2 Ṣárà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Ábúráhámù ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ní àkókò náà gan-an tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fún un.
3 Ábúráhámù sì sọ orúkọ ọmọ náà tí Sárà bí fun un ní Ísáákì.
4 Nígbà tí Ísáákì pé ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ, Ábúráhámù sì kọ ọ́ ní ilà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún-un.
5 Ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún ni Ábúráhámù nígbà tí ó bí Ísáákì.
6 Ṣárà sì wí pé, “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín. Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ pé mo bímọ yóò rẹ́rìn-ín pẹ̀lú mi.”
7 Ó sì fi kún un pé, “Ta ni ó le sọ fún Ábúráhámù pé, Ṣárà yóò di ọlọ́mọ? Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, mo sì tún bí ọmọ fún Ábúráhámù ní ìgbà ogbó rẹ.”
8 Nígbà tí ọmọ náà dàgbà ó sì gbà á lẹ́nu ọmú, ní ọjọ́ tí a gba Ísáákì lẹ́nu ọmú, Ábúráhámù ṣe àsè ńlá.