Jẹ́nẹ́sísì 33 BMY

Jákọ́bù àti Ísọ̀ Pàdé:

1 Jákọ́bù sì gbójú sókè, ó sì rí Ísọ̀ àti irinwó ọkùnrin tí wọ́n ń bọ̀, ó sì pín àwọn ọmọ fún Líà, Rákélì àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin méjèèjì.

2 Ó sì ti àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ọmọ wọn ṣíwájú, Líà àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọ̀wọ́ kejì tí ó tẹ̀lé wọn, Rákélì àti Jóṣẹ́fù sì wà lẹ́yìn pátapáta.

3 Jákọ́bù fúnra rẹ̀ wa lọ ṣíwájú pátapáta, ó sì tẹríba ní ìgbà méje bí ó ti ń sún mọ́ Ísọ̀, arákùnrin rẹ̀.

4 Ṣùgbọ́n Ísọ̀ sáré pàdé Jákọ́bù, ó sì dì mọ́ ọn, ó rọ̀ mọ́ ọn lọ́rùn, ó sì fẹnu kò ó lẹ́nu. Àwọn méjèèjì sì sunkún.

5 Nígbà tí Ísọ̀ sì ṣe àkíyèsí àwọn ìyàwó àti ọmọ Jákọ́bù, ó bèèrè lọ́wọ́ Jákọ́bù pé, “Ti tani àwọn wọ̀nyí?”Jákọ́bù sì fèsì wí pé, “Èyí ni àwọn ọmọ tí Ọlọ́run nínú àánú rẹ̀ ti fi fún ìránṣẹ́ rẹ.”

6 Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ọmọ wọn súnmọ́ tòsí, wọ́n sì tẹríba.

7 Lẹ́yìn náà ni Líà àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú dé, wọ́n sì tún tẹríba. Ní ìkẹyìn ni Jósẹ́fù àti Rákélì dé, wọ́n sì tún tẹríba pẹ̀lú.

8 Ísọ̀ sì béèrè pé, “Kín ni èrò rẹ tí o fi to àwọn ọ̀wọ̀ọ̀wọ̀ tí mo pàdé wọ̀nyí?”Jákọ́bù dáhùn pé, “Kí n ba le rí ojúrere rẹ ni olúwa mi.”

9 Ṣùgbọ́n Ísọ̀ wí pé, “Tèmi ti tó mi, pa èyí tí o ní mọ́ fún ara rẹ.”

10 Jákọ́bù bẹ̀ ẹ́ wí pé, “Rárá bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ó bá ṣe pé, mo rí ojú rere rẹ, jọ̀wọ́ gba wọ́n lọ́wọ́ mi. Bí mo ṣe rí ojú rẹ̀ yìí, ó dàbí wí pé mo rí ojú Ọlọ́run ni báyìí, tí inú un rẹ̀ ti dùn sí mi.

11 Jọ̀wọ́ gba àwọn ohun tí mo mú wá wọ̀nyí lọ́wọ́ mi. Nítorí Ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ hàn sí mi, gbogbo ohun tí mo fẹ́ sì ni mo ní.” Nígbà tí Jákọ́bù sì rọ̀ ọ́ pé Ísọ̀ gbọdọ̀ gbà wọ́n, Ísọ̀ sì gbà á.

12 Nígbà náà ni Ísọ̀ wí pé, “Jẹ́ kí a máa lọ, n ó sìn ọ.”

13 Ṣùgbọ́n Jákọ́bù wí fún un pé, “Ṣe ìwọ náà ṣe àkíyèsí pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ wọ̀nyí kéré, àwọn màlúù àti àgùntàn pẹ̀lú sì ní àwọn ọmọ kéékèèké. Bí a bá dà wọ́n rìn jìnnà ju bí agbára wọn se mọ lọ, wọ́n lè kú.

14 Èmi bẹ̀ ọ́, máa lọ ṣíwájú ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ó sì máa rọra bọ̀, títí èmi àti àwọn ọmọ yóò fi dé ọdọ̀ olúwa mi ní Ṣéírì.”

15 Ísọ̀ wí pé, “Jẹ́ kí n fi díẹ̀ sílẹ̀ fún ọ nínú àwọn ọkùnrin mi nígbà náà.”Jákọ́bù wí pé, “Èéṣe, àní kí n sáà rí ojú rere olúwa mi?”

16 Ní ọjọ́ náà gan-an ni Ísọ̀ padà lọ sí Ṣéírì.

17 Jákọ́bù sì lọ sí Ṣúkótù, ó sì kọ́ ilé fún ara rẹ̀, ó sì ṣe ọgbà fún àwọn ẹran. Ìdí èyí ní a fi ń pe ibẹ̀ ní Ṣúkótù.

18 Lẹ́yìn ìgbà tí Jákọ́bù tí Padani-Árámù dé: Àlàáfíà ni Jákọ́bù dé ìlú Sẹ́kẹ́mù ní ilẹ̀ Kénánì, ó sì pàgọ́ sí ìtòòsí ìlú náà.

19 Ó sì ra ilẹ̀ kan tí ó pàgọ́ sí ni ọgọ́rùn-ún owó fàdákà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hámórì tíí ṣe bàbá Sẹ́kẹ́mù.

20 Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan tí ó pè ní El Elohe Ísírẹ́lì (Ọlọ́run Ísírẹ́lì).