1 Nígbà tí ó ṣe, Ọlọ́run dán Ábúráhámù wò, ó pè é, ó sì wí pé, “Ábúráhámù.”Ábúráhámù sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”
2 Ọlọ́run sì wí pé, “Mú ọmọ rẹ, àní Ísáakì ọmọ rẹ kan ṣoṣo o nì, tí ìwọ fẹ́ràn, lọ sí ilẹ̀ Móráyà, kí o sì fi rúbọ ṣíṣun níbẹ̀ lórí ọ̀kan nínú àwọn òkè tí èmi yóò sọ fún ọ”
3 Ábúráhámù sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì mú méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti Ísáákì ọmọ rẹ̀, ó sì ṣe igi fún ẹbọ ṣíṣun, ó sì gbéra lọ sí ibi tí Ọlọ́run ti sọ fún-un.
4 Nígbà tí ó di ọjọ kẹ́ta, Ábúráhámù gbé ojú sókè, ó sì rí ibi tí ó ń lọ ní òkèrè,
5 Ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin, ẹ dúró níhìn-ín pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, èmi àti ọmọ yìí yóò lọ sí ọ̀hún-un-nì láti sin Olúwa, a ó sì tún pada wá bá a yín.”
6 Ábúráhámù sì gbé igi ẹbọ ṣíṣun náà ru Ísáákì, òun fúnra rẹ̀ sì mú iná àti ọ̀bẹ. Bí àwọn méjèèjì ti ń lọ,
7 Ísáákì sì sọ fún Ábúráhámù baba rẹ̀ wí pé, “Baba mi.”Ábúráhámù sì da lóhùn pé, “Èmi nìyí ọmọ mi.”Ísáákì sì tún wí pé, “Wò ó iná àti igi nìyí, ṣùgbọ́n níbo ni ọ̀dọ́ àgùntàn fún ẹbọ sísun náà wà?”
8 Ábúráhámù sì dáhùn pé, “Ọmọ mi, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni yóò pèsè ọ̀dọ̀-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì tẹ̀ṣíwájú nínú ìrìn-àjò wọn.
9 Nígbà tí wọn sì dé ibi tí Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù, ó mọ pẹpẹ kan, ó sì to igiọ lé e lórí, ó sì di Ísáákì ọmọ rẹ̀, ó sì da dùbúlẹ̀ lórí pẹpẹ náà.
10 Ábúráhámù sì nawọ́ mú ọ̀bẹ, láti dúńbú ọmọ rẹ̀.
11 Ṣùgbọ́n ańgẹ́lì Olúwa ké sí i láti ọ̀run wí pé “Ábúráhámù! Ábúráhámù!”Ábúráhámù sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”
12 Ańgẹ́lì Olúwa sì wí pé, “Má ṣe fọwọ́ kan ọmọ náà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣe é ni ohun kan. Nísinsin yìí ni mo mọ̀ pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, nítorí pé ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan soso dùn mi.”
13 Ábúráhámù sì gbójú sókè, ó sì rí àgbò kan tí ó fi ìwo há pàǹtírí, ó sì lọ mú un, ó sì fi rú ẹbọ ṣíṣun, dípò ọmọ rẹ̀.
14 Ábúráhámù sì pe orúkọ ibẹ̀ ni, Olúwa yóò pèṣè (Jìhófà Jirè). Bẹ́ẹ̀ ni a sì ń wí títí di òní olónìí pé, “Ní orí òkè Olúwa, ni a ó ti pèsè.”
15 Ańgẹ́lì Olúwa sì tún pe Ábúráhámù láti ọ̀run lẹ́ẹ̀kejì.
16 Ó sì wí pé, Olúwa wí pé, “Mo fi ara mi búra, níwọ̀n bí ìwọ ti ṣe èyí, tí ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dùn mí,
17 dájúdájú, Èmi yóò bùkún ọ, Èmi yóò sì mú kí ìran rẹ yìí kí ó pọ̀ bí i ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí i yanrìn etí òkun. Irú ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnu ibodè àwọn ọ̀ta wọn,
18 àti nípaṣẹ̀ irú ọmọ rẹ ni a ó ti bùkún fún gbogbo orílẹ̀ èdè ayé nítorí tí ìwọ gbọ́ràn sí mi lẹ̀nu”
19 Nígbà náà ni Ábúráhámù padà tọ àwọn ìrànṣẹ́ rẹ̀ lọ. Gbogbo wọn sì padà lọ sí Báá-Ṣébà Ábúráhámù sì dúró ní Báá-Ṣébà.
20 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni a wí fún Ábúráhámù pé, “Mílíkà aya Náhórì bí àwọn ọmọkùnrin fún-un.
21 Úsì, àkọ́bí rẹ̀, Búsì arákùnri rẹ̀, Kémúélì (Baba Árámù).
22 Kéṣédì, Áṣọ̀, Pílídásì, Jídíláfù, àti Bétúélì.”
23 Bétúélì sì ni baba Rèbékà. Mílíkà sì bí àwọn ọmọ mẹ́jọ wọ̀nyí fún Náhórì arákùnrin Ábúráhámù.
24 Àlè rẹ̀ tí ń jẹ́ Réhúmà náà bí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí fun un: Tébà, Gáhámù, Táhásì àti Máákà.