1 Ní àkókò náà, Júdà lọ kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ láti lọ dúró lọ́dọ̀ ọkùnrin ará Ádúlámù kan tí ń jẹ́ Hírà.
2 Júdà sì pàdé ọmọbìnrin Kénánì kan níbẹ ẹni ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Súà. Ó sì fi ṣe aya, ó sì bá a lò pọ̀;
3 ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, tí ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Érì.
4 Ó sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Ónánì.
5 Ó sì tún bí ọmọkùnrin mìíràn, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ṣélà. Ní Késíbù ni ó wà nígbà tí ó bí i.
6 Júdà sì fẹ́ aya fún Érì, àkọ́bí rẹ̀, orúkọ aya náà ni Támárì.
7 Ṣùgbọ́n Érì àkọ́bí Júdà ṣe ènìyàn búburú níwájú Olúwa, Ọlọ́run sì pa á.
8 Nígbà náà ni Júdà wí fún Ónánì, “Bá aya arákùnrin rẹ lò pọ̀, kí o ṣe ojúṣe rẹ fun un gẹ́gẹ́ bí àbúrò ọkọ, kí ó ba à le bí ọmọ fún un ní orúkọ arákùnrin-ìn rẹ.”
9 Ṣùgbọ́n Ónání mọ̀ pé àwọn ọmọ náà kì yóò jẹ́ ti òun, nítorí náà ni gbogbo ìgbà tí ó bá wọlé tọ aya arákùnrin rẹ̀ lọ, ilẹ̀ ni ó ń da nǹkan ọkùnrin rẹ̀ sí, kí ó má bá a bímọ fún arákùnrin rẹ̀.
10 Ohun tí ó ń ṣe yìí burú lójú Olúwa, ó sì pa òun náà pẹ̀lú.
11 Nígbà náà ni Júdà wí fún Támárì, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, “Lọ máa gbé bí opó ní ilé baba rẹ, títí tí Ṣélà yóò fi dàgbà ó lérò pé òun náà lè kú bí àwọn arákùnrin rẹ̀ tó kù.” Nígbà náà ni Támárì ń lọ gbé ilé baba rẹ̀.
12 Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ìyàwó Júdà, ọmọbìnrin Súà sì kú, nígbà tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ Júdà sì pé, ó gòkè lọ sí Tímínà, sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń bá a rẹ́run àgùntàn rẹ̀, Hírà ará Ádúlámù tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì bá a lọ.
13 Nígbà tí ẹnìkan sọ fún Támárì pé, “Baba ọkọ ọ̀ rẹ̀ wà ní ọ̀nà àjò rẹ̀ sí Tímínà láti rẹ́run àgùntàn rẹ̀.”
14 Ó bọ́ aṣọ opó rẹ̀, ó sì fi ìbòjú bo ojú ara rẹ̀ kí wọn má ba à mọ̀ ọ́. Ó sì jókòó sí ẹnu ibodè Énáímù, èyí tí ó wà ní ọ̀nà Tímínà. Nítorí ó rí i wí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ṣélà ti dàgbà, ṣíbẹ̀, a kò fi òun fún un gẹ́gẹ́ bí aya.
15 Nígbà tí Júdà rí i, ó rò pé aṣẹ́wó ni, nítorí ó ti bo ojú rẹ̀.
16 Láì mọ̀ pé, aya ọmọ òun ní í ṣe, ó yà tọ̀ ọ́, ó wí pé,“Kín ni ìwọ yóò fi fún mi kí ìwọ kó lè bá mi lò pọ̀.”
17 Ó sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọ ewúrẹ́ kan ránṣẹ sí ọ láti inú agbo ẹran.”Obìnrin náà sì dáhùn pé, “Ṣé ìwọ yóò fún mi ní ohun kan gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí títí tí ìwọ yóò fi fi ránṣẹ́?”
18 Júdà sì bi í pé, “Ẹ̀rí wo ni kí n fún ọ?”Ó sì dáhùn pé, “Èdìdì ìdámọ̀ okùn àti ọ̀pá ìtìlẹ̀ rẹ ti ń bẹ ní ọwọ́ rẹ.” Ó sì kó wọn fún un, ó sì sùn tì í, obìnrin náà sì lóyún nípaṣẹ̀ rẹ̀.
19 Lẹ́yìn ìgbà tí ó lọ, ó bọ́ ìbòjú ojú rẹ̀, ó sì tún wọ aṣọ opó rẹ̀ padà.
20 Nígbà náà ni Júdà fi ọmọ ewúrẹ́ náà rán ọ̀rẹ́ rẹ̀ sí obìnrin náà, kí ó ba à lè rí àwọn nǹkan tí ó fi ṣe ìdúró gbà padà. Ṣùgbọ́n wọn kò bá obìnrin náà níbẹ̀.
21 Ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn àdúgbò náà pé, “Níbo ni aṣẹ́wó (aṣẹ́wó ibi ojúbọ òrìṣa) tí ó wà ní etí ọ̀nà Énáímù wà?”Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Kò sí aṣẹ́wó kankan níbí”
22 Ó sì padà lọ sọ́dọ̀ Júdà ó wí fún-un pé, “Èmí kò rí i, à ti pé àwọn aládùúgbò ibẹ̀ sọ pé kò sí aṣẹ́wó kankan níbẹ̀.”
23 Nígbà náà ni Júdà wí pé, “Jẹ́ kí ó máa kó àwọn ohun tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ lọ bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ a ó di ẹlẹ́yà. Mo sáà fi ọmọ ewúrẹ́ ránṣẹ́ sí i, ṣùgbọ́n ìwọ kò rí òun.”
24 Lẹ́yìn nǹkan bí oṣù mẹ́ta, wọn sọ fún Júdà pé, “Támárì aya ọmọ rẹ̀ ṣe àgbèrè, ó sì ti lóyún.”Júdà sì wí pé, “Ẹ mú un jáde, kí ẹ sì dá iná sun ún.”
25 Bí wọ́n sì ti ń mú un jáde, ó ránṣẹ́ sí baba ọkọ rẹ̀ pé, “Ọkùnrin tí ó ni àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó fún mi lóyún. Wò ó, bóyá o lè mọ ẹni tí ó ni èdìdì ìdámọ̀, okùn àti ọ̀pá ìtìlẹ̀ wọ̀nyí.”
26 Júdà sì dá wọn mọ̀, ó sì wí pé, “O ṣe olódodo jù mí lọ, níwọ̀n ìgbà tí n kò fi fún Ṣélà ọmọ mi.” Kò sì bá a lò pọ̀ mọ́ láti ọjọ́ náà.
27 Nígbà tí àsìkò ìbímọ rẹ̀ tó. Ìbejì ọkùnrin ni ó bí.
28 Bí ó sì ti ń bímọ, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ náà na ọwọ́ jáde; agbẹ̀bí sì so okùn òdòdó mọ́ ọmọ náà ní ọrùn ọwọ́. Ó sì wí pé, “Èyí ni o kọ́kọ́ jáde.”
29 Ṣùgbọ́n nìgbá tí ó fa ọwọ́ rẹ̀ padà, èkejì rẹ̀ jáde. Támárì sì wí pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Pérésì.
30 Nígbà náà ni èkejì tí a ti so okùn olódòdó mọ́ lọ́rùn ọwọ́ jáde, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ni Ṣérà.