Jẹ́nẹ́sísì 41 BMY

Àwọn àlá Fáráò

1 Nígbà tí odindi ọdún méjì sì ti kọjá, Fáráò lá àlá: ó rí ara rẹ̀ tó dúró ní etí odò Náílì.

2 Nígbà náà ni màlúù méje jáde láti inú odò, wọ́n dára láti wò, wọ́n sì sanra, wọ́n sì ń jẹ koríko.

3 Lẹ́yìn àwọn wọ̀nyí, ni àwọn màlúù méje mìíràn tí kò lẹ́wà tí ó sì rù jáde wá láti inú odò Náílì, wọ́n sì dúró ti àwọn méje tí ó sanra tí ó wà ní bèbè odò náà.

4 Àwọn màlúù tí ó rù, tí kò sì lẹ́wà sì gbé àwọn tí ó lẹ́wà tí ó sanra jẹ. Nígbà náà ni Fáráò jí.

5 Ó sì tún padà sùn, ó sì lá àlá mìíràn: ó rí siírì ọkà méje tí ó kún, ó yó'mọ, ó sì dára, ó sì jáde lára igi ọkà kan ṣoṣo.

6 Lẹ́yìn wọn ni síírí ọkà méje mìíràn yọ, wọn kò yó'mọ, afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù.

7 Àwọn sìírì ọkà méje tí kò yó'mọ (ọmọ rẹ̀ kò tóbi) wọ̀nyí sì gbé àwọn tí ó yó'mọ (ọmọ rẹ̀ tóbi) mì. Nígbà náà ni Fáráò jí lójú oorun, ó sì rí i pé àlá ni.

8 Ní òwúrọ̀, ọkàn rẹ̀ dàrú, nítorí náà, ó ránṣẹ́ pe gbogbo àwọn onídán àti ọ̀mọ̀ran ilẹ̀ Éjíbítì. Fáráò rọ́ àlá rẹ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n kò rí ọ̀kan nínú wọn tí ó le sọ ìtúmọ̀ àlá náà fún un.

9 Nígbà náà ni olórí agbọ́tí wí fún Fáráò pé, “Lónìí ni mo rántí àìṣedéédé mi.

10 Nígbà kan tí Fáráò bínú sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, tí ó sì fi èmi àti olórí alásè sínú ẹ̀wọn ní ilé olórí ẹ̀sọ́.

11 Ọ̀kọ̀ọ̀kan wa lá àlá, àlá kọ̀ọ̀kan sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀.

12 Ọmọkùnrin ará Hébérù kan tí ó jẹ́ ìránṣẹ́ olórí ẹ̀sọ́ wà níbẹ̀ pẹ̀lú wa. A ṣọ́ àwọn àlá wa fún un, ó sì túmọ̀ wọn fún wa, ó sọ ìtúmọ̀ àlá ẹnìkọ̀ọ̀kan fún un.

13 Bí ó sì ti túmọ̀ àlá wọ̀nyí náà ni ohun gbogbo rí. A dá mi padà sí ipò mi, a sì ṣo ọkùnrin keji kọ́ sórí òpó.”

14 Nítorí náà Fáráò ránṣẹ́ pe Jósẹ́fù, wọn sì mu un wá kíákíá láti inú ìhámọ́. Nígbà tí ó fá irun rẹ̀, s tí ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó wá ṣíwájú Fáráò.

15 Fáráò wí fún Jósẹ́fù, “Mo lá àlá kan, kò sì sí ẹni tí o le è túmọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ nípa rẹ pé bí o bá ti gbọ́ àlá, o le è túmọ̀ rẹ̀”

16 Jóṣẹ́fù dáhùn pé, “kì í ṣe agbára mi, ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ni yóò fún Fáráò ní ìtúmọ̀ àlá náà.”

17 Nígbà náà ni Fáráò wí fún Jóṣẹ́fu pé, “Ní inú àlá mi, mo dúró ni etí bèbè odò Náílì,

18 sì kíyèsí i, màlúù méje tí ó sanra tí o sì lẹ́wà jáde wá, wọ́n sì ń jẹ koríko ní tòsí ibẹ̀.

19 Lẹ́yìn wọn, màlúù méje mìíràn jáde wá, wọ́n rù hángógo, wọn kò sì lẹ́wà tóbẹ́ẹ̀ tí n kò tíì rí irú màlúù tí ó ṣe àìlẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ rí ní ilẹ̀ Éjíbítì.

20 Àwọn màlúù tí ó rù tí kò sì lẹ́wà sì jẹ àwọn màlúù tí ó sanra tí ó kọ́ jáde nínú odò.

