15 Méjìméjì ni gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè nínú wọlé pẹ̀lú Nóà sínú ọkọ̀.
16 Gbogbo wọn wọlé ní takọ tabo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Nóà, Olúwa sì tì wọn mọ́ inú ọkọ̀.
17 Òjò náà sì rọ̀ ní àrọ̀ìrọ̀dá fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ọkọ̀ náà sì ń léfòó lórí omi, kúrò lórí ilẹ̀ bí omi náà ti ń pọ̀ sí i.
18 Bí omi náà ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ọkọ̀ náà sì ń léfòó lójú omi.
19 Omi náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó bo gbogbo àwọn òkè gíga tí ó wà lábẹ́ ọ̀run.
20 Omi náà kún bo àwọn òkè, bí ìwọ̀n mítà bí i méje.
21 Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ parun: ẹyẹ, ohun ọ̀sìn, ẹranko igbó, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ènìyàn.