14 Ó ní ọ̀pọ̀lopọ̀ ẹran ọ̀sìn àti agbo ẹran àti àwọn ìránṣẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn Fílístínì ń ṣe ìlara rẹ̀.
15 Nítorí náà àwọn ará Fílístínì ru erùpẹ̀ di gbogbo kànga tí àwọn ìránṣẹ́ Ábúráhámù baba rẹ̀ ti gbẹ́.
16 Nígbà náà ni Ábímélékì wí fún Ísáákì pé, “Jáde kúrò ní ilẹ̀ wa, nítorí tí ìwọ ti di alágbára púpọ̀ jù wá lọ.”
17 Ísáákì sì sí kúrò níbẹ̀, ó sì pàgọ́ sí àfonífojì Gérárì ó sì ń gbé ibẹ̀.
18 Ísáákì sì ṣe àtúngbẹ́ àwọn kànga tí baba rẹ̀ ti gbẹ́ nígbà ayé rẹ̀, èyí tí àwọn Fílístínì ti dí lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, ó sì fún wọn lórúkọ tí baba rẹ̀ ti sọ wọ́n tẹ́lẹ̀.
19 Àwọn ìránṣẹ́ Ísáákì sì gbẹ́ kànga ní àfonífojì náà, wọ́n kan ìsun omi níbẹ̀.
20 Ṣùgbọ́n àwọn darandaran Gérárì ń bá àwọn darandaran Ísáákì jà sí kànga náà pé àwọn ni àwọn ni ín. Nítorí náà ni ó fi pe orúkọ kànga náà ní Éṣékì, nítorí pé wọ́n bá a jà sí kànga náà.