1 Ábúrámù sì gòkè láti Éjíbítì lọ sí Nẹ́gẹ́fù ní ìhà gúsù, pẹ̀lú aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní àti Lọ́tì pẹ̀lú.
2 Ábúrámù sì ti di ọlọ́rọ̀ gidigidi, ní ẹran-ọ̀sìn, ó ní fàdákà àti wúrà.
3 Láti Gúúsù, ó ń lọ láti ibìkan sí ibòmíràn títí ó fi dé ilẹ̀ Bẹ́tẹ́lì, ní ibi tí àgọ́ rẹ̀ ti wà ní ìṣáájú ri lágbedeméjì Bẹ́tẹ́lì àti Áì.
4 Ní ibi tí ó ti tẹ́ pẹpẹ sí rí tẹ́lẹ̀; Ábúrámù sì ké pe orúkọ Olúwa.
5 Lọ́tì, tí ó ń bá Ábúrámù kiri pẹ̀lú ní agbo ẹran, ọ̀wọ́ ẹran àti àwọn àgọ́ tirẹ̀.
6 Ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà kò le gbà wọ́n tí wọ́n bá ń gbé pọ̀, nítorí, ohun-ìní wọn pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, débi wí pé wọn kò le è gbé pọ̀.
7 Èdè àìyedè sì bẹ̀rẹ̀ láàrin àwọn darandaran Ábúrámù àti ti Lọ́tì. Àwọn ará a Kénánì àti àwọn ará Pérísítì sì ń gbé ní ilẹ̀ náà nígbà náà.