Jẹ́nẹ́sísì 42 BMY

Àwọn Arákùnrin Jósẹ́fù Lọ Sí Éjíbítì

1 Nígbà tí Jákọ́bù mọ̀ pé ọkà wà ní Éjíbítì, ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pé, “Èéṣe tí ẹ ń wo ara yín lásán?”

2 “Mo tí gbọ́ pé ọkà wà ní ilẹ̀ Éjíbítì. Ẹ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibẹ̀ kí ẹ sì rà wá fún wa, kí a má ba à kú.”

3 Nigbà náà ni mẹ́wàá nínú àwọn arákùnrin Jósẹ́fù sọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì láti ra ọkà.

4 Ṣùgbọ́n Jákọ́bù kò rán Bẹ́ńjámínì àbúrò Jósẹ́fù lọ pẹ̀lú wọn nítorí ẹ̀rù ń bàá kí aburú má ba à ṣẹlẹ̀ síi.

5 Nítorí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà lára àwọn tó lọ Éjíbítì lọ ra oúnjẹ nítorí ìyàn náà mú ni ilẹ̀ Kénánì pẹ̀lú.

6 Nisinsin yìí, Jósẹ́fù ni alábojútó fún gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì, òun sì ni ó ń bojú tó ọkà títà fún gbogbo ènìyàn ìlú náà. Nítorí náà nígbà tí àwọn arákùnrin Jóṣẹ́fù dé, wọ́n tẹríba, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Jósẹ́fù.

7 Gbàrà tí Jósẹ́fù ti rí àwọn arákùnrin rẹ̀ ni ó ti dá wọn mọ̀, ṣùgbọ́n ó ṣe bí i wí pé kò mọ̀ wọ́n, ó sì sọ̀rọ̀ líle sí wọn. Ó béèrè pé, “Níbo ni ẹ ti wá?”Wọ́n sì dáhùn pé, “Láti ilẹ̀ Kénánì ni a ti wá ra oúnjẹ.”

8 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, Jósẹ́fù mọ àwọn arákùnrin rẹ̀, ṣíbẹ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ kò mọ̀ ọ́n.

9 Nígbà náà ni ó rántí àlá rẹ̀ tí ó lá sí wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Ayọ́lẹ̀wò (Amí) ni yín, ẹ wá láti wo àsírí ilẹ̀ wa ni”

10 Wọ́n dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ olúwa wa, àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá láti ra oúnjẹ ni,

11 Ọmọ baba ni wá, olóòótọ́ ènìyàn sì ni wá pẹ̀lú, àwa kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò.”

12 Ó wí fún wọn pé, “Rárá! Ẹ wá láti wo àsírí ilẹ̀ wa ni”

13 Ṣùgbọ́n wọ́n tún dáhùn pé, “Arákùnrin méjìlá ni àwa ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ baba kan náà, tí ó ń gbé ní ilẹ̀ Kénánì. Èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wa ń bẹ lọ́dọ̀ baba wa, ọ̀kan sì ti kú.”

14 Jósẹ́fù wí fún wọn pé, “Bí mo ti wí fún un yín náà ni: Ayọ́lẹ̀wò ni yín!

15 Èyí sì ni a ó fi dán-an yín wò, èmi búra pé, níwọ̀n ìgbà tí Fáráò bá wà láàyè, ẹ kì yóò kùró níbí, àyàfi bí arákùnrin yín kan tókù bá wá síbí.

16 Ẹ rán ọ̀kan nínú yín lọ láti mú arákùnrin yín wá, àwa yóò fi ẹ̀yin tókù pamọ́ sínú àtìmọ́lé, kí àwa ba à lè mọ bóyá òtítọ́ ni ẹ̀yin ń wí. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé irọ́ ni ẹ̀yin ń pa, ní òtítọ́ bí Fáráò ti ń bẹ láàyè ayọ́lẹ̀wò ni yín!”

17 Ó sì fi gbogbo wọn sínú àtìmọ́lé fún ọjọ́ mẹ́ta.

18 Ní ọjọ́ kẹ́ta, Jósẹ́fù wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe kí ẹ̀yin ba à le yè nítorí mo bẹ̀rù Ọlọ́run:

19 Tí ó bá jẹ́ pé olótìítọ́ ènìyàn ni yín, ẹ jẹ́ kí ọkan nínú yín dúró ni àtìmọ́lé ní ìhín, nígbà tí àwọn yókù u yín yóò gbé ọkà lọ fún àwọn ará ilé e yín tí ebi ń pa.

20 Ṣùgbọ́n ẹ gbọdọ̀ mú arákùnrin tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn yín wá, kí n ba à le mọ òtítọ́ ohun ti ẹ ń wí, kí ẹ má baà kú.” Wọn sì gbà láti ṣe èyí.

