21 Ọba Ṣódómù sì wí fún Ábúrámù pé, “Kó àwọn ènìyàn mi fún mi, ṣùgbọ́n mú àwọn ẹrù fún ara rẹ.”
22 Ṣùgbọ́n Ábúrámù dá ọba Ṣódómù lóhùn pé, “Mo ti búra fún Olúwa, Ọlọ́run ọ̀gá ògo, tí ó dá ọ̀run àti ayé, mo sì ti gbọ́wọ́ sókè,
23 pé, èmi kì yóò mú ohunkóhun tí í ṣe tìrẹ se tèmi, ìbáà kéré bí orí abẹ́rẹ́, kí ìwọ kí ó má ba à wí pé, ‘Mo sọ Ábúrámù di ọlọ́rọ̀.’
24 Èmi kì yóò gba ohunkóhun yàtọ̀ sí ohun tí àwọn ọkùnrin mi ti jẹ́, ṣùgbọ́n fi ìpín fún àwọn ọkùnrin tí ó bá mi lọ, Ánérì, Ésíkólì àti Mámúrè. Jẹ́ kí wọn kí ó gba ìpín wọn.”