Jẹ́nẹ́sísì 48 BMY

Mánásè àti Éfúráímù

1 Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ si, a wí fún Jósẹ́fù pé, “Baba rẹ ń sàìsàn,” nítorí náà, ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì, Mánásè àti Éfúráímù lọ́wọ́ lọ pẹ̀lú rẹ̀.

2 Nígbà tí a sọ fún Jákọ́bù pé, “Jósẹ́fù ọmọ rẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,” Ísírẹ́lì rọ́jú dìde jókòó lórí ìbùsùn rẹ̀.

3 Jákọ́bù wí fún Jósẹ́fù pé, “Ọlọ́run Olódùmarè fara hàn mí ní Lúsì ní ilẹ̀ Kénánì, níbẹ̀ ni ó sì ti súre fún mi.

4 Ó sì wí fún mi pé, ‘Èmi yóò mú kí bí sí i, ìwọ yóò sì pọ̀ sí i, Èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá, Èmi yóò sì fún ìwọ àti ìran rẹ lẹ́yìn rẹ ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ohun ìní ayérayé.’

5 “Nítorí náà báyìí, àwọn ọmọ rẹ méjèèjì tí a bí fún ọ ní ilẹ̀ Éjíbítì, kí èmi kí ó tó tọ̀ ọ́ wá ní ìhín, ni mo sọ di ọmọ mi fúnra mi. Mánásè àti Éfúráímù yóò jẹ́ tèmi gẹ́gẹ́ bí Rúbẹ́nì àti Símónì ti jẹ́ tèmi.

6 Àwọn ọmọ mìíràn tí ìwọ bá bí lẹ́yìn wọn yóò jẹ́ ọmọ rẹ. Ní ilẹ̀ tí wọn yóò jógún, orúkọ arákùnrin wọn ni a ó máa fi pè wọ́n.

7 Bí mo ti ń padà láti Pádánì, Rákélì kú ní ọ̀nà nígbà tí ó sì wà ní ilẹ̀ Kénánì, èyí tó mú ìbànújẹ́ bá mi, ní bi tí kò jìnnà sí Éfúrátì: Nítorí náà èmí sì sin ín sí ẹ̀bá ọ̀nà tí ó lọ sí Éfúrátì” (Bẹ́tílẹ́hẹ́mù).

8 Nígbà tí Ísírẹ́lì rí àwọn ọmọ Jósẹ́fù, ó béèrè wí pé, “Àwọn wo nìyí?”

9 Jósẹ́fù fún baba rẹ̀ lésì pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi fún mi ní ìhín.”Nígbà náà ni Ísírẹ́lì wí pé, “Kó wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi kí èmi kí ó baà le súre fún wọn.”

10 Báyìí, ojú Ísírẹ́lì ti ń di bàìbàì nítorí ogbó, agbára káká sì ni ó fi ń ríran. Jósẹ́fù sì kó àwọn ọmọ rẹ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, baba rẹ̀ fẹnu kò wọ́n ni ẹnu, ó sì dì mọ́ wọn.

11 Ísírẹ́lì wí fún Jósẹ́fù pé, “Èmi kò lérò rárá pé, mo tún le rí ojú rẹ mọ́ láéláé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tún fún mi ní àǹfààní, mo sì tún rí àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú.”

12 Nígbà náà ni Jósẹ́fù kó àwọn ọmọ náà kúrò ní orí eékún baba rẹ̀, ó wólẹ̀, ó sì tẹ́ríba.

13 Jósẹ́fù sì mú àwọn méjèèjì, Éfúráímù ni o fi sí ọwọ́ ọ̀tún òun tìkararẹ̀, èyí tí í ṣe ọwọ́ òsì fún Ísírẹ́lì, ó sì fi Mánásè sí ọwọ́ òsì ara rẹ̀, èyí tí ó bọ́ sí ọwọ́ ọ̀tún Ísírẹ́lì.

14 Ísírẹ́lì sì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jáde, ó sì gbe lé Éfúráímù lórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni àbúrò, ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ tàṣé ara wọn, ó sì na ọwọ́ òsì lé Mánásè lórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Mánásè ni àkọ́bí.

15 Nígbà náà ni ó súre fún Jósẹ́fù wí pé,“Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run, ẹni tí baba miÁbúráhámù àti Ísáákì rìn níwájú Rẹ̀,Ọlọ́run tí ó ti jẹ́ olùtọ́jú àti aláàbòmi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí di òní,

16 Ańgẹ́lì tí ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ gbogbo ewu,kí ó súre fún àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí.Kí a máa fi orúkọ́ mi pè wọ́n àti orúkọ àwọn baba miÁbúráhámù àti Ísáákì,kí wọn kí ó sì pọ̀ sí i lọ́pọ̀lọpọ̀lórí ilẹ̀ ayé.”

17 Nígbà tí Jósẹ́fù rí i pé baba òun gbé ọwọ́ ọ̀tún lé Éfúráímù lórí, inú rẹ̀ bàjẹ́, ó sì gbá ọwọ́ baba rẹ̀ mú láti gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lórí Éfúráímù lọ sí orí Mánásè.

18 Jósẹ́fù wí fun pé, “Rárá, baba mi, èyí ni àkọ́bí, orí rẹ̀ ni kí ìwọ kí o gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé.”

19 Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà, ó wí pé, “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀. Òun náà yóò di orílẹ̀-èdè, òun náà yóò sì di ńlá. Ṣùgbọ́n àbúrò rẹ̀ yóò di ẹni ńlá jù ú lọ, irú ọmọ rẹ yóò sì di ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.”

20 Ó súre fún wọn lọ́jọ́ náà pé,“Ní orúkọ yín ni Ísírẹ́lì yóò máa súre yìí pé:‘Kí Ọlọ́run ṣe ọ́ bí i ti Éfúráímù àti Mánásè.’ ”

21 Nígbà náà ni Ísírẹ́lì wí fún Jósẹ́fù pé, “Ọjọ́ ikú mi súnmọ́ etílé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò wà pẹ̀lú yín, yóò sì mú un yín padà sí ilẹ̀ àwọn baba yín.

22 Pẹ̀lúpẹ̀lú èmi yóò fún ọ ní ìpín kan ju ti àwọn arákùnrin rẹ lọ. Ilẹ̀ tí mo fi idà àti ọ̀kọ̀ mi gbà lọ́wọ́ àwọn ará Ámórì.”