Jẹ́nẹ́sísì 27 BMY

Ísáákì Súre fún Jákọ́bù

1 Nígbà ti Ísáákì di arúgbó, ojú rẹ̀ sì ti di bàìbàì tóbẹ́ẹ̀ tí kò le ríran. Ó pe Ísọ̀ àkọ́bí rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Ọmọ mi”,Ísọ̀ sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

2 Ísáákì sì wí pé, “Nísinsin yìí mo di arúgbó, èmi kò sì mọ ọjọ́ tí èmi yóò kú.

3 Nítorí náà, mú ohun èlò ọdẹ rẹ—apó àti ọrún—nísinsin yìí kí o sì lọ pa ẹran wá fún mi nínú igbó.

4 Kí o sì ṣe ẹran àdídùn fún mi, irú èyí tí mo fẹ́ràn kí o gbe wá fún mi kí n jẹ, kí n sì súre fún ọ kí n tó kú.”

5 Ṣùgbọ́n Rèbékà ń rfetí léko gbọ́ nígbà tí Ísáákì ń bá Ísọ̀ ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nítorí náà, nígbà ti Ísọ̀ ti ṣe ọdẹ lọ sínú igbó,

6 Rèbékà sọ fún Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ pé, “Wò ó, mo gbọ́ tí baba rẹ ń bá ẹ̀gbọ́n rẹ sọ̀rọ̀ pé,

7 ‘Pa ẹran fún mi wá, kí o sì se oúnjẹ àdídùn fún mi láti jẹ, kí n baà le súre fún ọ níwájú Olúwa kí èmi tó kú.’

8 Nísinsin yìí ọmọ mi, gbọ́ tèmi kí o sì ṣe ohun tí èmi yóò wí fún ọ:

9 Lọ sínú agbo ẹran, kí o sì mú ọmọ ewúrẹ́ méjì, kí ó lè ṣe oúnjẹ́ àdídùn fún baba rẹ, irú èyí tí ó fẹ́ràn dáradára.

10 Ìwọ yóò sì gbé e tọ baba rẹ lọ, kí òun baà lè jẹ ẹ́, kí ó sì súre fún ọ kí ó tó kú.”

11 Jákọ́bù sì wí fún Rèbékà ìyá rẹ̀ pé, “Ṣùgbọ́n Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n mi jẹ́ ènìyàn onírun lára bẹ́ẹ̀ alára ọ̀bọ̀rọ́ ni mi,

12 Bí baba mi bá fọwọ́ kàn mi ńkọ́? Èmi yóò jọ ẹlẹ́tàn lójú rẹ̀, dípò kí ó súre fún mi, èmi yóò sì mú ègún wá sórí ara mi.”

13 Mọ̀mọ́ rẹ̀ wá wí fun un pé, “Ọmọ mi jẹ́ kí ègún náà wá sórí mi, ṣáà ṣe ohun tí mo wí kí o sì mú àwọ̀ ẹran náà wá fún mi.”

14 Jákọ́bù sì ṣe ohun gbogbo tí ìyá rẹ̀ wí fun un, Rèbékà sì se oúnjẹ àdídùn náà, irú èyí tí Ísáákì fẹ́ràn.

15 Nígbà náà ni Rèbékà mú èyí tí ó dára jù nínú aṣọ Ísọ̀ ọmọ rẹ̀ àgbà tí ó wà nínú ilé Rèbékà, ó sì fi wọ Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ kékeré.

16 Ó sì fi awọ ewúrẹ́ wọ̀n-ọn-nì bo ọwọ́ àti ibi tí ó yọ silẹ̀ lọ́rùn rẹ̀ tí kò ní irun.

17 Nígbà náà ni ó gbé ẹran dídùn náà àti oúnjẹ tí ó ti sè lé Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́.

18 Jákọ́bù wọlé lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi”,Baba rẹ sì dáhùn pé, “Èmi nìyí, ìwọ ta ni, ọmọ mi?”

19 Jákọ́bù sì fèsì pé, “Èmi ni Ísọ̀ àkọ́bí rẹ, mo ti ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti wí, jọ̀wọ̀ dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran-igbó mi tí mo ti sè, kí o ba à le súre fún mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.”

20 Ísáákì tún béèrè pé, “Ọmọ mi, báwo ni ó ṣe tètè yá ọ bẹ́ẹ̀?”Jákọ́bù sì tún dáhùn pé, “Olúwa Ọlọ́run rẹ ló fún mi pa.”

21 Nígbà náà ni Ísáákì wí fún Jákọ́bù pé, “Súnmọ́ mi, kí n le è fọwọ́ kàn ọ́, kí n lè mọ̀ bóyá Ísọ̀ ọmọ mi ni ní tòótọ́ tàbí òun kọ́”

22 Jákọ́bù sì súnmọ Ísáákì baba rẹ̀. Ísáákì sì fọwọ́ kàn-án, ó sì wí pé, “Ohùn ni ohùn Jákọ́bù; ṣùgbọ́n ọwọ́ ni ọwọ́ Ísọ̀.”

23 Kò sì dá Jákọ́bù mọ̀ nítorí ọwọ́ rẹ̀ nírun bí i ti Ísọ̀ arákùnrin rẹ, nítorí náà, ó súre fún-un

24 ó sì bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ni Éṣáù ọmọ mi ni tòótọ́?”Jákọ́bù sì dáhùn pé, “Èmi ni.”

25 Nígbà náà ni Ísáákì wí pé “Gbé ẹran igbó náà súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi, kí èmi kí ó jẹ ẹ́, kí èmi sì súre fún ọ láti inú ọkàn mi wá.”Jákọ́bù sì gbé e wá ó sì jẹ ẹ́, ó sì tún fún-un ní wáìnì, ó sì mú un pẹ̀lú.