21 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹ́ wọ́n tan, kò sì ẹni tí ó le mọ̀ pé wọ́n jẹ ohunkóhun, nítorí wọn kò sanra sí i, wọn sì búrẹ́wà ṣíbẹ̀. Nígbà náà ni mo jí lójú oorun mi.”

22 “Ní ojú àlá mi, mo tún rí ṣiiri ọkà méje tí ó yó ọmọ tí ó sì dára, wọ́n jáde láti ara igi ọkà kan.

23 Lẹ́yìn wọn, àwọn méje mìíràn yọ jáde, tí kò yó ọmọ bẹ́ẹ̀ ni afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù tán.

24 Àwọn siiri ọkà méje tí kò yó mọ sì gbé àwọn méje tí ó dára wọ̀nyí mì. Mo ṣọ àlá yìí fún àwọn onídán àn mi, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó le è túmọ̀ rẹ̀ fún mi.”

25 Nígbà náà ni Jósẹ́fù wí fún Fáráò, “Ìtúmọ̀ kan náà ni àwọn àlá méjèèjì ní. Ọlọ́run fi ohun tí ó fẹ́ ṣe hàn fún Fáráò.

26 Àwọn màlúù méje ti ó dára jẹ́ ọdún méje, ṣiiri ọkà méje tí ó dára náà sì jẹ́ ọdún méje: ọ̀kan ṣoṣo ni wọn, àlá kan náà ni.

27 Àwọn màlúù méje tí kò sanra, tí kò sì rẹwà tí ó jáde gbẹ̀yìn jẹ́ ọdún méje, bẹ́ẹ̀ náà ni siiri ọkà méje tí kò dára, tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrun ti rẹ̀ dànù tan: Wọn jẹ́ ọdún méje tí ìyàn yóò fi mú.

28 “Bí mo ti wí fún Fáráò ní ìṣáájú náà ni: Ọlọ́run fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ han Fáráò.

29 Ọdún méje tí oúnjẹ yóò pọ yanturu ń bọ̀ wà ní Éjíbítì.

30 Ṣùgbọ́n ọdún méje mìíràn tí ìyàn yóò mú yóò tẹ̀lé e, nígbà náà ni a ó tilẹ̀ gbàgbé pé ọdún méje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ wà yanturu tilẹ̀ ti wà rí, ìyàn yóò sì run gbogbo ilẹ̀ náà,

31 A kò ní rántí àsìkò ọ̀pọ̀ oúnjẹ yanturu náà mọ́ nítorí pé ìyàn tí yóò tẹ̀lé e yóò pọ̀ púpọ̀.

32 Ìdí tí Ọlọ́run fi fi àlá náà han fún Fáráò ní ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni pé, Ọlọ́run ti pinnu pé yóò sẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ dandan, àti pé kò ni pẹ́ tí Ọlọ́run yóò fi ṣe é.

33 “Ìmọ̀ràn mi ni wí pé, jẹ́ kí Fáráò wá ọlọgbọ́n ènìyàn kan ní ilẹ̀ Éjíbítì, kí ó sì fi ṣe alákòóṣo iṣẹ́ àgbẹ̀ ilẹ̀ Éjíbítì.

34 Kí Fáráò sì yan àwọn alábojútó láti máa gba idá márùn-ún ìkórè oko ilẹ̀ Éjíbítì ní àsìkò ọdún méje ọ̀pọ̀.

35 Kí wọn kó gbogbo oúnjẹ ilẹ̀ náà ni àwọn ọdún méje ọ̀pọ̀ yìí, kí wọn sì kó àwọn ọkà tí wọn jẹ sẹ́kù pamọ́ lábẹ́ aṣẹ Fáráò. Kí a kó wọn pamọ́ ni àwọn ìlú fún jíjẹ.

36 Kí wọn kó oúnjẹ náà pamọ́ fún orílẹ̀ èdè yìí, kí a baà le lò ó ni ọdún méje tí ìyàn yóò fi jà ní ilẹ̀ Éjíbítì, kí ìyàn náà má ba à pa orílẹ̀ èdè yìí run.”

37 Èrò náà sì dára lójú Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀.

38 Fáráò sì bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ a le rí ẹnikẹ́ni bi ọkùnrin yìí, nínú ẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé?”

