Jẹ́nẹ́sísì 47 BMY

1 Jósẹ́fù lọ sọ fún Fáráò pé, “Baba mi àti àwọn arákùnrin mi, pẹ̀lú agbo ẹran, agbo màlúù àti ohun gbogbo tí wọ́n ní, ti dé láti ilẹ̀ Kénánì, wọ́n sì ti wà ní ilẹ̀ Gósénì báyìí.”

2 Ó yan márùn-ún àwọn arákùnrin rẹ́, ó sì fi wọ́n han Fáráò.

3 Fáráò béèrè lọ́wọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Kín ni iṣẹ́ yín?”Wọ́n sì fèsì pé, “Darandaran ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti jẹ́ darandaran”

4 Wọ́n sì tún sọ fun un síwájú sí i pé, “A wá láti gbé ìhín yìí fún ìgbà díẹ̀ nítorí ìyàn náà mú púpọ̀ ní ilẹ̀ Kénánì, àwọn ohun-ọ̀sìn àwa ìránṣẹ́ rẹ kò sì rí ewéko jẹ. Nítorí náà jọ̀wọ́ má sàì jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ tẹ̀dó sí ilẹ̀ Gósénì.”

5 Fáráò wí fún Jósẹ́fù pé, “Baba rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ tọ̀ ọ́ wá,

6 Ilẹ̀ Éjíbítì sì nìyí níwájú rẹ: Mú àwọn arákùnrin rẹ tẹ̀dó sí ibi tí ó dára jù nínú ilẹ̀ náà. Jẹ́ kí wọn máa gbé ní Gósénì. Bí o bá sì mọ ẹnikẹ́ni nínú wọn tí ó ní ẹ̀bùn-ìtọ́jú ẹran, fi wọ́n ṣe olùtọ́jú ẹran-ọ̀sìn mi.”

7 Nígbà náà ni Jósẹ́fù mú Jákọ́bù baba rẹ̀ wọlé wá sí iwájú Fáráò. Lẹ́yìn ìgbà tí Jákọ́bù súre fún Fáráò tán.

8 Fáráò béèrè pé, “Ọmọ ọdún mélòó ni ọ́?”

9 Jákọ́bù sì dá Fáráò lóhùn, “Ọdún ìrìn-àjò ayé mi jẹ́ àádóje (130), ọjọ́ mi kò pọ̀, ó sì kún fún wàhálà, ṣíbẹ̀ kò ì tí ì tó ti àwọn baba mi.”

10 Nígbà náà ni Jákọ́bù tún súre fún Fáráò, ó sì jáde lọ kúrò níwájú rẹ̀.

11 Joṣẹ́fù sì fi baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sí ilẹ̀ Éjíbítì, ó sì fún wọn ní ohun-ìní ní ibi tí ó dára jù ní ilẹ̀ náà, ní agbégbé Ráméṣéṣì bí Fáráò ti pàṣẹ.

12 Jósẹ́fù sì pèṣè oúnjẹ fún baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi iye àwọn ọmọ wọn.

Jóṣẹ́fù àti ìyàn ní ilẹ̀ Éjíbítì

13 Ṣùgbọ́n kò sí oúnjẹ ní gbogbo ilẹ̀ náà nítorí tí ìyàn náà mú púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ Éjíbítì àti ilẹ̀ Kénánì gbẹ nítorí ìyàn náà.

14 Jósẹ́fù gba gbogbo owó tí ó wà ní ilẹ̀ Éjíbítì àti Kénánì ní ìpààrọ̀ fún ti ọkà tí wọn ń rà, ó sì mú owó náà wá sí ààfin Fáráò.

15 Nígbà tí owó wọn tán pátapáta ní Éjíbítì àti Kénánì, gbogbo Éjíbítì wá bá Jósẹ́fù, wọ́n wí pé, “Fún wa ní oúnjẹ, èéṣe tí a ó fi kú ní ojú rẹ? Gbogbo owó wa ni a ti ná tan.”

16 Jósẹ́fù wí pé, “Ẹ mú àwọn ẹran-ọ̀sìn yín wá, èmi yóò fún un yín ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹran-ọ̀sìn yín, níwọ̀n bí owó yín ti tan.”

17 Nítorí náà wọ́n mú àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn tọ Jósẹ́fù wá, ó sì fún wọn ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹsin, àgùntàn, ewúrẹ́, màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Ó sì mú wọn la ọdún náà já, tí ó ń fún wọn ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹran-ọ̀sìn wọn.

