Jẹ́nẹ́sísì 48:1-7 BMY

1 Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ si, a wí fún Jósẹ́fù pé, “Baba rẹ ń sàìsàn,” nítorí náà, ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì, Mánásè àti Éfúráímù lọ́wọ́ lọ pẹ̀lú rẹ̀.

2 Nígbà tí a sọ fún Jákọ́bù pé, “Jósẹ́fù ọmọ rẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,” Ísírẹ́lì rọ́jú dìde jókòó lórí ìbùsùn rẹ̀.

3 Jákọ́bù wí fún Jósẹ́fù pé, “Ọlọ́run Olódùmarè fara hàn mí ní Lúsì ní ilẹ̀ Kénánì, níbẹ̀ ni ó sì ti súre fún mi.

4 Ó sì wí fún mi pé, ‘Èmi yóò mú kí bí sí i, ìwọ yóò sì pọ̀ sí i, Èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá, Èmi yóò sì fún ìwọ àti ìran rẹ lẹ́yìn rẹ ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ohun ìní ayérayé.’

5 “Nítorí náà báyìí, àwọn ọmọ rẹ méjèèjì tí a bí fún ọ ní ilẹ̀ Éjíbítì, kí èmi kí ó tó tọ̀ ọ́ wá ní ìhín, ni mo sọ di ọmọ mi fúnra mi. Mánásè àti Éfúráímù yóò jẹ́ tèmi gẹ́gẹ́ bí Rúbẹ́nì àti Símónì ti jẹ́ tèmi.

6 Àwọn ọmọ mìíràn tí ìwọ bá bí lẹ́yìn wọn yóò jẹ́ ọmọ rẹ. Ní ilẹ̀ tí wọn yóò jógún, orúkọ arákùnrin wọn ni a ó máa fi pè wọ́n.

7 Bí mo ti ń padà láti Pádánì, Rákélì kú ní ọ̀nà nígbà tí ó sì wà ní ilẹ̀ Kénánì, èyí tó mú ìbànújẹ́ bá mi, ní bi tí kò jìnnà sí Éfúrátì: Nítorí náà èmí sì sin ín sí ẹ̀bá ọ̀nà tí ó lọ sí Éfúrátì” (Bẹ́tílẹ́hẹ́mù).