Jẹ́nẹ́sísì 21 BMY

Ìbí Ísáákì

1 Olúwa sì fi oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ hàn sí Ṣárà, sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ti sèlérí fún-un.

2 Ṣárà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Ábúráhámù ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ní àkókò náà gan-an tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fún un.

3 Ábúráhámù sì sọ orúkọ ọmọ náà tí Sárà bí fun un ní Ísáákì.

4 Nígbà tí Ísáákì pé ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ, Ábúráhámù sì kọ ọ́ ní ilà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún-un.

5 Ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún ni Ábúráhámù nígbà tí ó bí Ísáákì.

6 Ṣárà sì wí pé, “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín. Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ pé mo bímọ yóò rẹ́rìn-ín pẹ̀lú mi.”

7 Ó sì fi kún un pé, “Ta ni ó le sọ fún Ábúráhámù pé, Ṣárà yóò di ọlọ́mọ? Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, mo sì tún bí ọmọ fún Ábúráhámù ní ìgbà ogbó rẹ.”

A lé Hágárì àti Ísímàẹ́lì jáde.

8 Nígbà tí ọmọ náà dàgbà ó sì gbà á lẹ́nu ọmú, ní ọjọ́ tí a gba Ísáákì lẹ́nu ọmú, Ábúráhámù ṣe àsè ńlá.

9 Ṣùgbọ́n Ṣárà rí ọmọ Ágárì ará Éjíbítì tí ó bí fún Ábúráhámù tí ó fi ṣe ẹlẹ́yà,

10 ó sì wí fún Ábúráhámù pé, “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrú yìí kò ní bá ọmọ mi Ísáákì pín ogún.”

11 Ọ̀rọ̀ náà sì ba Ábúráhámù lọ́kàn jẹ́ gidigidi nítorí ọmọ rẹ̀ náà sáà ni Isìmàẹ́lì i ṣe.

12 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fun un pé, “Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí ọmọ náà àti ẹrúbìnrin rẹ. Gbọ́ ohun tí Ṣárà wí fún ọ, nítorí nípasẹ̀ Ísáákì ni a ó ti ka irú ọmọ rẹ̀.

13 Èmi yóò sọ ọmọ ẹrúbìnrin náà di orílẹ̀ èdè pẹ̀lú, nítorí ọmọ rẹ ni.”

14 Ábúráhámù sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mú oúnjẹ àti ìgò omi kan, ó sì kó wọn fún Ágárì, ó kó wọn lé e léjìká, ó sì lé e jáde pẹ̀lú ọmọ náà. Ó sì lọ lọ́nà rẹ, ó sì ń ṣe alárìnkiri ní ijù Báá-Ṣébà.

15 Nígbà tí omi inú ìgò náà tan, ó gbé ọmọ náà sí abẹ́ igbó.

16 Ó sì lọ, ó sì jókòó nítòòsí ibẹ̀, níwọ̀n bí ìtafà (bí i ogójì míta), nítorí, ó rò ó nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi kò fẹ́ wo bí ọmọ náà yóò ṣe kú.” Bí ó sì ti jókòó sí tòòsí ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún.

17 Ọlọ́run gbọ́ ohun ẹkún náà, Ańgẹ́lì Ọlọ́run sì pe Ágárì láti ọ̀run, ó sì wí fun un pé, “Ágárì, kín ni ó ṣe ọ́? Má bẹ̀rù nítorí Olúwa ti gbọ́ ẹkún ọmọ náà níbi tí o tẹ́ ẹ sí.

18 Dìde, gbé ọmọ náà sókè, kí o sì dì í mú (tùú nínú) nítorí èmi yóò ṣọ ọmọ náà di orilẹ̀ èdè ńlá.”

19 Ọlọ́run sì ṣí ojú Ágárì, ó sì rí kànga kan, ó lọ ṣíbẹ̀, ó rọ omi kún inú ìgò náà, ó sì fún ọmọ náà mu.

20 Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú ọmọ náà bí ó ti ń dàgbà, ó ń gbé nínú ìjù, ó sì di tafàtafà.

21 Nígbà tí ó ń gbé ni ihà ní Páránì, ìyá rẹ̀ fẹ́ ìyàwó fún un láti ilẹ̀ Éjíbítì wá.

Májẹ̀mu ní Báá-Ṣébà

22 Ní àkókò yìí ni ọba Ábímélékì àti Píkólì, olórí ogun rẹ̀ wí fún Ábúráhámù pé, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣe.

23 Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, fi Ọlọ́run búra fún mi, ìwọ kì yóò tàn mí àti àwọn ọmọ mi àti àwọn ìran mi, ìwọ yóò fi inú rere hàn fún mi àti orílẹ̀ èdè tí ìwọ ti ṣe àtìpó, bí mo ti fi hàn fún ọ pẹ̀lú.”

24 Ábúráhámù sì wí pé, “Èmí búra.”

25 Nígbà náà ni Ábúráhámù fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn fún Ábímélékì nípa kànga tí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ gbà lọ́wọ́ rẹ̀.

26 Ṣùgbọ́n Ábímélékì dáhùn pé, “Èmi kò mọ ẹni tí ó ṣe èyí, ìwọ kò sì sọ fún mi tẹ́lẹ̀, òní ni mo sẹ̀sẹ̀ ń gbọ́ báyìí.”

27 Ábúráhámù sì mú àgùntàn àti màlúù wá, ó sì kó wọn fún Ábímélékì. Àwọn méjèèjì sì dá májẹ̀mú.

28 Ábúráhámù sì ya abo ọ̀dọ́-àgùtàn méje nínú agbo àgùntàn rẹ̀ sọ́tọ̀.

29 Ábímélékì sì béèrè lọ́wọ́ Ábúráhámù pé, “Kín ni ìtumọ̀ yíyà tí ìwọ ya àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn méje wọ̀nyí sọ́tọ̀ sí.”

30 Ó da lóhùn pé “Gba àwọn abo ọ̀dọ́-àgùtàn méje wọ̀nyí lọ́wọ́ mi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé èmi ni mo gbẹ́ kànga yìí.”

31 Nítorí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ náà ni Baa-Ṣébà nítorí níbẹ̀ ni àwọn méjèèjì gbé búra.

32 Lẹ́yìn májẹ̀mú tí wọ́n dá ní Báá-Ṣébà yìí ni Ábímélékì àti Píkólì olórí ogun rẹ̀ pada sí ilẹ̀ àwọn ará Fílístínì.

33 Ábúráhámù sì gbin igi Támárísíkì kan sí Báá-Ṣébà, níbẹ̀ ni ó sì pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run ayérayé.

34 Ábúráhámù sì gbé ilẹ̀ àwọn ará Fílístínì fún ọjọ́ pípẹ́.