21 Wọ́n ń sọ ọ́ láàrin ara wọn wí pé, “Dájúdájú a ń jìyà nítorí ohun tí a ṣe sí Jósẹ́fù. A rí ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀ nígbà tí ó ń bẹ̀ wá nítorí ẹ̀mí rẹ̀, ṣùgbọ́n a kò gbẹ́bẹ̀, nítorí náà ni ìdààmú yìí fi dé bá wa.”

22 Rúbẹ́nì fèsì pé, “Ǹjẹ́ ń ò wí fún yín pé kí ẹ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ọmọdé-kùnrin náà? Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́! Nisinsin yìí a ń béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ wa.”

23 Wọn kò sì mọ̀ pé, Jósẹ́fù ń gbọ́ wọn ní àgbọ́yé nítorí ògbufọ̀ ni ó ń lò tẹ́lẹ̀.

24 Ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún. Ó sì tún yí padà sí wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀. Ó mú Símónì kúrò láàrin wọn, ó sì dè é ní ojú wọn.

25 Jósẹ́fù pàṣẹ pé kí wọn bu ọkà kún inú àpò wọn, kí wọn sì mú owó ẹnìkọ̀ọ̀kan padá sínú àpò rẹ̀, kí wọn sì fún wọn ní ohun tí wọn yóò lò nírín-àjò wọn padá sílé. Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe èyí fún wọn,

26 Wọn gbé ẹrù wọn lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọn sì padà lọ sí ilé.

27 Níbi tí wọ́n ti dúró láti sùn lóru ọjọ́ náà, ọ̀kan nínú wọn tú àpò rẹ̀ láti mú oúnjẹ fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì rí owó rẹ̀ ní ẹnu àpò rẹ̀.

28 Ó sì wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “a ti dá owó mi padà, òun nìyí ní ẹnu àpò mi.”Ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì ń gbọ̀n, wọ́n sì wí pé, “Èwo nìyí tí Ọlọ́run ṣe sí wa yìí.”

29 Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Jákọ́bù baba wọn, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí ó sẹlẹ̀ fún-un wí pé,

30 “Ọkùnrin náà tí í ṣe alábojútó ilẹ̀ náà, sọ̀rọ̀ líle sí wa, ó sì fi ẹ̀sùn kàn wá pé a wá yọ́ ilẹ̀ náà wò ni.

31 Ṣùgbọ́n, a wí fun-un pé, ‘Rárá o, olóòtọ́ ènìyàn ni wá, a kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò.

32 Arákùnrin méjìlá ni wá, ọmọ bàbá kan náà, ọ̀kan ti kú, èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wà lọ́dọ̀ baba wa ni ilẹ̀ Kénánì.’

33 “Nígbà náà ni ọkùnrin tí ó jẹ́ alábojútó ilẹ̀ náà wí fún wa pé, ‘Báyìí ni n ó ṣe mọ̀ bóyá olóòótọ́ ènìyàn ni yín; Ẹ fi ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin yín sílẹ̀ níbí, pẹ̀lú mi, ẹ sì mú oúnjẹ lọ fún àwọn ará ilé yín tí ebi ń pa kú lọ, lọ́wọ́ ìyàn.

34 Ṣùgbọ́n ẹ mú arákùnrin yín tí ó kéré jù lọ wá fún mi kí n le mọ̀ pé dájúdájú ẹ kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò bí kò ṣe ènìyàn tòótọ́. Nígbà náà ni n ó mú arákùnrin yín pada fún un yín, lẹ́yìn náà ẹ le máa wá ṣe òwò bí ó ti wù yín ní ilẹ̀ yìí.’ ”

35 Bí wọ́n sì ti ń tú àpò ẹrù wọn, ẹnìkọ̀ọ̀kan bá owó tí ó san fún ọjà náà lẹ́nu àpò rẹ̀! Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi, àwọn àti baba wọn.

36 Jákọ́bù bàbá wọn wí fún wọn pé, “Ẹ ti mú mi pàdánù àwọn ọmọ mi. N kò rí Jósẹ́fù mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n ò kò sì rí Símónì náà mọ. Ẹ sì tún fẹ́ mú Bẹ́ńjámínì lọ! Èmi ni gbogbo ohun búburú yìí wá ń ṣẹlẹ̀ sí.”

37 Nígbà náà ni Rúbẹ́nì wí fún bàbá rẹ̀ pé, “Pa àwọn ọmọ mi méjèèjì bí n kò bá mú Bẹ́ńjámínì padà wá fún ọ, èmi ni kí o fà á lé lọ́wọ́, n ó sì mu-un padà wá.”

38 Ṣùgbọ́n Jákọ́bù wí pé, “Ọmọ mi kì yóò bá a yín lọ, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nikan sì ni ó kù nínú àwọn ọmọ ìyá rẹ̀. Bí ohunkóhun bá sẹlẹ̀ sí i, ìbànújẹ́ ni yóò sì pa mi kú ni ọjọ́ ogbó mi yìí.”