Jẹ́nẹ́sísì 24 BMY

Ísáákì àti Rèbékà

1 Ábúráhámù sì ti darúgbó ní àkókò yìí, Olúwa sì ti bùkún fún-un ni gbogbo ọ̀nà,

2 Ó wí fún olórí àwọn ìránṣẹ́ ilẹ̀ rẹ̀, tí ó jẹ́ alábojútó ohun gbogbo tí ó ní pé, “Fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ itan mi.

3 Èmi yóò mú ọ búra lórúkọ Olúwa Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ kì yóò fẹ́ aya fún ọmọ mi nínú àwọn ọmọbìnrin ará Kénánì, láàrin àwọn ẹni tí èmi ń gbé.

4 Ṣùgbọ́n, ìwọ yóò lọ sí orílẹ̀-èdè mi, láàrin àwọn ará mi láti fẹ́ aya fún Ísáákì, ọmọ mi.”

5 Ìránṣẹ́ náà bi í wí pé, “Ǹjẹ́ bí ọmọbìnrin náà bá kọ̀ láti bá mi wá sí ilẹ̀ yìí ń kọ́? Ǹjẹ́ mo lè mú ọmọ rẹ padà lọ sí orílẹ̀-èdè níbi tí ìwọ ti wá?”

6 Ábúráhámù sì wí fún un pé, “Rí i dájú pé iwọ kò mú ọmọ mi padà lọ sí ibẹ̀.”

7 “Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run tí ó mú mi jáde láti ilẹ̀ baba mi àti ní ilẹ̀ tí a bí mi, tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tí ó sì búra fún mi pé, ‘Irú ọmọ rẹ ni n ó fi ilẹ̀ yìí fún’, yóò rán ańgẹ́lì rẹ̀ ṣáájú rẹ, kí ìwọ kí ó lè rí aya fẹ́ wá fún ọmọ mi láti ibẹ̀.

8 Bí obìnrin náà kò bá fẹ́ tẹ̀lé ọ wá, nígbà náà ni a tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú ìbúra yìí, ṣùgbọ́n pàtàkì ni pé ìwọ kò gbọdọ̀ mú ọmọ mi padà lọ sí ibẹ̀.”

9 Ìránṣẹ́ náà sì fi ọwọ́ rẹ̀ sí abẹ́ itan Ábúráhámù olúwa rẹ̀, ó sì búra fún nítorí ọ̀rọ̀ náà.

10 Ìránṣẹ́ náà sì mú ràkunmí mẹ́wàá, pẹ̀lú onírúurú ohun dáradára láti ọ̀dọ̀ olúwa rẹ̀, ó sì dìde ó sì lọ sí Aramu-Náháráímù, sí ìlú Náhórì,

11 Ó sì mú àwọn ràkunmí náà kúnlẹ̀ nítòòsí kànga lẹ́yìn ìlú, ó ti ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ̀ ní àkókò tí àwọn obìnrin máa ń lọ pọn omi.

12 Ó sì gbàdúrà wí pé, “Olúwa, Ọlọ́run Ábúráhámù olúwa à mi; jẹ́ kí n ṣe àṣeyọrí lónìí, sì fi àánú hàn fún Ábúráhámù olúwa mi.

13 Kíyèsí i, mo dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ yìí, àwọn ọmọbìnrin ìlú yìí sì ń jáde wá pọn omi.

14 Jẹ́ kí ó ṣe pé nígbà tí mo bá wí fún ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin pe, ‘Jọ̀wọ́ sọ ládugbó rẹ kalẹ̀, kí n le mu omi,’ tí ó bá sì wí pé, ‘mu un, èmi ó sì fún àwọn ràkunmí rẹ náà mu pẹ̀lú,’ jẹ́ kí ó ṣe èyí tí o yàn fún ìránṣẹ́ rẹ Ísáákì. Nípa èyí ni n ó fi mọ̀ pé o ti fi àánú hàn fún olúwa mi.”

15 Kí o tó di pé, ó parí àdúrà, Rèbékà dé pẹ̀lú ìkòkò omi rẹ̀ ní èjìká rẹ̀. Ọmọ Bétúélì ni. Bétúélì yìí ni Mílíkà bí fún Náhórì arákùnrin Ábúráhámù.

16 Ọmọbìnrin náà rẹwà, wúndíá ni, kò sì tíì mọ ọkùnrin, ó lọ sí ibi ìsun omi náà, ó sì pọn omi sínú ìkòkò omi, ó sì gbé e, ó ń gòkè bọ̀ kúrò níbi omi.

