Jẹ́nẹ́sísì 48:10-16 BMY

10 Báyìí, ojú Ísírẹ́lì ti ń di bàìbàì nítorí ogbó, agbára káká sì ni ó fi ń ríran. Jósẹ́fù sì kó àwọn ọmọ rẹ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, baba rẹ̀ fẹnu kò wọ́n ni ẹnu, ó sì dì mọ́ wọn.

11 Ísírẹ́lì wí fún Jósẹ́fù pé, “Èmi kò lérò rárá pé, mo tún le rí ojú rẹ mọ́ láéláé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tún fún mi ní àǹfààní, mo sì tún rí àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú.”

12 Nígbà náà ni Jósẹ́fù kó àwọn ọmọ náà kúrò ní orí eékún baba rẹ̀, ó wólẹ̀, ó sì tẹ́ríba.

13 Jósẹ́fù sì mú àwọn méjèèjì, Éfúráímù ni o fi sí ọwọ́ ọ̀tún òun tìkararẹ̀, èyí tí í ṣe ọwọ́ òsì fún Ísírẹ́lì, ó sì fi Mánásè sí ọwọ́ òsì ara rẹ̀, èyí tí ó bọ́ sí ọwọ́ ọ̀tún Ísírẹ́lì.

14 Ísírẹ́lì sì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jáde, ó sì gbe lé Éfúráímù lórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni àbúrò, ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ tàṣé ara wọn, ó sì na ọwọ́ òsì lé Mánásè lórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Mánásè ni àkọ́bí.

15 Nígbà náà ni ó súre fún Jósẹ́fù wí pé,“Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run, ẹni tí baba miÁbúráhámù àti Ísáákì rìn níwájú Rẹ̀,Ọlọ́run tí ó ti jẹ́ olùtọ́jú àti aláàbòmi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí di òní,

16 Ańgẹ́lì tí ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ gbogbo ewu,kí ó súre fún àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí.Kí a máa fi orúkọ́ mi pè wọ́n àti orúkọ àwọn baba miÁbúráhámù àti Ísáákì,kí wọn kí ó sì pọ̀ sí i lọ́pọ̀lọpọ̀lórí ilẹ̀ ayé.”