1 Ábúráhámù sì tún fẹ́ aya mìíràn, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kétúrà.
2 Ó sì bí Ṣímúránì, Jókíṣánì, Médánì, Mídíánì, Ísíbákù, àti Ṣúà
3 Jókíṣánì ni baba Ṣébà àti Dédánì, àwọn ìran Dédánì ni àwọn ara Áṣúrímù, Létúsì àti Léúmínù.
4 Àwọn ọmọ Mídíánì ni Éfánì, Éférì, Ánókù, Ábídà àti Élídà. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ìran Kétúrà.
5 Ábúráhámù sì fi ohun gbogbo tí ó ní fún Ísáákì.
6 Ṣùgbọ́n kí o tó kú, ó fún àwọn ọmọ tí àwọn àlè rẹ̀ bí fún un ní ẹ̀bùn, ó sì lé wọn jáde lọ fún Ísáákì ọmọ rẹ sí ilẹ̀ ìlà oòrùn.
7 Gbogbo àpapọ̀ ọdún tí Ábúráhámù lò láyé jẹ́ igba ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (175).
8 Ábúráhámù sì kú ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Ó dàgbà, ó darúgbó kí ó tó kú. A sì sin in sí ibojì àwọn ènìyàn rẹ̀.
9 Àwọn ọmọ rẹ̀, Ísáákì àti Ísímáélì sì sin-in sínú ihò àpáta ni Mákípélà ní ẹ̀gbẹ́ Mámúrè, ní oko Éfúrónì ọmọ Ṣóhárì ara Hítì
10 Inú oko tí Ábúráhámù rà lọ́wọ́ ara Hítì yìí ni a sin Ábúráhámù àti Ṣárà aya rẹ̀ sí.
11 Lẹ́yìn ikú Ábúráhámù, Ọlọ́run sì bùkún fún Ísáákì ọmọ rẹ̀, tí ó ń gbé nítòòsí orísun omi Bia-Lahai-Róì ní ìgbà náà.
12 Wọ̀nyí ni ìran Íṣímáélì, ọmọ Ábúráhámù ẹni tí Hágárì ará Éjíbítì, ọmọ ọ̀dọ̀ Ṣárà bí fún un.
13 Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Íṣímáélì bí a ṣe bí wọn, bẹ̀rẹ̀ láti orí Nébáótì tí í ṣe àkọ́bí, Kédárì, Ábídélì, Míbísámù,
14 Mísímà, Dúmà, Máṣà,
15 Hádádì, Témà, Jétúrì, Náfísì, àti Kédémà.
16 Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọmọ-ọba méjìlá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn.
17 Àpapọ̀ ọdún tí Íṣímáélì lò láyé jẹ́ ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún, a sì sin in pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.
18 Àwọn ìran rẹ̀ sì tẹ̀dó sí agbégbé Áfílà títí tí ó fi dé Súrì, lẹ́bàá ààlà Éjíbítì bí ènìyàn bá ṣe ń lọ sí Áṣíríà. Wọn kò sì gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn.
19 Wọ̀nyí ni ìtàn ìran Ísáákì ọmọ Ábúráhámù.Ábúráhámù bí Ísáákì.
20 Nígbà tí Ísáákì di ọmọ ogójì (40) ọdún ni ó gbé Rèbékà ọmọ Bétúélì ará Árámíà ti Padani-Árámù tí í ṣe arábìnrin Lábánì ará Árámíà ní ìyàwó.
21 Ísáákì sì gbàdúrà sì Olúwa, nítorí aya rẹ̀ tí ó yàgàn, Olúwa sì gbọ́ àdúrà rẹ̀, Rèbékà sì lóyún.
22 Àwọn ọmọ náà ń gbún ara wọn nínú rẹ̀, ó sì wí pé, “Èéṣe tí èyí ń ṣẹlẹ̀ sí mi,” ó sì lọ béèrè lọ́dọ̀ Olúwa.
23 Olúwa sì wí fún un pé,“Orílẹ̀ èdè méjì ni ń bẹ nínú rẹ,àwọn méjì tí ó jáde láti inú rẹ yóò sì pínyà,àwọn ènìyàn kan yóò jẹ́ alágbára ju èkejì lọ,ẹ̀gbọ́n yóò sì máa sin àbúrò.”
24 Nígbà tí ó tó àkókò fun un láti bímọ, ìbejì ni ó wà nínú rẹ̀, ọkùnrin sì ni wọ́n.
25 Èyí tí ó kọ jáde jẹ́ ọmọ pupa, irun sì bo gbogbo ara rẹ̀ bí aṣọ onírun, nítorí náà, wọ́n pè é ní Ísọ̀.
26 Lẹ́yìn rẹ̀ ni èyí èkejì jáde, ó sì di arákùnrin rẹ̀ ni gìgíṣẹ̀ mú, nítorí náà ni wọn ṣe pe orúkọ rẹ ni Jákọ́bù. Ọmọ ọgọ́ta ọdún ni Ísáákì, nígbà tí Rèbékà bí ìbejì yìí fún un.
27 Àwọn ọmọkùnrin náà sì dàgbà. Ísọ̀ sì di ọlọ́gbọ́n ọdẹ, ẹni tí ó fẹ́ràn àti máa dúró ní oko. Jákọ́bù sì jẹ́ ènìyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tí ó ń gbé láàrin ìlú.
28 Ísáákì, ẹni tí ó fẹ́ràn ẹran-ìgbẹ́ fẹ́ràn Ísọ̀ nítorí ẹran ìgbẹ́ tí Éṣáù máa ń pa, ṣùgbọ́n Rèbékà fẹ́ràn Jákọ́bù.
29 Ní ọjọ́ kan, Jákọ́bù ń ṣe oúnjẹ, Éṣáù sì ti igbó ọdẹ dé, ó sì ti rẹ̀ ẹ́.
30 Ó wí fún Jákọ́bù pé, “Ṣe kánkán, fún mi jẹ lára àsáró rẹ pupa yìí, nítorí ebi ń pa mi gidigidi.” (Ìdí èyí ni wọn fi ń pe Éṣáù ni Édómù).
31 Jákọ́bù dáhùn pé, “Kò burú, ṣùgbọ́n kọ́kọ́ ta ogún ìbí rẹ fún mi ná.”
32 Éṣáù sì dáhùn pé, “Wò ó mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú, àǹfààní kín sì ni ogún ìbí jẹ́ fún mi?”
33 Ṣùgbọ́n, Jákọ́bù dáhùn pé, “Kọ́kọ́ búra fún mi pé tèmi ni ogún ìbí náà yóò jẹ́.” Báyìí ni Ísọ̀ búra tí ó sì gbé ogún ìbí rẹ̀ tà fún Jákọ́bù.
34 Nígbà náà ni Jákọ́bù fún Ísọ̀ ní oúnjẹ àti ọbẹ̀. Ó jẹ ẹ́, ó sì jáde lọ.Báyìí ni Ísọ̀ ṣe aláìka ogún ìbí rẹ̀ sí.