4 Ṣékémù sì wí fún Hámórì bàbá rẹ̀ pé, “Fẹ́ ọmọbìnrin yìí fún mi bí aya.”
5 Nígbà tí Jákọ́bù gbọ́ ohun tí ó sẹlẹ̀ pé a fi ipá bá Dínà ọmọbìnrin òun lò pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀ wà nínú pápá níbi tí wọ́n ti ń daran nítorí náà ó mú sùúrù títí tí wọ́n fi dé.
6 Ámórì baba Ṣékémù sì jáde wá láti bá Jákọ́bù sọ̀rọ̀.
7 Àwọn ọmọ Jákọ́bù sì ti oko dé, wọ́n sì gbọ́ ohun tí ó ṣelẹ̀ inú wọn sì bàjẹ́, ó sì ń bí wọn nínú gidigidi, nítorí pé, ohun àbùkù ńlá ni ó jẹ́ pé Ṣékémù bá ọmọ Jákọ́bù lò pọ̀-irú ohun tí kò yẹ kí ó ṣẹlẹ̀ rárá.
8 Hámórì sì bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkàn ọmọ mi Ṣékémù fà sí ọmọ rẹ. Jọ̀wọ́ fi fún un gẹ́gẹ́ bí aya.
9 Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ìgbéyàwó láàrin ara wa, kí àwọn ọmọ yín kó máa fẹ́ àwọn ọmọ wa.
10 Ẹ lè máa gbé láàrin wa, ibikíbi tí ó bá tẹ́ yín lọ́rùn láàrin wa ni ẹ lè gbé, ẹ máa ṣe òwò yín kí ẹ sì kó ọrọ̀ jọ fún ara yín.”