Jẹ́nẹ́sísì 31 BMY

Jákọ́bù Ṣá kúrò lọ́dọ̀ Lábánì

1 Jákọ́bù sì gbọ́ pé àwọn ọmọ Lábánì ń wí pé, “Jákọ́bù ti gba gbogbo ohun ìní baba wa, ó sì ti kó ọrọ̀ jọ fún ara rẹ̀ lára àwọn ohun tí í ṣe ti baba wa.”

2 Jákọ́bù sì ṣàkíyèsí pé ìwà Lábánì sí òun ti yí padà sí ti àtẹ̀yìnwá.

3 Nígbà náà ni Olúwa wí fún Jákọ́bù pé, “Padà lọ sí ilẹ̀ àwọn baba à rẹ, sí ọ̀dọ̀ àwọn ará rẹ, èmi ó sì wà pẹ̀lú rẹ.”

4 Jákọ́bù sì ránṣẹ́ pe Rákélì àti Líà sí pápá níbi tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ wà.

5 Ó sì wí fún wọn pé, “Mo rí i wí pé ìwà baba yín sí mi ti yí padà sí ti tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n Ọlọ́run baba mi wà pẹ̀lú mi.

6 Ẹ sáà mọ̀ pé, mo ti fi gbogbo agbára mi ṣiṣẹ́ fún baba yín,

7 Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ baba yín ti rẹ́ mi jẹ ní ẹ̀ẹ̀mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó sì ti yí owó iṣẹ́ mi padà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò jẹ́ kí ó le è pa mi lára.

8 Tí ó bá wí pé, ‘Àwọn ẹran onílà ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ rẹ’, nígbà náà ni gbogbo àwọn ẹran ń bí onílà; bí ó bá sì wí pé, ‘Àwọn ẹran oni-tótòtó ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ rẹ’ nígbà náà ni gbogbo ẹran ń bi oní-tótòtó.

9 Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run gba ẹran baba yín, ó sì fi fún mi”

10 “Ní àsìkò tí àwọn ẹran ń gùn, mo la àlá mo sì ri pé àwọn òbúkọ tí wọ́n ń gun àwọn ẹran jẹ́ oní-tótòtó, onílà àti alámì.

11 Ańgẹ́lì Ọlọ́run wí fún mi nínú àlá náà pé, ‘Jákọ́bù’, mo sì wí pé, ‘Èmi nìyí.’

12 Ó sì wí pé, ‘Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wò ó, gbogbo àwọn òbúkọ tí ó ń gun àwọn ẹran jẹ́ oni tótòtó, onílà àti alámì, nítorí mo ti rí gbogbo ohun ti Lábánì ń ṣe sí ọ.

13 Èmi ni Ọlọ́run Bẹ́tẹ́lì, níbi tí ìwọ ti ta òróró sí òpó (ọ̀wọ́n), ìwọ sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti sìn mi. Nísinsin yìí, kúrò ní ilẹ̀ yìí kíákíá kí o sì padà sí ilẹ̀ ibi tí a gbé ti bí ọ.’ ”

14 Nígbà náà ni Rákélì àti Líà dàhún pé, “Ìpín wo ní nínú ogún baba wa?

15 Àjèjì ha kọ́ ni ó kà wá sí? Kì í ṣe pé torí pé ó tà wá nìkan, ṣùgbọ́n ó ti ná gbogbo owó tí ó gbà lórí wa tán.

16 Dájúdájú gbogbo ọrọ̀ ti Ọlọ́run gbà lọ́wọ́ baba wa fún ọ, tiwa àti ti àwọn ọmọ wa ní í ṣe. Nítorí náà ohun gbogbo tí Ọlọ́run bá páṣẹ fun ọ láti ṣe ni kí ìwọ kí ó ṣe.”

17 Nígbà náà ni Jákọ́bù gbé àwọn ọmọ àti aya rẹ̀ gun ràkunmí

18 Ó sì da gbogbo agbo ẹran rẹ̀ ṣáájú pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ tí ó ti kó jọ ni Padani-Árámù, láti lọ sí ọ̀dọ̀ Ísáákì baba rẹ̀ ni ilẹ̀ Kénánì.

19 Nígbà tí Lábánì sì lọ láti rẹ́run àgùntàn, Rákélì sì jí àwọn ère òrìṣà ilé baba rẹ̀.

20 Síwájú sí i, Jákọ́bù tan Lábánì ará Árámù, nítorí kò sọ fún un wí pé òun ń sá lọ.

21 Ó sì sá lọ pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ni, ó sì la odò kọjá (Yúfúrátè), ó sì kọrí sí àwọn ilẹ̀ olókè ti Gílíádì.