18 Nígbà tí ọdún náà parí, wọn padà tọ̀ ọ́ wá ní ọdún tí ó tẹ̀le, wọn wí pé, “A kò le fi pamọ́ fun olúwa wa pé níwọ̀n bí owó wa ti tan tí gbogbo ẹran-ọ̀sìn wa sì ti di tirẹ̀ pé, kò sí ohunkóhun tó kù fún olúwa wa bí kò ṣe ara wa àti ilẹ̀ wa.

19 Èése tí àwa yóò fi parun lójú rẹ, ra àwa tìkárawa àti ilẹ̀ wa ní ìpààrọ̀ fún oúnjẹ, àwa àti ilẹ̀ wa yóò sì wà nínú ìgbékùn Fáráò. Fún wa ni oúnjẹ kí àwa kí ó má ba à kú, kí ilẹ̀ wa má ba à di ahoro.”

20 Nítorí náà Jósẹ́fù ra gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní Éjíbítì fún Fáráò, kò sí ẹnìkan tí ó sẹ́kù ní Éjíbítì tí kò ta ilẹ̀ tirẹ̀ nítorí ìyàn náà mú jù fún wọn. Gbogbo ilẹ̀ náà sì di ti Fáráò,

21 Jósẹ́fù sì sọ gbogbo ará Éjíbítì di ẹrú láti igun kan dé èkejì

22 Ṣùgbọ́n sá, kò ra ilẹ̀ àwọn àlùfáà, nítorí wọ́n ń gba ìpín oúnjẹ lọ́wọ́ Fáráò, wọn sì ní oúnjẹ tí ó tó láti inú ìpín tí Fáráò ń fún wọn. Ìdí nìyí tí wọn kò fi ta ilẹ̀ wọn.

23 Jósẹ́fù wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Níwọ̀n ìgbà tí mo ti ra ẹ̀yin àti ilẹ̀ yín tan lónìí fún Fáráò, irúgbìn rè é, ẹ lọ gbìn ín sí ilẹ̀ náà.

24 Ṣùgbọ́n nígbà tí ire oko náà bá jáde, ẹ ó mú ìdá kan nínú ìdá márùn-ún rẹ̀ fún Fáráò. Ẹ le pa ìdá mẹ́rin tókù mọ́ fún ara yín àti ìdílé yín àti àwọn ọmọ yín.”

25 Wọ́n dá á lóhùn pé, “O ti gbà wá là, Ǹjẹ́ kí a rí ojúrere níwájú olúwa wa, àwa yóò di ẹrú Fáráò.”

26 Nítorí náà Jósẹ́fù sọ ọ́ di òfin nípa ọ̀rọ̀ ilẹ̀ ni Éjíbítì, ó sì wà bẹ́ẹ̀ di òni olónìí-pé, ìdá kan nínú ìdá márùn-ún irè oko jẹ́ ti Fáráò, ilẹ̀ àwọn àlùfáà nìkan ni kò di ti Fáráò.

27 Àwọn ará Ísírẹ́lì sì tẹ̀dó sí Éjíbítì ní agbégbé Gósénì. Wọ́n ní ohun-ìní fún ara wọn, wọ́n sì bí sí i tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n pọ̀ si gidigidi ní iye.

28 Jákọ́bù gbé ní Éjíbítì fún ọdún mẹ́tadínlógún (17) iye ọdún ọjọ́ ayé rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀tàdín ní àádọ́jọ (147).

29 Nígbà tí àkókò ń súnmọ́ etílé fún Ísírẹ́lì láti kú, ó pe Jósẹ́fù, ọmọ rẹ̀, ó sì wí fún-un pé, “Bí mo bá rí ojú rere ni oju rẹ̀ fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ itan mi, kí o sì ṣe ìlérí pé ìwọ yóò fi àánú àti òtítọ́ hàn sí mi. Má ṣe sin òkú mi sí ilẹ̀ Éjíbítì,

30 Ṣùgbọ́n, nígbà tí mo bá sinmi pẹ̀lú àwọn baba mi, gbé mí jáde kúrò ní Éjíbítì kí o sì sin mí sí ibi tí wọ́n sin àwọn baba mi sí.”Jóṣẹ́fù sì dáhùn wí pé, “Èmi ó ṣe bí ìwọ ti wí.”

31 Jákọ́bù wí pé, “Búra fún mi,” Jósẹ́fù sì búra fún un. Ísírẹ́lì sì tẹ orí rẹ̀ ba, bí ó ti sinmi lé ori ìbùsùn rẹ̀.