1 Nígbà ti Ísáákì di arúgbó, ojú rẹ̀ sì ti di bàìbàì tóbẹ́ẹ̀ tí kò le ríran. Ó pe Ísọ̀ àkọ́bí rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Ọmọ mi”,Ísọ̀ sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”
2 Ísáákì sì wí pé, “Nísinsin yìí mo di arúgbó, èmi kò sì mọ ọjọ́ tí èmi yóò kú.
3 Nítorí náà, mú ohun èlò ọdẹ rẹ—apó àti ọrún—nísinsin yìí kí o sì lọ pa ẹran wá fún mi nínú igbó.
4 Kí o sì ṣe ẹran àdídùn fún mi, irú èyí tí mo fẹ́ràn kí o gbe wá fún mi kí n jẹ, kí n sì súre fún ọ kí n tó kú.”
5 Ṣùgbọ́n Rèbékà ń rfetí léko gbọ́ nígbà tí Ísáákì ń bá Ísọ̀ ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nítorí náà, nígbà ti Ísọ̀ ti ṣe ọdẹ lọ sínú igbó,
6 Rèbékà sọ fún Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ pé, “Wò ó, mo gbọ́ tí baba rẹ ń bá ẹ̀gbọ́n rẹ sọ̀rọ̀ pé,
7 ‘Pa ẹran fún mi wá, kí o sì se oúnjẹ àdídùn fún mi láti jẹ, kí n baà le súre fún ọ níwájú Olúwa kí èmi tó kú.’