Jẹ́nẹ́sísì 50:11-17 BMY

11 Nígbà tí àwọn ará Kénánì tí ń gbé níbẹ̀ ri i bí wọ́n ti ń sọ̀fọ̀ náà ni ilẹ̀ ìpakà Átadì, wọ́n wí pé, “Ọ̀fọ̀ ńlá ni àwọn ará Éjíbítì ń ṣe yìí.” Ìdí èyí ni a fi ń pe ibẹ̀ ní Abeli-Mísíráímù (Ìsọ̀fọ̀ àwọn ará Éjíbítì). Kò sì jìnnà sí Jọ́dánì.

12 Báyìí ni àwọn ọmọ Jákọ́bù ṣe ohun tí baba wọn páṣẹ fún wọn.

13 Wọ́n gbé e lọ sí ilẹ̀ Kénánì, wọ́n sì sin-ín sínú ihò àpáta tí ó wà ní oko Makipélà, ní tòsí i Mámúrè tí Ábúráhámù rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìsìnkú lọ́wọ́ Éfúrónì ará Hítì, pẹ̀lú ilẹ̀ náà.

14 Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti sìnkú baba rẹ̀ tan, Jóṣẹ́fù padà sí Éjíbítì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn mìíràn tí ó tẹ̀lé e lọ láti sin baba rẹ̀.

15 Nígbà tí àwọn arákùnrin Jósẹ́fù rí i pé baba wọn kú, wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ǹjẹ́ bí ó bá ṣe pé Jósẹ́fù sì fi wá sínú ńkọ́, tí ó sì fẹ́ gbẹ̀ṣan gbogbo aburú tí a ti ṣe sí i?”

16 Nítorí náà wọ́n ránṣẹ́ sí Jósẹ́fù wí pé, “Baba rẹ fi àṣẹ yìí sílẹ̀ kí ó tó lọ wí pé:

17 ‘Èyí ni kí ẹ̀yin kí ó sọ fún Jóṣẹ́fù: Mo bẹ̀ ọ́ kí o dáríjìn àwọn arákùnrin rẹ, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti aburú tí wọ́n ṣe sí ọ, èyí tí ó mú ibi bá ọ’. Nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run baba rẹ jìn wọ́n.” Nígbà tí iṣẹ́ ti wọ́n rán dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Jósẹ́fù sunkún.