5 Ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún ni Ábúráhámù nígbà tí ó bí Ísáákì.
6 Ṣárà sì wí pé, “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín. Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ pé mo bímọ yóò rẹ́rìn-ín pẹ̀lú mi.”
7 Ó sì fi kún un pé, “Ta ni ó le sọ fún Ábúráhámù pé, Ṣárà yóò di ọlọ́mọ? Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, mo sì tún bí ọmọ fún Ábúráhámù ní ìgbà ogbó rẹ.”
8 Nígbà tí ọmọ náà dàgbà ó sì gbà á lẹ́nu ọmú, ní ọjọ́ tí a gba Ísáákì lẹ́nu ọmú, Ábúráhámù ṣe àsè ńlá.
9 Ṣùgbọ́n Ṣárà rí ọmọ Ágárì ará Éjíbítì tí ó bí fún Ábúráhámù tí ó fi ṣe ẹlẹ́yà,
10 ó sì wí fún Ábúráhámù pé, “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrú yìí kò ní bá ọmọ mi Ísáákì pín ogún.”
11 Ọ̀rọ̀ náà sì ba Ábúráhámù lọ́kàn jẹ́ gidigidi nítorí ọmọ rẹ̀ náà sáà ni Isìmàẹ́lì i ṣe.