17 Ìránṣẹ́ náà súré lọ pàdé e rẹ̀ ó sì wí fun un pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ni omi díẹ̀ nínú ìkòkò omi rẹ.”

18 Òun náà dáhùn pé, “Mu, olúwa mi,” ó sì yára sọ ìkòkò omi náà ka ọwọ́ rẹ̀, ó sì fún-un mu.

19 Lẹ́yìn tí ó ti fún un ni omi mu tán, ó wí pé, “Èmi ó bu omi fún àwọn ràkunmí rẹ pẹ̀lú títí wọn yóò fi mu àmutẹ́rùn.”

20 Ó sì yára da omi inú ìkòkò omi rẹ̀ sínú ìbùmu, ó sáré padà lọ síbi omi láti pọn sí i wá fún àwọn ràkunmí, títí tí ó fi pọn fún gbogbo wọn.

21 Láì sọ ọ̀rọ̀ kan, ìránṣẹ́ yìí ń wo ọmọbìnrin náà fínnífínní láti mọ̀ bóyá Ọlọ́run ti ṣe ìrìn-àjò òun ní rere tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.

22 Lẹ́yìn tí àwọn ràkunmí náà ti mu omi tán, ni ọkùnrin náà mú òrùka wúrà ààbọ̀ ìwọn sékélì àti júfù méjì fún ọwọ́ rẹ̀, tí ìwọ̀n sékélì wúrà mẹ́wàá.

23 Lẹ́yìn náà, ó béèrè pé, “Ọmọ ta ni ìwọ í ṣe? Jọ̀wọ́ wí fún mi, ǹjẹ́ ààyè wà ní ilé baba rẹ láti wọ̀ sí ní alẹ́ yìí?”

24 Ó dáhùn pé, “Bétúélì ọmọ tí Mílíkà bí fún Náhórì ni baba mi”

25 Ó sì fi kún un pé, “A ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ koríko àti oúnjẹ fún àwọn ràkunmí yín àti yàrá pẹ̀lú fún-un yín láti wọ̀ sí.”

26 Nígbà náà ni ọkùnrin náà tẹríba, ó sì sin Olúwa.

27 Wí pe, “Ògo ni fún Olúwa, Ọlọ́run Ábúráhámù olúwa mi ti kò jẹ́ kí àánú àti òtítọ́ rẹ̀ kí ó yẹ̀ lọ́dọ̀ olúwa mi. Ní ti èmi Olúwa ti darí ìrìn-àjò mi sí ilé ìbátan olúwa mi.”

28 Ọmọbìnrin náà sì sáré, ó sì lọ sọ ohun gbogbo wọ̀nyí fún àwọn ará ilé ìyá rẹ̀.

29 Rèbékà ní arákùnrin tí ń jẹ́ Lábánì; Lábánì sì sáré lọ bá ọkùnrin náà ní etí odò.

30 Bí ó sì ti rí òrùka imú àti ẹ̀gbà ní ọwọ́ arábìnrin rẹ̀ tí ó sì tún gbọ́ ohun tí Rèbékà sọ pé ọkùnrin náà sọ fún òun, ó jáde lọ bá ọkùnrin náà, ó sì bá a, ó dúró ti ràkunmí wọ̀n-ọn-nì ní ẹ̀bá ìsun-omi.

31 Ó wí fún ọkùnrin náà pé, “Wá, ìwọ ẹni ìbùkún Olúwa, Èéṣe tí o dúró sí ìta níhìn-ín? Mo ti pèsè ààyè sílẹ̀ fún ọ àti ààyè fún àwọn ràkunmí rẹ.”

32 Ọkùnrin náà sì bá Lábánì lọ ilé, ó sì tú ẹrù orí ràkunmí rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fún wọn ni koríko àti oúnjẹ. Ó sì bu omi fún ọkùnrin náà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ láti wẹ ẹsẹ̀ wọn.

33 Wọ́n sì gbé oúnjẹ ṣíwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Èmi kò ní jẹun àyàfi bí mo bá sọ ohun tí mo níí sọ.”Lábánì sì wí pé, “Kò burú, sọ ọ́.”

