1 Báyìí, ìyàn náà sì mú gidigidi ní ilẹ̀ náà.
2 Nígbà tí wọ́n sì ti jẹ gbogbo ọkà tí wọ́n rà ní Éjíbítì tan, baba wọn wí fún wọn pé, “Ẹ padà lọ ra oúnjẹ́ díẹ̀ si wá fún wa.”
3 Ṣùgbọ́n Júdà wí fún un pé, “Ọkùnrin náà tẹnumọ́ ọn nínú ìkìlọ̀ rẹ̀ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò rí ojúrere mi mọ́, àyàfi bí arákùnrin yín bá bá a yín wá’.
4 Tí ìwọ yóò bá rán Bẹ́ńjámínì arákùnrin wa lọ pẹ̀lú wa, a ó lọ ra oúnjẹ wá fún ọ.
5 Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ni jẹ́ kí ó bá wa lọ, àwa kì yóò lọ, nítorí ọkùnrin náà sọ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò rí ojúrere mi mọ́ àyàfi bí arákùnrin yín bá bá a yín wá.’ ”