1 Ní àsáálẹ́, àwọn ańgẹ́lì méjì sì wá sí ìlú Ṣódómù, Lọ́tì sì jókòó ní ẹnu ibodè ìlú. Bí ó sì ti rí wọn, ó sì dide láti pàdé wọn, ó kí wọn, ó sí foríbalẹ̀ fún wọn.
2 Ó wí pé, “Ẹ̀yin olúwa mi, èmi bẹ̀ yín, ẹ yà sí ilé ìránṣẹ́ yín kí ẹ sì wẹ ẹsẹ̀ yín, kí n sì gbà yín lálejò, ẹ̀yin ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ láti máa bá ìrìnàjò yín lọ.”Wọ́n sì wí pé, “Rárá o, àwa yóò dúró ní ìgboro ní òru òní.”
3 Ṣùgbọ́n Lọ́tì rọ̀ wọ́n gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n gbà láti bá a lọ sì ilé. Ó sì ṣe oúnjẹ fún wọn, ó ṣe Búrẹ́dì aláìwú wọ́n sì jẹ ẹ́.
4 Ṣùgbọ́n kí ó tó di pé wọ́n lọ sùn, àwọn ọkùnrin ìlú Ṣódómù tọmọdé tàgbà yí ilé náà ká.
5 Wọ́n pe Lọ́tì pé, “Àwọn ọkùnrin tí ó wọ̀ sí ilé rẹ lálẹ́ yìí ńkọ́? Mú wọn jáde fún wa, kí a le ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú wọn.”
6 Lọ́tì sì jáde láti pàdé wọn, ó sì ti ilẹ̀kùn lẹ́yìn rẹ̀ bí ó ti jáde.
7 Ó sì wí pé; “Rárá, ẹ̀yin ará mi, ẹ má ṣe se ohun búburú yìí,
8 kíyèsí i, mo ní ọmọbìnrin méjì tí kò mọ ọkùnrin rí, ẹ jẹ́ kí n mú wọn tọ̀ yín wá kí ẹ sì ṣe ohun tí ẹ fẹ́ pẹ̀lú wọn. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ṣe àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ní ibi kan nítorí wọ́n wá wọ̀ lábẹ́ ààbò ní ilé mi.”
9 Wọ́n sì wí fún Lọ́tì pé “Yàgò lọ́nà fún wa, o jẹ́ àlejò láàrin wa, o wá ń fẹ́ ṣe onídájọ́: ohun tí a ó fi ṣe ọ́ ju ohun tí a ó fi ṣe wọn lọ.” Wọn rọ́ lu Lọ́tì, wọ́n sì súnmọ ọn láti fọ́ ilẹ̀kùn.
10 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà nawọ́ fa Lọ́tì wọlé, wọ́n sì ti ilẹ̀kùn.
11 Wọ́n sì bu ìfọ́jú lu àwọn ọkùnrin tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà ilé náà, àti èwe àti àgbà: wọ́n kò sì rí ẹnu ọ̀nà mọ́.
12 Àwọn ọkùnrin náà sì wí fún Lọ́tì pé, “Ǹjẹ́ ó ní ẹlòmíràn ní ìlú yìí bí? Àna rẹ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tàbí ẹnikẹ̀ni tí ìwọ ní ní ìlú yìí, kó wọn jáde kúrò ní ibí yìí,
13 nítorí a ó pa ìlú yìí run, nítorí igbe iṣẹ́ búrurú wọn ń dí púpọ̀ níwájú Olúwa, Olúwa sì rán wa láti pa á run.”
14 Nígbà náà ni Lọ́tì jáde, ó sì wí fún àwọn àna rẹ̀ ọkùnrin tí ó ti bá jẹ́jẹ̀ẹ́ láti fẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣe kánkán, kí ẹ jáde ní ìlú yìí nítorí Olúwa fẹ́ pa ilu yìí run!” Ṣùgbọ́n àwọn ọkọ ọmọ rẹ̀ wọ̀nyí rò pé àwàdà ló ń ṣe.
15 Ní àfẹ̀mọ́jú, àwọn ańgẹ́lì náà rọ Lọ́tì pé, “Ṣe wéré, mú aya rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì tí ó wà níhìnín, àìṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò parun pẹ̀lú ìlú yìí nígbà tí wọ́n bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”
16 Nígbà tí ó ń jáfara, àwọn ọkùnrin náà nawọ́ mú un lọ́wọ́, wọ́n sì nawọ́ mú aya rẹ̀ náà lọ́wọ́ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì, wọ́n sì mú wọn jáde sẹ́yìn odi ìlú, nítorí Olúwa sàánú fún wọn.
