Aisaya 53:6-12 BM

6 Gbogbo wa ti ṣáko lọ bí aguntan,olukuluku wa yà sí ọ̀nà tirẹ̀,OLUWA sì ti kó ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo wa lé e lórí.

7 Wọ́n ni í lára, wọ́n pọ́n ọn lójú,sibẹsibẹ kò lanu sọ̀rọ̀,wọ́n fà á lọ bí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń lọ pa,ati bí aguntan tíí yadi níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò lanu sọ̀rọ̀.

8 Wọ́n mú un lọ tipátipá,lẹ́yìn tí wọ́n ti dá a lẹ́jọ́,ta ni ninu ìran rẹ̀ tí ó ṣe akiyesi péwọ́n ti pa á run lórí ilẹ̀ alààyè,ati pé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi, ni wọ́n ṣe nà án?

9 Wọ́n tẹ́ ẹ sí ibojì, pẹlu àwọn eniyan burúkú,wọ́n sì sin ín pẹlu ọlọ́rọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò ṣe ẹnikẹ́ni níbi,kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

10 Sibẹsibẹ, ó wu OLUWA láti pa á lára,ó sì fi í sinu ìbànújẹ́,nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;yóo fojú rí ọmọ rẹ̀,ọjọ́ rẹ̀ yóo sì gùn.Ìfẹ́ OLUWA yóo ṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀.

11 Yóo rí èrè àníyàn ọkàn rẹ̀,yóo sì tẹ́ ẹ lọ́rùn;nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni iranṣẹ mi, olódodo,yóo dá ọpọlọpọ eniyan láre,yóo sì ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

12 Nítorí náà, n óo fún un ní ìpín,láàrin àwọn eniyan ńlá,yóo sì bá àwọn alágbára pín ìkógun,nítorí pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún ikú,wọ́n sì kà á mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.Sibẹsibẹ ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ eniyan,ó sì bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.