34 Nítorí náà ó wí pé, “Ìránṣẹ́ Ábúráhámù ni èmi.

35 Olúwa sì ti bùkún olúwa mi gidigidi. Ó sì ti di ọlọ́rọ̀, Ó sì ti fún-un ní àgùntàn, màlúù, àti fàdákà àti wúrà, ìránṣẹ́-kùnrin àti ìránṣẹ́-bìnrin àti ràkúnmí àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

36 Ṣárà aya olúwa mi sì ti bí ọmọkùnrin kan fún un, ní ìgbà ogbó rẹ̀, olúwa mi sì ti fún ọmọ náà ní ohun gbogbo tí ó ní.

37 Olúwa mi sì ti mú mi búra wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ aya fún ọmọ mi, láàrin àwọn ọmọbìnrin Kénánì, ní ilẹ̀ ibi tí èmi ń gbé,

38 Ṣùgbọ́n lọ sí ìdílé baba mi láàrin àwọn ìbátan mi kí o sì fẹ́ aya fún ọmọ mi.’

39 “Mo sì bí olúwa mi léèrè pé, ‘Ǹjẹ́ bí ọmọbìnrin náà kò bá fẹ́ bá mi wá ńkọ́?’

40 “Ó sì dáhùn wí pé, ‘Olúwa, níwájú ẹni tí èmi ń rìn yóò rán Ańgẹ́lì rẹ̀ ṣáájú rẹ yóò sì jẹ́ kí o ṣe aṣeyọrí ní ìrìn-àjò rẹ, kí ìwọ kí ó ba le fẹ́ aya fún ọmọ mi, láàrin àwọn ìbátan mi, àti láàrin àwọn ìdílé baba mi.

41 Nígbà tí ìwọ bá lọ sí ọ̀dọ̀ ìdílé baba mi (gẹ́gẹ́ bí mo tí wí), nígbà náà ni ìwọ tó bọ́ nínú ìbúra yìí.’

42 “Nígbà tí mo dé ibi ìsun omi lónìí, mo wí pé, ‘Olúwa Ọlọ́run Ábúráhámù olúwa mi, bí ìwọ bá fẹ́, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n ṣe àṣeyọ́rí lórí ohun tí mo bá wá yìí,

43 Wò ó, mo dúró ní ẹ̀gbẹ́ ìsun omi yìí, kí ó ṣe pé, nígbà tí wúndíá kan bá jáde wá pọn omi, tí èmi sì wí fún un pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ní ìwọ̀nba omi díẹ̀ mu nínú ládugbó rẹ”,

44 tí ó bá sì wí fún mi pé, “Mu ún, èmi yóò sì tún pọn omi fún àwọn ràkunmí rẹ pẹ̀lú,” Jẹ́ kí ẹni náà jẹ́ ẹni tí Olúwa yàn fún ọmọ Ábúráhámù, olúwa mi.’

45 “Kí n sì tó gbàdúrà tán nínú ọkàn mi, Rèbékà jáde wá pẹ̀lú ìkòkò omi rẹ̀ ní èjìká rẹ̀, ó sì lọ sí ibi ìsun omi ó sì pọn omi. Mo sì wí fun un pé, ‘Jọ̀wọ́ fún mi ni omi mu.’

46 “Kíákíá ni ó sọ ìkòkò rẹ̀ kalẹ̀ láti èjìká rẹ̀, ó sì wí fún mi pé, ‘Mu ún, èmi yóò sì tún fún àwọn ràkúnmí rẹ mu pẹ̀lú.’ Mo sì mu, ó sì tún fún àwọn ràkúnmí mi mu pẹ̀lú.

47 “Mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, ‘ọmọ ta ní ìwọ í ṣe?’“Ó sì wí fún mi pé, ‘ọmọbìnrin Bétúélì tí í ṣe ọmọ Náhórì ni òun, Mílíkà sì ni ìyá òun.’“Nígbà náà ni mo fi òrùka náà bọ imú rẹ̀, mo sì fi ẹ̀gbà-ọwọ́ náà si ní ọwọ́.

48 Mo sì wólẹ̀ mo sì sin Olúwa, Ọlọ́run Ábúráhámù olúwa à mi, ẹni tí ó ṣe amọ̀nà mi láti rí ọmọ ọmọ arákùnrin olúwa mi, mú wá fún ọmọ rẹ̀ (Ísáákì).

49 Ǹjẹ́ nísin yìí bí ẹ̀yin yóò bá fi inú rere àti òtítọ́ bá olúwa mi lò, ẹ sọ fún mi, bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, ẹ sọ fún mi, kí ó le è mọ ọ̀nà tí èmi yóò yà sí.”

