1 Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí, ni agbọ́tí ọba àti alásè rẹ̀ ṣẹ ọba Éjíbítì, olúwa wọn.
2 Fáráò sì bínú sí méjì nínú àwọn ìjòyè rẹ̀, olórí agbọ́tí àti olórí alásè,
3 Ó sì fi wọ́n sí ìhámọ́ ní ilé olórí ẹ̀sọ́, ní inú ẹ̀wọ̀n ibi tí Jósẹ́fù pẹ̀lú wà.
4 Olórí ẹ̀sọ́ sì yan Jósẹ́fù láti máa ṣe ìránṣẹ́ wọn.Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wà ní ìhámọ́ fún ìgbà díẹ̀.
5 Ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọkùnrin méjèèjì náà-olórí agbọ́tí àti olórí alásè lá àlá, ní òru kan náà, àlá kọ̀ọ̀kan sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀.
6 Nígbà tí Jósẹ́fù dé ọ̀dọ̀ wọn ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó ṣe àkíyèsí pé, inú wọn kò dùn.
7 Ó sì bi àwọn ìjòyè Fáráò tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìhámọ́, nínú ilé olúwa rẹ̀ léèrè pé, “Èéṣe tí ojú yín fi fàro bẹ́ẹ̀ ní òní, tí inú yín kò sì dùn?”