17 Ní kété tí wọ́n mú wọn jáde tán, ọ̀kan nínú àwọn Ańgẹ́lì náà wí fún wọn pé, “Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí ti yín, ẹ má ṣe wẹ̀yìn, orí òkè ni kí ẹ sá lọ, ẹ má ṣe dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àìṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin yóò ṣègbé!”
18 Ṣùgbọ́n Lọ́tì wí fún wọn pé, “Rárá, ẹ̀yin Olúwa mi, ẹ jọ̀wọ́!
19 Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ ti rí oju rere rẹ, tí o sì ti fi àánú rẹ hàn nípa gbígba ẹ̀mí mi là, Èmi kò le è ṣá lọ sórí òkè, kí búrurú yìí má ba à lé mi bá, kí n sì kú.
20 Wò ó, ìlú kékeré kan nìyí ní tòòsí láti ṣá sí: jẹ́ kí n ṣá lọ ṣíbẹ̀, ìlú kékeré ha kọ́?, Ẹ̀mí mi yóò sì yè.”
21 Ó sì wí fún un pé, “Ó dára, mo gba ẹ̀bẹ̀ rẹ. Èmi kì yóò run ìlú náà tí ìwọ sọ̀rọ̀ rẹ̀.
22 Tètè! Sá lọ ṣíbẹ̀, nítorí èmi kò le ṣe ohun kan àyàfi tí ó bá dé ibẹ̀,” (ìdí nìyí tí a fi ń pe ìlú náà ní Ṣóárì).
23 Nígbà tí Lọ́tì yóò fi dé ìlú náà oòrùn ti yọ.
24 Nígbà náà ni Olúwa rọ̀jò iná àti Ṣúlúfúrù (òkúta iná) ṣórí Ṣódómù àti Gòmórà-láti ọ̀run lọ́dọ̀ Olúwa wá.
25 Báyìí ni ó run àwọn ìlú náà àti gbogbo ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wà ní ìlú ńláńlá wọ̀n-ọn-nì àti ohun gbogbo tí ó hù jáde nílẹ̀.
26 Ṣùgbọ́n aya Lọ́tì bojú wo ẹ̀yìn, ó sì di òpó (ọ̀wọ́n) iyọ̀.
27 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Ábúráhámù sì dìde ó sì padà lọ sí ibi tí ó gbé dúró níwájú Olúwa.
28 Ó sì wo ìhà Sódómù àti Gòmórà àti àwọn ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì, ó sì rí èéfín tí ń ti ibẹ̀ jáde bí èéfín iná ìléru.
29 Ọlọ́run sì rántí Ábúráhámù, nígbà tí ó run ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì tan, ó sì mú Lọ́tì jáde kúrò láàrin ìparun náà, tí ó kọ lu ìlú tí Lọ́tì ti gbé.
30 Lọ́tì àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin méjèèjì sì kúrò ní Sóárì, wọ́n sì ń lọ gbé ní orí òkè ní inú ihò-àpáta, nítorí ó bẹ̀rù láti gbé ní ìlú Sóárì.
31 Ní ọjọ́ kan, èyí ẹ̀gbọ́n sọ fún àbúrò rẹ̀ pé, “Baba wa ti dàgbà, kò sì sí ọkùnrin kankan ní agbégbé yìí tí ì bá bá wa lò pọ̀, bí ìṣe gbogbo ayé.
32 Wá, jẹ́ kí a mú bàbá wa mu ọtí yó, kí ó ba à le bá wa lò pọ̀, kí àwa kí ó lè bí ọmọ, kí ìran wa má ba à parẹ́.”
33 Ní òru ọjọ́ náà, wọ́n rọ baba wọn ní ọtí yó. Èyí ẹ̀gbọ́n sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bá a lò pọ̀, baba wọn kò mọ̀ ìgbà tí ó sùn ti òun àti ìgbà tí ó dìdè.
34 Ní ọjọ́ kejì èyí ẹ̀gbọ́n wí fún àbúrò rẹ̀ pé, “Ní àná mo sùn ti bàbá mi. Jẹ́ kí a tún wọlé tọ̀ ọ́, kí a lè ní irú ọmọ láti ọ̀dọ̀ baba wa.”
35 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún fún baba wọn ní ọtí mu yó ni alẹ́ ọjọ́ náà, èyí àbúrò náà sì wọlé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bá a lò pọ̀, kò sì tún mọ ìgbà tí ó wọlé ṣùn ti òun tàbí ìgbà tí ó dìde.
36 Àwọn ọmọbìnrin Lọ́tì méjèèjì sì lóyún fún baba wọn.
37 Èyí ẹ̀gbọ́n sì bí ọmọkùnrin, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Móábù. Òun ni baba ńlá àwọn ará Móábù lónìí.
38 Èyí àbúrò náà sì bí ọmọkùnrin, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Bẹni-Ámì. Òun ni baba ńlá àwọn ará Ámónì lónìí.