13 Ísírẹ́lì sì wí fún Jósẹ́fù pé, “Ṣé o mọ̀ pé, àwọn arákunrin rẹ ń da ẹran ní Ṣékémù, wá, jẹ́ kí n rán ọ sí wọn.”Jósẹ́fù sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”
14 O sì wí fún un pé, “Lọ wò bí àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn agbo ẹran bá wà ní àlàáfíà, kí o sì wá jíṣẹ́ fún mi.” Ó sì rán Jósẹ́fù lọ láti àfonífojì Ébúrónì.Nígbà tí Jósẹ́fù dé Ṣékémù,
15 Ọkùnrin kan sì rí i tí ó ń rìn kiri inú pápá, ó sì bi í pé, “Kín ni ò ń wá?”
16 Ó sì dáhùn pé, “Àwọn arákùnrin mi ni mò ń wá, ǹjẹ́ o mọ ibi tí wọ́n wà pẹ̀lú agbo ẹran?”
17 Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Wọ́n ti kúrò ní ìhín, mo gbọ́ tí wọ́n ń wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ sí Dótanì.’ ”Jósẹ́fù sì wá àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, ó sì rí wọn ní tòsí Dótanì.
18 Ṣùgbọ́n bí wọ́n sì ti rí i tí ń bọ̀ lókèèrè, kí ó sì tó dé ọ̀dọ̀ wọn, wọn gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.
19 “Alálàá ni ń bọ̀ yìí,” ni wọ́n ń wí fún ara wọn.