Lábánì Lépa Jákọ́bù:

22 Ní ọjọ́ kẹ́ta ni Lábánì gbọ́ pé Jákọ́bù ti sa lọ.

23 Ó sì mú àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì lépa Jákọ́bù, ó sì lépa wọn fún ọjọ́ méje, ó sì bá wọn ní òkè Gílíádì.

24 Ọlọ́run sì yọ sí Lábánì ará Arámáínì lójú àlá ní òru, ó sì wí fun un pé, “Ṣọ́ra, má ṣe sọ ohunkóhun fún Jákọ́bù, ìbá à ṣe rere tàbí búburú.”

25 Jákọ́bù ti pa àgọ́ rẹ̀ si orí òkè kan, nígbà tí Lábánì bá a. Lábánì àti àwọn tí ó wá pẹ̀lú rẹ̀ sì pàgọ́ tiwọn sí ilẹ̀ òkè Gílíádì.

26 Nígbà náà ni Lábánì wí fún Jákọ́bù pé, “Èwo ni ìwọ ṣe yìí? Tí ìwọ sì tàn mi, ó sì kó àwọn ọmọbìnrin mi bi ìgbékùn tí a mú lógun.

27 Èéṣe tí ìwọ yọ́ lọ tí ìwọ sì tàn mi? Kín ló dé tí ìwọ kò sọ fún mi pé ìwọ ń lọ, kí èmi fi ayọ̀ sìn ọ, pẹ̀lú orin àti ohun èlò orin.

28 Ìwọ kò tilẹ̀ jẹ́ kí èmi fi ẹnu ko àwọn ọmọ ọmọ mi lẹ́nu, pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin mi pé ó dìgbà? Ohun tí ìwọ ṣe yìí jẹ́ ìwà òmùgọ.

29 Mo ní agbára láti ṣe ọ ni ibi, ṣùgbọ́n ní òru àná, Ọlọ́run baba rẹ sọ fún mi pé, kí èmi ṣọ́ra, kí èmi má ṣe sọ ohun kan fún ọ, ìbáà ṣe rere tàbí búburú.

30 Nísin yìí, ìwọ ti lọ nítorí ìwọ fẹ́ lati padà lọ sí ilé baba rẹ, ṣùgbọ́n èéṣe tí ìwọ fi jí àwọn òrìṣà mi?”

31 Jákọ́bù dá Lábánì lóhùn pé, “Ẹ̀rù ni ó bà mi nítorí, mo rò pé ìwọ le fi tipá tipá gba àwọn ọmọbìnrin rẹ lọ́wọ́ mi.”

32 “Ṣùgbọ́n bí o bá ri ẹnikẹ́ni pẹ̀lú ère rẹ, kí ẹni náà di òkú.” Ó tún wí pé, “Níwájú gbogbo ìbátan wa báyìí, wò ó fúnra rẹ, bí o bá rí ohunkóhun tí í ṣe tìrẹ, mú un.” Jákọ́bù kò sì mọ̀ pé, Rákélì ni ó jí àwọn òrìṣà náà.

33 Lábánì sì lọ sínú àgọ́ Jákọ́bù àti ti Líà àti ti àwọn ìránṣẹ́-bìnrin méjèèjì, kò sì rí ohunkóhun. Lẹ́yìn ìgbà tí ó jáde nínú àgọ́ Líà ni ó lọ sí àgọ́ Rákélì.

34 Rákélì sì gbé àwọn òrìṣà náà sínú gàárì ràkunmí, ó sì jókòó lé e lórí. Lábánì sì wá gbogbo inú àgọ́, kò sì rí ohunkóhun.

35 Rákélì sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Má ṣe bínú pé èmi ò le dìde dúró níwájú rẹ bàbá à mi, ohun tí ó fà á ni pé, mò ń ṣe nǹkan oṣù lọ́wọ́.” Ó sì wá àgọ́ kiri, kò sì rí àwọn òrìṣà-ìdílé náà.

36 Inú sì bí Jákọ́bù, ó sì pe Lábánì ní ìjà pé, “Kín ni ẹ̀ṣẹ̀ mi? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ tí ìwọ fi ń lépa mi bí ọ̀daràn?

37 Nísinsin yìí tí ìwọ ti tú gbogbo ẹrù mi wò, kín ni ohun tí í ṣe tirẹ̀ tí ìwọ rí? Kó wọn kalẹ̀ báyìí níwájú gbogbo ìbátan rẹ àti tèmi, kí wọn kí ó sì ṣe ìdájọ́ láàrin àwa méjèèjì.

38 “Mo ti wà lọ́dọ̀ rẹ fún ogún ọdún, àwọn àgùntàn tàbí ewúrẹ́ rẹ kò sọnù bẹ́ẹ̀ n kò pa ọ̀kan jẹ rí nínú àwọn àgbò rẹ.