39 Nígbà náà ni Fáráò wí fún Jósẹ́fù, “Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti fi gbogbo èyí hàn ọ, kò sí ẹni náà tí ó gbọ́n tí ó sì mọ̀ràn bí i tìrẹ ní ilẹ̀ Éjíbítì yìí,

40 ìwọ yóò ṣe àkóso ààfin mi gbogbo àwọn ènìyàn gbọdọ̀ tẹríba fún àṣẹ ẹ̀ rẹ. Ìtẹ́ mi nìkan ni èmi yóò fi jù ọ́ lọ.”

Jóṣẹ́fù di alábojútó ilẹ̀ Éjíbítì

41 Fáráò wí fún Jósẹ́fù pé, “Mo fi ọ́ ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì.”

42 Fáráò sì bọ́ òrùka èdìdì ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ Jósẹ́fù ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ó sì fi ẹ̀gbà tí ó dára sí i lọ́rùn.

43 Ó sì mú un kí ó gun kẹ̀kẹ́ ẹsin bí igbàkejì ara rẹ̀, àwọn ènìyàn sì ń pariwo níwájú rẹ̀ pé, “Ẹ yàgò lọ́nà.” Báyìí ni ó sì fi ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì.

44 Nígbà náà ni Fáráò wí fún Jóṣẹ́fù pé, “Èmi ni Fáráò. Ṣùgbọ́n láì sí àṣẹ rẹ, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe ohunkohun ní ilẹ̀ Éjíbítì.”

45 Fáráò sì sọ Jósẹ́fù ní orúkọ yìí: Ṣefunati-Páníà èyí tí ó túmọ̀ sí, (ẹni tí ó ni agbára ikú àti ìyè ní ìkáwọ́ bí òrìṣà), Ó sì fun un ní Áṣénátì ọmọ Pótífẹ́rà, alábojútó òrìṣà Ónì, gẹ́gẹ́ bí aya. Jósẹ́fù sì rin gbogbo ilẹ̀ náà já.

46 Ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni Jósẹ́fù nígbà tí ó wọ iṣẹ́ Fáráò ọba Éjíbítì. Jósẹ́fù sì jáde kúrò níwájú Fáráò, ó sì ṣe ìbẹ̀wò káàkiri gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì

47 Ní ọdún méje ọ̀pọ̀, ilẹ̀ náà ṣo èso lọ́pọ̀lọpọ̀.

48 Jóṣẹ́fù kó gbogbo oúnjẹ tí a pèṣè ni ilẹ̀ Éjíbítì ní ọdún méje ọ̀pọ̀ yìí, ó sì pa wọ́n mọ́ sí àwọn ìlú. Ní ìlú kọ̀ọ̀kan ni ó kó gbogbo oúnjẹ tí wọ́n gbìn ní àyíká ìlú wọn sí.

49 Jósẹ́fù pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkà mọ́ bí i yanrìn òkun; ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ tí kò ṣe àkọsílẹ̀ mọ́ nítorí, ó tayọ kíkà.

50 Kí ó tó di pé ọdún ìyàn dé, Áṣénátì ọmọ Pótífẹ́rà alábojútó Ónì bí ọmọkùnrin méjì fún Jósẹ́fù.

51 Jósẹ́fù sọ orúkọ àkọ́bí rẹ̀ ni Mánásè, ó sì wí pé, “Nítorí tí Ọlọ́run ti mú mi gbàgbé gbogbo ìdààmú mi àti gbogbo ilé baba mi.”

52 Ó sì sọ orúkọ èkejì ní Éfúráímù, ó sì wí pé, “Nítorí pé Ọlọ́run fún mi ní ọmọ ní ilẹ̀ ìpọ́njú mi”

53 Ọdún méje ọ̀pọ̀ oúnjẹ sì wá sí òpin ní ilẹ̀ Éjíbítì,

54 Ọdún méje ìyàn sì bẹ̀rẹ̀, bí Jósẹ́fù ti wí gan-an. Ìyàn sì mú ní gbogbo ilẹ̀ tó kù, ṣùgbọ́n oúnjẹ wà ní gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì.

55 Nígbà tí àwọn ará Éjíbítì bẹ̀rẹ̀ sí ní rí ipá ìyàn náà, wọ́n kígbe sí Fáráò. Nígbà náà ni Fáráò wí fún wọn pé, “Ẹ lọ bá Jóṣẹ́fù, ẹ ṣe ohun tí ó bá wí fún un yín.”

56 Nígbà tí ìyàn sì ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ náà, Jósẹ́fù sí inú àká, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ọkà fún àwọn ènìyàn, nítorí ìyàn náà mú gan-an ní gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì.

57 Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè sì ń wá láti ra oúnjẹ lọ́wọ́ Jósẹ́fù, nítorí ìyàn náà pọ̀ gidigidi káàkiri gbogbo ayé.