1 Wọ̀nyí ni ìran Ísọ̀, ẹni tí a ń pè ní Édómù.
2 Nínú àwọn ọmọbìnrin Kénánì ni Ísọ̀ ti fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀: Ádà ọmọbìnrin Élónì ará Hítì àti Óhólíbámà, ọmọbìnrin Ánà, ọmọ ọmọ Ṣíbéónì ará Hífítì.
3 Ó sì tún fẹ́ Báṣémátì ọmọ Ísímáélì arábìnrin Nébájótù.
4 Ádà bí Élífásì fún Ísọ̀, Báṣémátì sì bí Réúẹ́lì,
5 Óhólíbámà pẹ̀lú sì bí Jéúsì, Jálámù, àti Kórà. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Ísọ̀ bí ní Kénánì.
6 Ísọ̀ sì mú àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ àti àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn àti gbogbo ohun ìní mìíràn tí ó ní, ni Kénánì, ó sì kó lọ sí ilẹ̀ mìíràn, jìnà sí ibi tí Jákọ́bù arakùnrin rẹ̀ wà.
7 Ohun ìní wọn pọ̀ ju èyí tí àwọn méjèèjì lè máa gbé ní ojúkan lọ. Ilẹ̀ tí wọ́n wà kò le gba àwon méjèèjì nítorí àwọn ohun ọ̀sìn wọn.