Jẹ́nẹ́sísì 48:7-13 BMY

7 Bí mo ti ń padà láti Pádánì, Rákélì kú ní ọ̀nà nígbà tí ó sì wà ní ilẹ̀ Kénánì, èyí tó mú ìbànújẹ́ bá mi, ní bi tí kò jìnnà sí Éfúrátì: Nítorí náà èmí sì sin ín sí ẹ̀bá ọ̀nà tí ó lọ sí Éfúrátì” (Bẹ́tílẹ́hẹ́mù).

8 Nígbà tí Ísírẹ́lì rí àwọn ọmọ Jósẹ́fù, ó béèrè wí pé, “Àwọn wo nìyí?”

9 Jósẹ́fù fún baba rẹ̀ lésì pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi fún mi ní ìhín.”Nígbà náà ni Ísírẹ́lì wí pé, “Kó wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi kí èmi kí ó baà le súre fún wọn.”

10 Báyìí, ojú Ísírẹ́lì ti ń di bàìbàì nítorí ogbó, agbára káká sì ni ó fi ń ríran. Jósẹ́fù sì kó àwọn ọmọ rẹ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, baba rẹ̀ fẹnu kò wọ́n ni ẹnu, ó sì dì mọ́ wọn.

11 Ísírẹ́lì wí fún Jósẹ́fù pé, “Èmi kò lérò rárá pé, mo tún le rí ojú rẹ mọ́ láéláé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tún fún mi ní àǹfààní, mo sì tún rí àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú.”

12 Nígbà náà ni Jósẹ́fù kó àwọn ọmọ náà kúrò ní orí eékún baba rẹ̀, ó wólẹ̀, ó sì tẹ́ríba.

13 Jósẹ́fù sì mú àwọn méjèèjì, Éfúráímù ni o fi sí ọwọ́ ọ̀tún òun tìkararẹ̀, èyí tí í ṣe ọwọ́ òsì fún Ísírẹ́lì, ó sì fi Mánásè sí ọwọ́ òsì ara rẹ̀, èyí tí ó bọ́ sí ọwọ́ ọ̀tún Ísírẹ́lì.