19 Ọlọ́run sì ṣí ojú Ágárì, ó sì rí kànga kan, ó lọ ṣíbẹ̀, ó rọ omi kún inú ìgò náà, ó sì fún ọmọ náà mu.
20 Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú ọmọ náà bí ó ti ń dàgbà, ó ń gbé nínú ìjù, ó sì di tafàtafà.
21 Nígbà tí ó ń gbé ni ihà ní Páránì, ìyá rẹ̀ fẹ́ ìyàwó fún un láti ilẹ̀ Éjíbítì wá.
22 Ní àkókò yìí ni ọba Ábímélékì àti Píkólì, olórí ogun rẹ̀ wí fún Ábúráhámù pé, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣe.
23 Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, fi Ọlọ́run búra fún mi, ìwọ kì yóò tàn mí àti àwọn ọmọ mi àti àwọn ìran mi, ìwọ yóò fi inú rere hàn fún mi àti orílẹ̀ èdè tí ìwọ ti ṣe àtìpó, bí mo ti fi hàn fún ọ pẹ̀lú.”
24 Ábúráhámù sì wí pé, “Èmí búra.”
25 Nígbà náà ni Ábúráhámù fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn fún Ábímélékì nípa kànga tí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ gbà lọ́wọ́ rẹ̀.