1 Jósẹ́fù sì subú lé baba rẹ̀, ó sunkún, ó sì fẹnu kò ó ní ẹnu.
2 Nígbà náà ni Jósẹ́fù pàṣẹ fún àwọn oníṣègùn tí ó wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pé kí wọn kí ó ṣe òkú Ísírẹ́lì baba rẹ̀ lọ́jọ̀, àwọn oníṣègùn náà sì ṣe bẹ́ẹ̀,
3 Fún ogójì ọjọ́ ni wọ́n fi ṣe èyí, nítorí èyí ni àsìkò tí a máa ń fi ṣe ẹ̀ǹbáàmù òkú. Àwọn ará Éjíbítì sì sọ̀fọ̀ rẹ̀ fún àádọ́rin ọjọ́.
4 Nígbà tí ọjọ́ ìṣọ̀fọ̀ náà kọjá. Jósẹ́fù wí fún àwọn ará ilé Fáráò pé, “Bí mo bá bá ojúrere yín pàdé, ẹ bámi sọ fún Fáráò.