Aisaya 5:23-29 BM

23 Àwọn tí wọn ń dá ẹni tí ó jẹ̀bi sílẹ̀nígbà tí wọ́n bá ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tán;tí wọn kì í jẹ́ kí aláìṣẹ̀ rí ẹ̀tọ́ gbà.

24 Nítorí náà, bí iná tíí jó àgékù igi kanlẹ̀,tíí sìí jó ewéko ní àjórun;bẹ́ẹ̀ ní gbòǹgbò wọn yóo ṣe rà,tí ìtànná wọn yóo sì fẹ́ lọ bí eruku.Nítorí wọ́n kọ òfin OLUWA àwọn ọmọ ogun sílẹ̀,wọ́n sì kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́ Israẹli.

25 Nítorí náà ni inú ṣe bí OLUWA sí àwọn eniyan rẹ̀,ó sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì pa wọ́n,àwọn òkè sì mì tìtì.Òkú wọn dàbí pàǹtí láàrin ìgboro,sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò sì dá ọwọ́ ìjà dúró.

26 Ó ta àsíá, ó fi pe orílẹ̀-èdè kan tí ó wà ní òkèèrè;ó sì fọn fèrè sí i láti òpin ayé.Wò ó! Àwọn eniyan orílẹ̀-èdè náà ń bọ̀ kíákíá.

27 Kò rẹ ẹnikẹ́ni ninu wọn,ẹnikẹ́ni ninu wọn kò fẹsẹ̀ kọ.Ẹyọ ẹnìkan wọn kò sì sùn,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tòògbé.Àmùrè ẹnìkankan kò tú,bẹ́ẹ̀ ni okùn bàtà ẹnìkankan kò já.

28 Ọfà wọn mú wọ́n kẹ́ ọrun wọn.Pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin wọn le bí òkúta akọ;ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọn dàbí ìjì líle.

29 Bíbú wọn dàbí ti kinniun,wọn a bú ramúramù bí ọmọ kinniun,wọn a kígbe, wọn a sì ki ohun ọdẹ wọn mọ́lẹ̀,wọn a gbé e lọ, láìsí ẹni tí ó lè gbà á lọ́wọ́ wọn.