Jẹ́nẹ́sísì 20 BMY

Ábúráhámù àti Ábímélékì

1 Ábúráhámù sì kó kúrò níbẹ̀ lọ sí ìhà gúsù ó sì ń gbé ní agbede-méjì Kádésì àti Ṣúrì; ó sì gbé ní ìlú Gérárì fún ìgbà díẹ̀.

2 Ábúráhámù sì sọ ní ti Ṣárà aya rẹ̀ níbẹ̀ pé, “Arábìnrin mi ni.” Ábímélékì ọba Gérárì sì ránṣẹ́ mú Ṣárà wá sí ààfin rẹ̀.

3 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tọ Ábímélékì wá ní ojú àlá lọ́jọ́ kan, ó sì wí fún un pé, “Kíyèsi, kò sí ohun tí o fi sàn ju òkú lọ, nítorí obìnrin tí ìwọ mú sọ́dọ̀, aya aláya ni.”

4 Ṣùgbọ́n Ábímélékì kò tí ì bá obìnrin náà lò pọ̀, nítorí náà ó wí pé, “Olúwa ìwọ yóò run orílẹ̀ èdè aláìlẹ́bi bí?

5 Ǹjẹ́ òun kò sọ fún mi pé, ‘Arábìnrin mi ni,’ obìnrin náà pẹ̀lú sì sọ pé, ‘arákùnrin mí ni’? Ní òtítọ́ pẹ̀lú ọ̀kàn mímọ́ àti ọwọ́ mímọ́, ni mo ṣe èyí.”

6 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún un nínú àlá náà pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ pé pẹ̀lú òtítọ́ inú ni ìwọ ṣe èyí, èyí ni mo fi pa ọ́ mọ́ tí ń kò jẹ́ kí o dẹ́ṣẹ̀ sí mi. Ìdí nìyí tí n kò fi jẹ́ kí o ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin náà.

7 Níṣinyìí, dá aya ọkùnrin náà padà, nítorí pé wòlíì ni, yóò sì gbàdúrà fún ọ, ìwọ yóò sì yè. Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá dá a padà, mọ̀ dájú pé ìwọ àti gbogbo ẹni tíí ṣe tìrẹ yóò kú.”

8 Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, Ábímélékì pe gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀. Nígbà tí ó sì ṣọ gbogbo ohun tí ó sẹlẹ̀ fún wọn, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi.

9 Nígbà náà ni Ábímélékì pe Ábúráhámù ó sì wí fún un pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa yìí? Ẹ̀sẹ̀ wo ni mo sẹ̀ ọ́ tí ìwọ fi mú ìdálẹ́bi ńlá wá sí orí èmi àti ìjọba mi? Kò yẹ kí ìwọ hu irú ìwà yìí sí mi.”

10 Ábímélékì sì bi Ábúráhámù pé, “Kín ló dé tí ìwọ fi ṣe èyí?”

11 Ábúráhámù sì dáhùn pé, “Mo ṣe èyí nítorí mo rò nínú ara mi pé, ẹ̀yin tí ẹ wà níhìn-ín, ẹ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, pé, ẹ sì le pa mí nítorí aya mi.

12 Yàtọ̀ fún ìyẹn, òtítọ́ ni pé arábìnrin mi ni. Ọmọ baba kan ni wá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a kì í ṣe ọmọ ìyá kan. Mo sì fẹ́ ẹ ní aya.

13 Nígbà tí Ọlọ́run sì mú mi rìn kiri kúrò ní ilé baba mi, mo wí fún un pé, ‘Èyí ni ọ̀nà tí ó lè gbà fi hàn pé ó fẹ́ràn mi: Gbogbo ibi tí a bá dé máa sọ pé, “Arákùnrin rẹ ni mí.” ’ ”

14 Nígbà náà ni Ábímélékì mú àgùntàn àti màlúù wá, àti ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ó sì kó wọn fún Ábúráhámù, ó sì dá Sárà aya rẹ̀ padà fún un.

15 Ábímélékì sì tún wí fún un pé, “Gbogbo ilé mí nìyí níwájú rẹ, máa gbé ní ibikíbi tí o fẹ́ níbẹ̀.”

16 Ábímélékì sì wí fún Ṣárà pé, “Mo fi ẹgbẹ̀rún owó ẹyọ fàdákà fún arákùnrin rẹ. Éyí ni owó ìtanràn ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ níwájú gbogbo ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ àti pé, a dá ọ láre pátapáta.”

17 Nígbà náà, Ábúráhámù gbàdúrà sí Ọlọ́run, Ọlọ́run sì wo Ábímélékì àti aya rẹ̀ àti àwọn ẹrúbìnrin rẹ̀ sàn. Wọ́n sì tún ń bímọ.

18 Nítorí Ọlọ́run ti ṣé gbogbo ará ilé Ábímélékì nínú nítorí Sárà aya Ábúráhámù.