28 Ó sì wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “a ti dá owó mi padà, òun nìyí ní ẹnu àpò mi.”Ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì ń gbọ̀n, wọ́n sì wí pé, “Èwo nìyí tí Ọlọ́run ṣe sí wa yìí.”
29 Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Jákọ́bù baba wọn, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí ó sẹlẹ̀ fún-un wí pé,
30 “Ọkùnrin náà tí í ṣe alábojútó ilẹ̀ náà, sọ̀rọ̀ líle sí wa, ó sì fi ẹ̀sùn kàn wá pé a wá yọ́ ilẹ̀ náà wò ni.
31 Ṣùgbọ́n, a wí fun-un pé, ‘Rárá o, olóòtọ́ ènìyàn ni wá, a kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò.
32 Arákùnrin méjìlá ni wá, ọmọ bàbá kan náà, ọ̀kan ti kú, èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wà lọ́dọ̀ baba wa ni ilẹ̀ Kénánì.’
33 “Nígbà náà ni ọkùnrin tí ó jẹ́ alábojútó ilẹ̀ náà wí fún wa pé, ‘Báyìí ni n ó ṣe mọ̀ bóyá olóòótọ́ ènìyàn ni yín; Ẹ fi ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin yín sílẹ̀ níbí, pẹ̀lú mi, ẹ sì mú oúnjẹ lọ fún àwọn ará ilé yín tí ebi ń pa kú lọ, lọ́wọ́ ìyàn.
34 Ṣùgbọ́n ẹ mú arákùnrin yín tí ó kéré jù lọ wá fún mi kí n le mọ̀ pé dájúdájú ẹ kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò bí kò ṣe ènìyàn tòótọ́. Nígbà náà ni n ó mú arákùnrin yín pada fún un yín, lẹ́yìn náà ẹ le máa wá ṣe òwò bí ó ti wù yín ní ilẹ̀ yìí.’ ”