39 Èmi kò mú ọ̀kankan wá fún ọ rí nínú èyí tí ẹranko búburú fà ya, èmi ni ó fara mọ́ irú àdánù bẹ́ẹ̀. Ẹrankẹ́ran tí wọ́n bá sì jí lọ, lọ́sàn án tàbí lóru, ìwọ ń gba owó rẹ̀ lọ́wọ́ mi

40 Báyìí ni mo wà; oòrùn ń pa mi lọ́sàn-án, òtútù ń pa mi lóru, mo sì ń ṣe àìsùn.

41 Báyìí ni ohun gbogbo rí fún ogún ọdún tí mo fi wà nínú ilé rẹ. Ọdún mẹ́rìnlá ni mo fi sìn ọ́ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì, mo sì sìn ọ fún ọdún mẹ́fà fún àwọn ẹran ọ̀sìn, lẹ́ẹ̀mẹ́wàá ni o sì yí owó iṣẹ́ mi padà.

42 Bí ó bá ṣe pé Ọlọ́run àwọn baba mi, Ọlọ́run Ábúráhámù àti ẹ̀rù Ísáákì kò wà pẹ̀lú mi ni, ìwọ ì bá ti lé mi jáde lọ́wọ́ òfo. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ti rí gbogbo ìpọ́njú mi àti iṣẹ́ àṣekára tí mo fi ọwọ mi ṣe, ó sì kìlọ̀ fún ọ lóru àná.”

43 Lábánì sì dá Jákọ́bù lóhùn, “Tèmi ni àwọn obìnrin wọ̀nyí, ọmọ mi ni àwọn ọmọ wọ̀nyí pẹ̀lú, àwọn agbo ẹran yìí, tèmi ni wọ́n pẹ̀lú. Gbogbo ohun tí o rí wọ̀nyí, tèmi ni. Kín ni mo wá le ṣe sí àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí àti àwọn ọmọ wọn tí wọn bí?

44 Wá, jẹ́ kí a dá májẹ̀mú pẹ̀lú ara wa, èyí yóò sì jẹ́ ẹ̀rí ní àárin wa.”

45 Jákọ́bù sì mú òkúta kan ó sì gbé e dúró bí ọ̀wọ̀n.

46 Ó sì wí fún àwọn ìbátan rẹ̀ pé, “Ẹ kó àwọn òkúta díẹ̀ jọ.” Wọ́n sì kó òkúta náà jọ bí òkítì wọ́n sì jẹun níbẹ̀.

47 Lábánì sì pe orúkọ rẹ̀ ní Akojọ òkítì ẹ̀rí, ṣùgbọ́n Jákọ́bù pè é ni Gálíídì.

48 Lábánì sì wí pé, “Òkítì yìí jẹ́ ẹ̀rí láàrin èmi àti ìwọ ní òní.” Ìdí nìyí tí a fi pe orúkọ rẹ̀ ni Gálíídì.

49 Ó tún pè é ni Mísípà nítorí, ó wí pé, “Kí Olúwa kí ó máa sọ́ èmi àti ìwọ nígbà tí a bá yà kúrò lọ́dọ̀ ara wa tán.

50 Bí o bá fìyà jẹ àwọn ọmọbìnrin mi, tàbí tí o fẹ́ aya mìíràn yàtọ̀ sí wọn, rántí pé, Ọlọ́run ń bẹ láàrin wa bí ẹlẹ́rìí bí ẹnikẹ́ni kò tilẹ̀ sí.”

51 Lábánì tún sọ síwájú pé, “Òkítì àti òpó tí mo gbé kalẹ̀ láàrin èmi àti ìwọ yìí,

52 yóò jẹ́ ẹ̀rí wí pé èmi kò ni ré òpó àti òkítì yìí kọjá láti bá ọ jà àti pé ìwọ pẹ̀lú kì yóò kọjá òkítì tàbí òpó yìí láti ṣe mí ní ibi.

53 Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ọlọ́run Náhórì, àti Ọlọ́run baba wọn ṣe ìdájọ́ láàrin wa.”Báyìí ni Jákọ́bù dá májẹ̀mu ní orúkọ Ọlọ́run Ẹ̀rù-Ísáákì baba rẹ̀.

54 Jákọ́bù sì rúbọ níbẹ̀ ni orí òkè, ó sì pe àwọn ẹbí rẹ̀ láti jẹun. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti jẹun, ibẹ̀ náà ni wọ́n sùn ní ọjọ́ náà.

55 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Lábánì fi ẹnu ko àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lẹ́nu àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì súre fún wọn. Lábánì sì padà lọ sí ilé.