26 Nígbà náà ni Ísáákì baba rẹ̀ wí fun un pé, “Súnmọ mi, ọmọ mi, kí o sì fẹnu kò mí ní ẹnu.”

27 Ó sì súnmọ ọn, ó sì fẹnu kò ó ní ẹnu. Nígbà tí Ísáákì gbọ́ òórùn aṣọ rẹ̀, ó súre fún-un ó wí pé:“Wò ó òórùn ọmọ miDà bí òórùn okotí Olúwa ti bùkún.

28 Kí Olúwa kí ó fún ọ ní ìrì ọ̀runàti nínú ọ̀rá ilẹ̀àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ àti wáìnì túntún.

29 Kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó máa sìn ọ́,kí àwọn ènìyàn sì máa tẹríba fún ọ,máa ṣe olórí àwọn arákùnrin rẹ,kí àwọn ìyekan rẹ sì máa wólẹ̀ fún ọÈgún ni fún gbogbo ẹni tí ń fi ọ́ ré,Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó súre fún ọ.”

30 Bí Ísáákì ti súre tan tí Jákọ́bù ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ni Ísọ̀ ti oko ọdẹ dé.

31 Òun pẹ̀lú ṣe ẹran dídùn, ó sì gbé e tọ baba rẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, “Baba mi, dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran igbó tí mo ti ṣè, kí o sì súre fún mi.”

32 Ìsáákì baba rẹ̀ sì bi í wí pé, “Ìwọ ta ni?” Ó sì dáhùn pé “Èmi Ísọ̀, àkọ́bí rẹ ni.”

33 Nígbà náà ni Ísáákì wárìrì gidigidi, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni náà, tí ó ti pa ẹran igbó tí ó sì ti gbe wá fún mi, tí mo sì ti jẹ ẹ́ kí ó tó dé? Mo sì ti súre fún un sì wò ó dájúdájú a ó sì bùkún un”

34 Nígbà tí Ísọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ baba rẹ̀, ó ké, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún kíkorò, ó sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Baba mi súre fún èmi náà, àní fún èmi náà pẹ̀lú.”

35 Ṣùgbọ́n Ísáákì wí pé, “Àbúrò rẹ ti fi ẹ̀tàn wá, ó sì ti gba ìbùkún rẹ lọ”

36 Ísọ̀ sì wí pé, “Lásán ni a pe orúkọ rẹ̀ ní Jákọ́bù, (Arẹ́nijẹ) bí? Ní ìgbà méjì yìí ni ó ti tàn mí jẹ: ní àkọ́kọ́, ó gba ogún ìbí mi, nísinsinyìí, ó tún gba ìbùkún mi! Áà! Baba mi, ṣe o kò wá fi ìre kankan sílẹ̀ fun mi ni?”

37 Ísáákì sì dá Ísọ̀ lóhùn pé, “Mo ti fi ṣe olórí rẹ àti àwọn ìbátan rẹ ni mo fi ṣe ìránṣẹ́ fún-un, àti oúnjẹ àti wáìnì ni mo ti fi lé e lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀, kí ni ó tún kù tí ǹ bá tún fún ọ báyìí ọmọ mi?”

38 Ísọ̀ sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Ṣe ìre kan ṣoṣo ni ìwọ ní lẹ́nu ni baba mi?, Ṣúre fún èmi náà, baba mi.” Ísọ̀ sì sunkún kíkankíkan.

39 Ísáákì bàbá rẹ̀ sì dá a lóhùn pé,“Ibùjòkòó rẹyóò jìnnà sí ọ̀rá ilẹ̀,àti sí ìrì ọ̀run láti òkè wá.

40 Nípa idà ni ìwọ yóò máa gbé,ìwọ yóò sì máa sin àbúrò rẹ,ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, nígbà tí ìwọ bá di alágbáraìwọ yóò já àjàgà rẹ̀-kúrò lọ́rùn rẹìwọ yóò sì di òmìnira.”

Jákọ́bù Sá lọ sí ọ̀dọ̀ Lábánì:

41 Ísọ̀ sì kóríra Jákọ́bù nítorí ìre tí baba rẹ̀ sú fún un, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “Baba mi ṣáà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú, nígbà náà ni èmi ó pa Jákọ́bù, arákùnrin mi.”

42 Nígbà tí Rèbékà sì gbọ́ ohun tí Ísọ̀ àkọ́bí rẹ̀ wí, ó sì ránṣẹ́ sí Jákọ́bù, ó sì wí fun un pé, “Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ ń tu ara rẹ̀ nínú pẹ̀lú èrò àti pa ọ́.

43 Nítorí náà ọmọ mi, ṣe ohun tí èmi yóò sọ fún ọ: Ṣá lọ sọ́dọ̀ Lábánì ẹ̀gbọ́n mi ní Háránì.

44 Dúró sí ibẹ̀ títí di ìgbà tí inú Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ yóò fi rọ̀.

45 Nígbà tí ẹ̀gbọ́n rẹ kò bá bínú sí ọ mọ́, tí ó sì ti gbàgbé ohun tí ìwọ ṣe sí i, èmí ó ránṣẹ́ sí ọ láti padà wá, Èéṣe tí èmi ó fi pàdánù ẹ̀yin méjèèjì ní ọjọ́ kan náà?”

46 Nígbà náà ni Rèbékà wí fún Isaaki pé, “Ayé sì sú mi nítorí àwọn ọmọbìnrin Hétì wọ̀nyí. Bí Jákọ́bù bá fẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Hétì wọ̀nyí, ó kúkú sàn kí n má wà láàyè.”