17 Nígbà tí Ábúrámù ti ṣẹ́gun Kedolaómérì àti àwọn ọba tí ó pẹ̀lú rẹ̀, ọba Ṣódómù lọ pàdé e rẹ̀ ní àfonífojì Ṣáfè (èyí tí ó túmọ̀ sí Àfonífojì ọba).
18 Mélíkísédékì ọba Ṣálẹ́mù (Jérúsálẹ́mù) sì mú oúnjẹ àti ọtí wáìnì jáde wá. Òun ni àlùfáà Ọlọ́run, ọ̀gá ògo.
19 Ó sì súre fún Ábúrámù wí pé,“Ìbùkún ni fún Ábúrámù láti ọ̀dọ̀Ọlọ́run ọ̀gá ògo tí ó dá ọ̀run òun ayé.
20 Ìbùkún sì ni fún Ọlọ́run ọ̀gá ògojùlọ tí ó fi àwọn ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́.”Ábúrámù sì fún un ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo.
21 Ọba Ṣódómù sì wí fún Ábúrámù pé, “Kó àwọn ènìyàn mi fún mi, ṣùgbọ́n mú àwọn ẹrù fún ara rẹ.”
22 Ṣùgbọ́n Ábúrámù dá ọba Ṣódómù lóhùn pé, “Mo ti búra fún Olúwa, Ọlọ́run ọ̀gá ògo, tí ó dá ọ̀run àti ayé, mo sì ti gbọ́wọ́ sókè,
23 pé, èmi kì yóò mú ohunkóhun tí í ṣe tìrẹ se tèmi, ìbáà kéré bí orí abẹ́rẹ́, kí ìwọ kí ó má ba à wí pé, ‘Mo sọ Ábúrámù di ọlọ́rọ̀.’