16 Ó sì lọ, ó sì jókòó nítòòsí ibẹ̀, níwọ̀n bí ìtafà (bí i ogójì míta), nítorí, ó rò ó nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi kò fẹ́ wo bí ọmọ náà yóò ṣe kú.” Bí ó sì ti jókòó sí tòòsí ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún.
17 Ọlọ́run gbọ́ ohun ẹkún náà, Ańgẹ́lì Ọlọ́run sì pe Ágárì láti ọ̀run, ó sì wí fun un pé, “Ágárì, kín ni ó ṣe ọ́? Má bẹ̀rù nítorí Olúwa ti gbọ́ ẹkún ọmọ náà níbi tí o tẹ́ ẹ sí.
18 Dìde, gbé ọmọ náà sókè, kí o sì dì í mú (tùú nínú) nítorí èmi yóò ṣọ ọmọ náà di orilẹ̀ èdè ńlá.”
19 Ọlọ́run sì ṣí ojú Ágárì, ó sì rí kànga kan, ó lọ ṣíbẹ̀, ó rọ omi kún inú ìgò náà, ó sì fún ọmọ náà mu.
20 Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú ọmọ náà bí ó ti ń dàgbà, ó ń gbé nínú ìjù, ó sì di tafàtafà.
21 Nígbà tí ó ń gbé ni ihà ní Páránì, ìyá rẹ̀ fẹ́ ìyàwó fún un láti ilẹ̀ Éjíbítì wá.
22 Ní àkókò yìí ni ọba Ábímélékì àti Píkólì, olórí ogun rẹ̀ wí fún Ábúráhámù pé, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣe.