1 Ìyàn kan sì mú ní ilẹ̀ náà, yàtọ̀ fún èyí tí ó mú ní ìgbà ayé Ábúráhámù, Ísáákì sì lọ sọ́dọ̀ Ábímélékì ọba àwọn Fílístínì ni Gérárì.
2 Olúwa sì fi ara han Ísáákì, ó sì wí pé, “Má ṣe sọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì: Jókòó ní ilẹ̀ tí èmi sọ fún ọ.
3 Dúró ní ilẹ̀ yìí fún ìgbà díẹ̀, èmi ó sì wà pẹ̀lú rẹ, Èmi yóò sì bùkún ọ. Nítorí ìwọ àti irú ọmọ rẹ ni èmi yóò fi gbogbo àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí fún, èmi yóò sì fi ìdí ìbúra tí mo ṣe fún Ábúráhámù baba rẹ mulẹ̀.
4 Èmi yóò sọ ìran rẹ di púpọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, n ó sì fún wọn ní àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí, nípaṣẹ̀ irú ọmọ rẹ ni a ó sì bùkún fún gbogbo orílẹ̀ èdè ayé,
5 nítorí pé Ábúráhámù gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, ó sì pa gbogbo ìkìlọ̀, àṣẹ, ìlànà àti òfin mi mọ́.”
6 Nítorí náà Ísáákì dúró ní Gérárì.