní Édómù wá, wọ́n jẹ́ ọmọ-ọmọ Ádà.

17 Wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Rúélì,Náhátì, Ṣérátì, Ṣámò àti Mísà. Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Rúélì jáde ní Édómù. Ọmọ-ọmọ Básémátì aya Ísọ̀ ni wọ́n jẹ́.

18 Àwọn ọmọ Óhólíbámà aya Ísọ̀:Jéúsì, Jálámì, àti Kórà, àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olorí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Óhólíbámà ọmọ Ánà, ìyàwó Ísọ̀ wá.

19 Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ísọ̀ (Édómù). Àwọn wọ̀nyí ni olórí wọn.

20 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ṣéírì ara Hórì tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà:Lótanì, Ṣóbálì, Ṣíbéónì, Ánà

21 Dísónì, Éṣérì, àti Díṣánì, àwọn wọ̀nyìí ọmọ Ṣéírì ni Édómù.

22 Àwọn ọmọ Lótanì:Órì àti Ómámù: Arábìnrin Lótanì sì ni Tímínà.

23 Àwọn ọmọ Ṣóbálì:Álífánì, Mánáhátì, Ébálì, Ṣéfò àti Onámù.

24 Àwọn ọmọ Ṣíbéónì:Áíyà àti Ánà. Èyí ni Ánà tí ó rí ìṣun omi gbígbóná ní inú asálẹ̀ bí ó ti ń da àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Ṣébéónì baba rẹ̀.

25 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ánà:Dísónì àti Óhólíbámà (Àwọn ọmọbìnrin ni wọn).

26 Àwọn ọmọ Dísónì ni:Hémídánì, Ésíbánì, Ítíránì àti Kéránì.

27 Àwọn ọmọ Éṣérì:Bílíhánì, Ṣááfánì, àti Ákánì.

28 Àwọn ọmọ Díṣánì ni Húsì àti Áránì.

29 Àwọn wọ̀nyí ni olórí ìdílé Hórì:Lótanì, Ṣóbálì, Ṣíbéónì, Áná,

30 Dísónì Éṣérì, àti Díṣánì. Àwọn ni olórí ìdílé àwọn ará Órì gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní ilẹ̀ Ṣéírì.

Àwọn Aláṣẹ Édómù:

31 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọba tí ó ti jẹ ní Édómù kí ó tó di pé a ń jẹ ọba ní Ísírẹ́lì rárá:

32 Bẹ́là ọmọ Béórì jẹ ní Édómù. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Díníhábà.

33 Nígbà tí Bẹ́là kú, Jóbábù ọmọ Ṣérà ti Bósírà sì jọba ní ipò rẹ̀.

34 Nígbà tí Jóbábù kú, Úṣámù láti ilẹ̀ Témánì sì jọba ní ipò rẹ̀.

35 Nígbà tí Húṣámù kú, Hádádì ọmọ Bédádì tí ó ṣẹ́gun Mídíánì ní orílẹ̀ èdè Móábù sì jọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Áfítì.

36 Lẹ́yìn ikú Ádádì, Ṣámílà tí ó wá láti Másírékà ni ó jọba lẹ́yìn rẹ̀.

37 Sámílà sì kú, Ṣáúlì ti Réhóbótì, létí odò sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

38 Nígbà tí Sáúlì kú, Báálì-Hánánì ọmọ Ákíbórì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

39 Nígbà tí Baali-Hánánì ọmọ Ákíbórì kú, Ádádì ni ó jọba lẹ́yìn rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Páù, Méhétà-bélì ọmọbìnrin Mátírédì àti ọmọ-ọmọ Mé-ṣáhábù ni ìyàwó rẹ̀.

40 Àwọn wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ìjòyè tí ó ti ọ̀dọ̀ Ísọ̀ jáde wá, ní orúkọ ìdílé wọn, bí ìpínlẹ̀ wọn ti rí:Tínínà, Álífánì, Jététì.

41 Ohólíbámà, Élà, Pínónì,

42 Kénásì, Témáínì Míbísárì,

43 Mágídíélì, àti Írámù. Àwọn wọ̀nyí ni olóyè Édómù, gẹ́gẹ́ bí wọn ti tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí wọ́n gbà.Èyí ni Ísọ̀ baba àwọn ará Édómù.