50 Lábánì àti Bétúélì sì dáhùn pé, “Lọ́dọ̀ Olúwa ni èyi ti wá, nítorí náà àwa kò le sọ rere tàbí búburú fún ọ.

51 Rèbékà nìyí, mu un kí ó má a lọ, kí ó sì di aya ọmọ olúwa à rẹ, bí Olúwa ti fẹ́.”

52 Nígbà tí ọmọ-ọ̀dọ̀ Ábúráhámù gbọ́ ohun tí wọ́n wí, ó wólẹ̀ níwájú Olúwa.

53 Nígbà náà ni ó kó ohun èlò wúrà àti fàdákà jáde àti aṣọ, ó sì fi wọ́n fún Rèbékà, ó fún arákùnrin Rèbékà àti ìyá rẹ̀ ní ẹ̀bùn olówó iyebíye pẹ̀lú.

54 Lẹ́yìn náà ni òun àti àwọn ọkùnrin tí ó bá a wá tó jẹ, tí wọ́n sì mu, tí wọn sì sùn níbẹ̀ ní òru ọjọ́ náà.Bí wọ́n ti dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó wí pé, “Ẹ rán mi padà lọ sí ọ̀dọ̀ olúwa mi.”

55 Ṣùgbọ́n arákùnrin Rèbékà àti ìyá rẹ̀ fèsì pé, “A fẹ́ kí Rèbékà wà pẹ̀lú wa fún nǹkan bí ọjọ́ mẹ́wàá sí i, lẹ́yìn ìyẹn, ìwọ le máa mu lọ.”

56 Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe dá mi dúró, Olúwa ṣáà ti ṣe ọ̀nà mi ní rere. Ẹ rán mi lọ, kí èmi kí ó le è tọ olúwa à mi lọ.”

57 Nígbà náà ni wọ́n sọ pé, “Jẹ́ kí a pe ọmọ náà gan-an kí a sì bi í”

58 Wọ́n sì pe Rèbékà wọ́n sì bi í, wí pé, “Ṣe ìwọ yóò bá ọkùnrin yìí lọ.”Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, èmi yóò lọ”

59 Wọ́n sì gbà kí Rèbékà àti olùtọ́jú rẹ̀, pẹ̀lú ìránṣẹ́ Ábúráhámù àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ má a lọ.

60 Wọ́n sì súré fún Rèbékà, wọn sì wí fun un pé,“Arábìnrin wa, ìwọ yóò di ìyáẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún.Ǹjẹ́ kí àwọn irú-ọmọ rẹkí ó gba ibodè ọ̀ta a wọn.”

61 Nígbà náà ni Rèbékà àti àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀ múra, wọn sì gun àwọn ràkunmí, wọ́n sì bá ọkùnrin náà padà lọ. Ìránṣẹ́ náà sì mú Rèbékà ó sì bá tirẹ̀ lọ.

62 Ísáákì sì ń ti Bia-Lahai-Róì bọ, nítorí ìhà gúsù ni ó ń gbé.

63 Ísáákì sáà jáde lọ sí oko ni ìrọ̀lẹ́ láti ṣe àsàrò, bí ó sì ti gbé ojú sókè, ó rí àwọn ràkunmí tí ń bọ̀ wá.

64 Rèbékà pẹ̀lú sì gbójú sókè, ó sì rí Ísáákì. Ó sọ̀kalẹ̀ lórí ràkunmí,

65 Ó sì béèrè lọ́wọ́ ìránṣẹ́ náà wí pé, “Ta ni ọkùnrin tí ń bọ̀ wá pàdé wa láti inú oko?”Ìránṣẹ́ náà sì wí fun un pé, “Olúwa mi ni,” nítorí náà ni Rèbékà mú ìbòjú, ó sì bo ojú rẹ̀.

66 Nígbà náà ni ìránṣẹ́ náà ròyìn fún Ísáákì ohun gbogbo tí ó ti ṣe.

67 Nígbà náà ni Ísáákì mú Rèbékà wọ inú àgọ́ ọ ìyá rẹ̀, Ṣárà, ó sì di aya rẹ̀, ó sì fẹ́ràn rẹ̀; ó sì jẹ́ ìtùnú fún Ísáákì lẹ́yìn ikú ìyá rẹ̀.