Jẹ́nẹ́sísì 46 BMY

Jákọ́bù lọ sí Éjíbítì

1 Báyìí ni Ísírẹ́lì mú ìrìn-àjò rẹ̀ pọ̀n pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ní, nígbà tí ó sì dé Báá-Ṣébà, ó rúbọ sí Ọlọ́run Ísáákì baba rẹ̀.

2 Ọlọ́run sì bá Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ ní ojú ìrán ní òru pé, “Jákọ́bù! Jákọ́bù!”Ó sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

3 Ọlọ́run sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run, Ọlọ́run baba rẹ, má ṣe bẹ̀rù láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Éjíbítì nítorí, èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá níbẹ̀.

4 Èmi yóò sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ lọ sí Éjíbítì, èmi yóò sì tún mú ọ pada wá. Ọwọ́ Jósẹ́fù fúnra rẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí.”

5 Nígbà náà ni Jákọ́bù kúrò ní Báá-Ṣébà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì mú Jákọ́bù bàbá wọn àti àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì kó wọn sí inú kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Fáráò fí ránsẹ́ fún ìrìn-àjò rẹ̀:

6 Wọ́n tún kó àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun-ìní tí wọ́n ti ní láti ilẹ̀ Kénánì, Jákọ́bù àti gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì.

7 Ó kó àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ obìnrin-gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ lọ sí Éjíbítì.

8 Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (Jákọ́bù àti Ìran rẹ̀) tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ Éjíbítì:Rúbẹ́nì àkọ́bí Jákọ́bù.

9 Àwọn ọmọkùnrin Rúbẹ́nì:Ánókù, Pálù, Ésírónì àti Kámì

10 Àwọn ọmọkùnrin Símónì:Jémúélì, Jámínì, Óhádì, Jákínì, Ṣóhárì àti Ṣáúlì, tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọbìnrin ará Kénánì.

11 Àwọn ọmọkùnrin Léfì:Gáṣónì, Kóhátì àti Mérárì.

12 Àwọn ọmọkùnrin Júdà:Ẹ́rì, Ónánì, Ṣélà, Pérésì àti Ṣérà (ṣùgbọ́n Ẹ́rì àti Ónánì ti kú ní ilẹ̀ Kénánì).Àwọn ọmọ Pérésì:Ésírónì àti Ámúlù.

13 Àwọn ọmọkùnrin Ísákárì!Tólà, Pútà, Jásíbù àti Ṣímírónì.

14 Àwọn ọmọkùnrin Ṣébúlúnì:Ṣérédì, Élónì àti Jáhálélì.

15 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Líà tí ó bí fún Jákọ́bù ní Padani-Árámù yàtọ̀ fún Dínà ọmọbìnrin rẹ̀. Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ mẹ́talélọ́gbọ̀n. (35) lápapọ̀.

16 Àwọn ọmọkùnrin Gádì:,Ṣífónì, Ágì, Ṣúnì, Ésíbónì, Érì, Áródì, àti Árélì.

17 Àwọn ọmọkùnrin Ásérì:Ímínà, Íṣífà, Íṣífì àti Béríà. Arábìnrin wọn ni Ṣérà.Àwọn ọmọkùnrin Béríà:Ébérì àti Málíkíélì.

18 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Jákọ́bù bí nípaṣẹ̀ Ṣílípà, ẹni tí Lábánì fi fún Líà ọmọbìnrin rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìndínlógún (16) lápapọ̀.

19 Àwọn ọmọkùnrin Rákélì aya Jákọ́bù:Jósẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì.

20 Ní Éjíbiti, Áṣénátù ọmọbìnrin Pọ́tíférà, alábojútó àti àlùfáà Ónì, bí Mánásè àti Éfúráímù fún Jósẹ́fù.

21 Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì:Bélà, Békérì, Áṣíbélì, Gérà, Náámánì, Éhì, Rósì, Múpímù, Húpímù àti Árídà.

22 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Rákẹ́lì bí fún Jákọ́bù. Wọ́n jẹ́ mẹ́rìnlá (14) lápapọ̀.

23 Àwọn ọmọ Dánì:Úsímù.

24 Àwọn ọmọ Náfítalì:Jáháṣíè, Gúnì, Jésérì, àti Ṣílémù.

25 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Bílíhà ẹni tí Lábánì fi fún Rákélì ọmọ rẹ̀ bí fún Jákọ́bù. Wọ́n jẹ́ méje lápapọ̀.

26 Gbogbo àwọn tí ó lọ pẹ̀lú Jákọ́bù sí Éjíbítì, àwọn tí ó jẹ́ ìran rẹ̀ tààrà láì ka àwọn aya ọmọ rẹ̀, jẹ́ ènìyàn mẹ́rìndín-ní-àadọ́rin (66).

27 Pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin méjì tí a bí fún Jósẹ́fù ní Éjíbítì àwọn ará ilé Jákọ́bù tí ó lọ sí Éjíbítì jẹ́ àádọ́rin (70) lápapọ̀

28 Jákọ́bù sì rán Júdà ṣáájú rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Jósẹ́fù, kí wọn báà le mọ ọ̀nà Gósénì. Nígbà tí wọ́n dé agbégbé Gósénì,

29 Jósẹ́fù tọ́jú kẹ̀kẹ́-ẹsin rẹ̀ ó sì lọ sí Gósénì láti pàdé Ísírẹ́lì baba rẹ̀. Bí Jósẹ́fù ti dé iwájú baba rẹ̀, ó dì mọ́ baba rẹ̀ ó sì sunkún fún ìgbà pípẹ́.

30 Ísírẹ́lì wí fún Jósẹ́fù pé, “Wàyí o, mo le kú, níwọ̀n bí mo ti rí i fún ara a mi pé, o wà láàyè ṣíbẹ̀.”

31 Nígbà náà ni Jósẹ́fù wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ àti fún àwọn ará ilé baba rẹ̀ pé, “Èmi yóò gòkè lọ, èmi yóò sì bá Fáráò sọ̀rọ̀, èmi yóò sì wí fún-un pé, Àwọn arákùnrin mi àti ìdílé baba mi tí ń gbé ní Kénánì ti tọ̀ mí wá.

32 Darandaran ni àwọn ènìyàn náà, wọ́n ń tọ́jú ẹran-ọ̀sìn, wọ́n sì kó agbo ẹran wọn àti agbo màlúù wọn àti gbogbo ohun tí wọ́n ní pẹ̀lú wá.”

33 Nígbà tí Fáráò bá pè yín wọlé tí ó sí béèrè irú iṣẹ́ tí ẹ ń ṣe,

34 ẹ fún-un lésì pé, “àwọn ìránṣẹ́ rẹ ń tọ́jú ẹran-ọ̀sìn ni láti ìgbà ewe wa wá gẹ́gẹ́ bí a ṣe ba a lọ́wọ́ àwọn baba wa.” Nígbà náà ni wọn yóò fún un yín láàyè láti tẹ̀dó sí ilẹ̀ Gósénì. Nítorí pé àwọn ará Éjíbítì kóríra ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ darandaran.